Ìsíkíẹ́lì
45 “‘Nígbà tí ẹ bá pín ilẹ̀ náà bí ogún,+ kí ẹ mú ìpín kan tó jẹ́ mímọ́ lára ilẹ̀ náà wá fún Jèhófà láti fi ṣe ọrẹ.+ Kí gígùn rẹ̀ jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (25,000) ìgbọ̀nwọ́,* kí fífẹ̀ rẹ̀ sì jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (10,000) ìgbọ̀nwọ́.+ Gbogbo agbègbè* rẹ̀ yóò jẹ́ mímọ́. 2 Apá kan nínú ilẹ̀ náà tí ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin dọ́gba yóò wà fún ibi mímọ́, ìwọ̀n rẹ̀ yóò jẹ́ ọgọ́rùn-ún márùn-ún (500) ìgbọ̀nwọ́ níbùú àti lóòró,+ yóò sì ní ibi ìjẹko lẹ́gbẹ̀ẹ́ kọ̀ọ̀kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ àádọ́ta (50) ìgbọ̀nwọ́.+ 3 Látinú ibi tí ẹ wọ̀n yìí ni kí ẹ ti wọn ibi tó jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (25,000) ìgbọ̀nwọ́ ní gígùn, tí fífẹ̀ rẹ̀ sì jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (10,000) ìgbọ̀nwọ́, inú rẹ̀ ni ibi mímọ́ yóò wà, ohun mímọ́ jù lọ. 4 Ibẹ̀ ló máa jẹ́ ibi mímọ́ nínú ilẹ̀ náà, yóò jẹ́ ti àwọn àlùfáà,+ àwọn tó ń ṣiṣẹ́ ní ibi mímọ́, tó ń wá síwájú Jèhófà láti ṣiṣẹ́ fún un.+ Ibẹ̀ ni ilé wọn máa wà, ibẹ̀ ló sì máa jẹ́ ibi mímọ́ fún tẹ́ńpìlì náà.
5 “‘Àwọn ọmọ Léfì, àwọn tó ń ṣiṣẹ́ nínú tẹ́ńpìlì máa ní ibì kan tí gígùn rẹ̀ jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (25,000) ìgbọ̀nwọ́, tí fífẹ̀ rẹ̀ sì jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (10,000) ìgbọ̀nwọ́,+ ogún (20) yàrá ìjẹun*+ yóò sì jẹ́ ohun ìní wọn.
6 “‘Ẹ ó ya apá kan sọ́tọ̀ tó máa jẹ́ ohun ìní tó jẹ́ ti ìlú. Gígùn rẹ̀ máa jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (25,000) ìgbọ̀nwọ́, (èyí tó bá ilẹ̀ mímọ́ náà mu) fífẹ̀ rẹ̀ á sì jẹ́ ẹgbẹ̀rún márùn-ún (5,000) ìgbọ̀nwọ́.+ Yóò jẹ́ ti gbogbo ilé Ísírẹ́lì.
7 “‘Ní ti ìjòyè, ilẹ̀ rẹ̀ yóò wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ méjèèjì ilẹ̀ mímọ́ náà àti lẹ́gbẹ̀ẹ́ ilẹ̀ tó jẹ́ ti ìlú. Yóò wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ ilẹ̀ mímọ́ náà àti ilẹ̀ tó jẹ́ ti ìlú náà. Apá ìwọ̀ oòrùn àti ìlà oòrùn ló máa wà. Gígùn rẹ̀ láti ààlà ìwọ̀ oòrùn dé ààlà ìlà oòrùn yóò dọ́gba pẹ̀lú ọ̀kan nínú àwọn ilẹ̀ tí ẹ̀yà kan ní.+ 8 Ilẹ̀ yìí yóò di ohun ìní rẹ̀ ní Ísírẹ́lì. Àwọn ìjòyè mi kò ní ni àwọn èèyàn mi lára mọ́,+ wọ́n á sì fún ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan ní ilé Ísírẹ́lì ní ilẹ̀ náà bí wọ́n bá ṣe rí.’+
9 “Ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí: ‘Ó tó gẹ́ẹ́, ẹ̀yin ìjòyè Ísírẹ́lì!’
“‘Ẹ má hùwà ipá mọ́, ẹ má sì ni àwọn èèyàn lára mọ́. Ẹ ṣe ohun tó tọ́, tó sì jẹ́ òdodo.+ Ẹ má gba ohun ìní àwọn èèyàn mi mọ́,’+ ni Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí. 10 ‘Àwọn òṣùwọ̀n tó péye ni kí ẹ máa lò, kí ẹ sì máa lo òṣùwọ̀n eéfà* àti òṣùwọ̀n báàtì* tó péye.+ 11 Kí ìwọ̀n pàtó kan wà tí a ó máa lò fún òṣùwọ̀n eéfà àti báàtì. Kí ìdá mẹ́wàá òṣùwọ̀n hómérì* kún òṣùwọ̀n báàtì, kí ìdá mẹ́wàá òṣùwọ̀n hómérì sì kún òṣùwọ̀n eéfà. Òṣùwọ̀n hómérì ni kí ẹ máa lò láti fi díwọ̀n. 12 Kí ṣékélì*+ kan jẹ́ ogún (20) gérà.* Àpapọ̀ ogún (20) ṣékélì àti ṣékélì mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (25) àti ṣékélì mẹ́ẹ̀ẹ́dógún (15) ni kó jẹ́ mánẹ̀* kan tí ẹ ó máa lò.’
13 “‘Ọrẹ tí ẹ máa mú wá nìyí: àlìkámà* tó kún ìdá mẹ́fà òṣùwọ̀n eéfà ni kí ẹ mú látinú òṣùwọ̀n hómérì kọ̀ọ̀kan àti ọkà bálì tó kún ìdá mẹ́fà òṣùwọ̀n eéfà ni kí ẹ mú látinú òṣùwọ̀n hómérì kọ̀ọ̀kan. 14 Òṣùwọ̀n báàtì ni kí ẹ máa fi díwọ̀n òróró. Ìdá mẹ́wàá òṣùwọ̀n kọ́ọ̀* ni báàtì jẹ́. Òṣùwọ̀n báàtì mẹ́wàá ló wà nínú òṣùwọ̀n hómérì kan, torí báàtì mẹ́wàá ni hómérì kan. 15 Kí ẹ sì mú àgùntàn kọ̀ọ̀kan nínú igba (200) àgùntàn látinú agbo ẹran ọ̀sìn Ísírẹ́lì wá bí ọrẹ. Ìwọ̀nyí ni wọ́n á lò fún ọrẹ ọkà,+ odindi ẹbọ sísun+ àti ẹbọ ìrẹ́pọ̀+ kí wọ́n lè ṣe ètùtù fún àwọn èèyàn náà,’+ ni Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí.
16 “‘Gbogbo èèyàn ilẹ̀ náà yóò mú ọrẹ yìí wá+ fún ìjòyè ní Ísírẹ́lì. 17 Àmọ́ ìjòyè náà ló máa mú odindi ẹbọ sísun,+ ọrẹ ọkà+ àti ọrẹ ohun mímu wá nígbà àwọn àjọ̀dún,+ ọjọ́ òṣùpá tuntun, àwọn Sábáàtì+ àti ní gbogbo àjọ̀dún tí ilé Ísírẹ́lì máa ń ṣe.+ Òun ló máa pèsè ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, ọrẹ ọkà, odindi ẹbọ sísun àti àwọn ẹbọ ìrẹ́pọ̀, láti ṣe ètùtù torí ilé Ísírẹ́lì.’
18 “Ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí: ‘Ní ọjọ́ kìíní, oṣù kìíní, kí o mú akọ ọmọ màlúù kan látinú agbo ẹran, èyí tí ara rẹ̀ dá ṣáṣá, kí o sì wẹ ibi mímọ́ náà mọ́ kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀.+ 19 Àlùfáà yóò mú lára ẹ̀jẹ̀ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, yóò sì fi sára férémù ilẹ̀kùn tẹ́ńpìlì náà,+ sí igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ìgbásẹ̀ tó yí pẹpẹ náà ká àti sára férémù ilẹ̀kùn ẹnubodè àgbàlá inú. 20 Ohun tí ẹ máa ṣe ní ọjọ́ keje oṣù náà nìyẹn, torí ẹnikẹ́ni tó bá ṣèèṣì dẹ́ṣẹ̀ tàbí tó dẹ́ṣẹ̀ láìmọ̀;+ kí ẹ sì ṣe ètùtù láti sọ tẹ́ńpìlì náà di mímọ́.+
21 “‘Ní ọjọ́ kẹrìnlá oṣù kìíní, kí ẹ ṣe àjọyọ̀ Ìrékọjá.+ Ọjọ́ méje ni kí ẹ fi jẹ búrẹ́dì aláìwú.+ 22 Ní ọjọ́ yẹn, ìjòyè náà yóò pèsè akọ ọmọ màlúù láti fi rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ torí ara rẹ̀ àti torí gbogbo èèyàn ilẹ̀ náà.+ 23 Yóò pèsè akọ ọmọ màlúù méje àti àgbò méje tí ara wọn dá ṣáṣá lójoojúmọ́ fún ọjọ́ méje tí wọ́n á fi ṣe àjọyọ̀ náà.+ Wọ́n á jẹ́ odindi ẹbọ sísun sí Jèhófà, yóò sì tún máa pèsè òbúkọ kan lójoojúmọ́ láti fi rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀. 24 Yóò tún pèsè òṣùwọ̀n eéfà kan fún akọ ọmọ màlúù kọ̀ọ̀kan àti òṣùwọ̀n eéfà kan fún àgbò kọ̀ọ̀kan, yóò sì tún pèsè òróró tó kún òṣùwọ̀n hínì* kan fún òṣùwọ̀n eéfà kọ̀ọ̀kan.
25 “‘Ní ọjọ́ kẹẹ̀ẹ́dógún oṣù keje, kó pèsè ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, odindi ẹbọ sísun, ọrẹ ọkà àti òróró kan náà fún ọjọ́ méje tí wọ́n á fi ṣe àjọyọ̀ náà.’”+