Ìwé Kejì sí Tímótì
1 Pọ́ọ̀lù, àpọ́sítélì Kristi Jésù nípasẹ̀ ìfẹ́ Ọlọ́run, èyí tó bá ìlérí ìyè tí a rí gbà nípasẹ̀ Kristi Jésù mu,+ 2 sí Tímótì, ọmọ tí mo nífẹ̀ẹ́:+
Kí o ní inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí, àánú àti àlàáfíà látọ̀dọ̀ Ọlọ́run tó jẹ́ Baba àti látọ̀dọ̀ Kristi Jésù Olúwa wa.
3 Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run, ẹni tí mò ń fi ẹ̀rí ọkàn tó mọ́ ṣe iṣẹ́ ìsìn mímọ́ fún bí àwọn baba ńlá mi ti ṣe, mi ò sì yéé rántí rẹ nínú àwọn ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ mi tọ̀sántòru. 4 Bí mo ṣe ń rántí omijé rẹ, àárò rẹ ń sọ mí, kí inú mi lè dùn gidigidi. 5 Torí mo rántí ìgbàgbọ́ rẹ tí kò ní ẹ̀tàn,+ èyí tí ìyá rẹ àgbà Lọ́ìsì àti ìyá rẹ Yùníìsì kọ́kọ́ ní, ó sì dá mi lójú pé irú ìgbàgbọ́ yìí ni ìwọ náà ní.
6 Torí èyí ni mo ṣe rán ọ létí pé kí o jẹ́ kí ẹ̀bùn Ọlọ́run tó wà nínú rẹ nígbà tí mo gbé ọwọ́ lé+ ọ máa jó bí iná. 7 Nítorí Ọlọ́run kò fún wa ní ẹ̀mí ojo,+ àmọ́ ó fún wa ní ẹ̀mí agbára+ àti ti ìfẹ́ àti ti àròjinlẹ̀. 8 Torí náà, má ṣe tijú láti jẹ́rìí nípa Olúwa wa+ tàbí èmi, ẹlẹ́wọ̀n nítorí rẹ̀, àmọ́ kí ìwọ náà jìyà torí ìhìn rere,+ kí o sì gbára lé agbára Ọlọ́run.+ 9 Ó gbà wá, ó sì fi ìpè mímọ́ pè wá,+ kì í ṣe torí àwọn iṣẹ́ wa, àmọ́ torí ohun tó fẹ́ ṣe àti inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí rẹ̀.+ Ọjọ́ pẹ́ tí a ti fún wa ní èyí nípasẹ̀ Kristi Jésù, 10 àmọ́ nísinsìnyí ìfarahàn Olùgbàlà wa, Kristi Jésù,+ ti mú kó ṣe kedere, ẹni tó mú ikú kúrò,+ tó sì tipasẹ̀ ìhìn rere+ tan ìmọ́lẹ̀ sí ìyè+ àti àìdíbàjẹ́.+ 11 Torí rẹ̀ ni a ṣe yàn mí láti di oníwàásù, àpọ́sítélì àti olùkọ́.+
12 Ìdí tí èmi náà ṣe ń jìyà àwọn nǹkan yìí nìyẹn,+ àmọ́ ojú ò tì mí.+ Torí mo mọ Ẹni tí mo gbà gbọ́, ó sì dá mi lójú pé ó lè dáàbò bo ohun tí mo fi sí ìkáwọ́ rẹ̀ títí di ọjọ́ náà.+ 13 Máa tẹ̀ lé ìlànà* àwọn ọ̀rọ̀ tó ṣàǹfààní*+ tí o gbọ́ lọ́dọ̀ mi pẹ̀lú ìgbàgbọ́ àti ìfẹ́ tó ń wá látinú àjọṣe tí a ní pẹ̀lú Kristi Jésù. 14 Máa fi ẹ̀mí mímọ́ tó ń gbé inú wa+ ṣọ́ ohun rere tí a fi síkàáwọ́ rẹ.
15 O mọ̀ pé gbogbo èèyàn ní ìpínlẹ̀ Éṣíà+ ti pa mí tì, títí kan Fíjẹ́lọ́sì àti Hẹmojẹ́nísì. 16 Kí Olúwa fi àánú hàn sí ìdílé Ónẹ́sífórù,+ torí pé ó máa ń mú kí ara tù mí lọ́pọ̀ ìgbà, kò sì tijú pé wọ́n fi ẹ̀wọ̀n dè mí. 17 Kàkà bẹ́ẹ̀, nígbà tó wà ní Róòmù, ó fara balẹ̀ wá mi, ó sì rí mi. 18 Kí Olúwa jẹ́ kó rí àánú gbà látọ̀dọ̀ Jèhófà* ní ọjọ́ yẹn. Gbogbo iṣẹ́ ìsìn tó ṣe ní Éfésù lo mọ̀ dáadáa.