Ìsíkíẹ́lì
28 Jèhófà tún bá mi sọ̀rọ̀, ó ní: 2 “Ọmọ èèyàn, sọ fún aṣáájú Tírè pé, ‘Ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí:
“Torí pé ò ń gbéra ga nínú ọkàn rẹ,+ tí o sì ń sọ pé, ‘ọlọ́run ni mí.
Orí ìtẹ́ ọlọ́run ni mo jókòó sí láàárín òkun.’+
Àmọ́ èèyàn lásán ni ọ́, o kì í ṣe ọlọ́run,
Bí o tiẹ̀ ń pe ara rẹ ní ọlọ́run nínú ọkàn rẹ.
3 Wò ó! O gbọ́n ju Dáníẹ́lì lọ.+
Kò sí àṣírí tó pa mọ́ fún ọ.
4 O ti fi ọgbọ́n àti òye rẹ sọ ara rẹ di ọlọ́rọ̀,
O sì ń kó wúrà àti fàdákà jọ síbi ìṣúra rẹ.+
5 Bí o ṣe já fáfá nídìí òwò rẹ ti mú kí ọrọ̀ rẹ pọ̀ rẹpẹtẹ,+
O sì bẹ̀rẹ̀ sí í gbéra ga nínú ọkàn rẹ nítorí ọrọ̀ rẹ.”’
6 “‘Torí náà, ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí:
“Torí ò ń pe ara rẹ ní ọlọ́run nínú ọkàn rẹ,
7 Èmi yóò mú kí àwọn àjèjì wá bá ọ jà, àwọn tó burú jù láàárín àwọn orílẹ̀-èdè,+
Wọn yóò fa idà yọ sí gbogbo ohun tó rẹwà tí o fi ọgbọ́n rẹ kó jọ,
Wọn yóò sì sọ ògo rẹ tó rẹwà di aláìmọ́.+
9 Ṣé wàá ṣì sọ fún ẹni tó fẹ́ pa ọ́ pé, ‘ọlọ́run ni mí?’
Èèyàn lásán lo máa jẹ́ lọ́wọ́ àwọn tó ń sọ ọ́ di aláìmọ́, o ò ní jẹ́ ọlọ́run.”’
10 ‘Ìwọ yóò kú lọ́wọ́ àwọn àjèjì bí aláìdádọ̀dọ́,*
Torí èmi fúnra mi ti sọ̀rọ̀,’ ni Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí.”
11 Jèhófà tún bá mi sọ̀rọ̀ pé: 12 “Ọmọ èèyàn, kọ orin arò* nípa ọba Tírè, kí o sì sọ fún un pé, ‘Ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí:
13 O wà ní Édẹ́nì, ọgbà Ọlọ́run.
Gbogbo òkúta iyebíye ni mo fi ṣe ọ́ lọ́ṣọ̀ọ́,
Rúbì, tópásì àti jásípérì; kírísóláítì, ónísì àti jéèdì; sàfáyà, tọ́kọ́wásì+ àti émírádì;
Wúrà sì ni mo fi ṣe ojú ibi tí wọ́n lẹ̀ wọ́n mọ́.
Ọjọ́ tí mo dá ọ ni mo ṣe wọ́n.
14 Mo fi ọ́ ṣe kérúbù aláàbò tí mo fòróró yàn.
O wà lórí òkè mímọ́ Ọlọ́run,+ o sì rìn kiri láàárín àwọn òkúta oníná.
Torí náà, màá ta ọ́ nù kúrò ní òkè Ọlọ́run bí ẹni tí wọ́n kẹ́gàn, màá sì pa ọ́ run,+
Ìwọ kérúbù aláàbò, màá pa ọ́ run kúrò láàárín àwọn òkúta oníná.
17 O bẹ̀rẹ̀ sí í gbéra ga nínú ọkàn rẹ torí ẹwà rẹ.+
Ògo rẹ tó rẹwà mú kí o ba ọgbọ́n rẹ jẹ́.+
Èmi yóò jù ọ́ sí ilẹ̀.+
Màá sì mú kí àwọn ọba fi ọ́ ṣe ìran wò.
18 O ti sọ àwọn ibi mímọ́ rẹ di aláìmọ́ nítorí pé ẹ̀bi rẹ pọ̀, o ò sì ṣòótọ́ nídìí òwò rẹ.
Màá mú kí iná sọ láàárín rẹ, yóò sì jẹ ọ́ run.+
Màá sọ ọ́ di eérú lórí ilẹ̀ lójú gbogbo àwọn tó ń wò ọ́.
19 Gbogbo àwọn tó mọ̀ ọ́ láàárín àwọn èèyàn yóò wò ọ́ tìyanutìyanu.+
Ìparun rẹ yóò dé lójijì, yóò sì burú jáì,
O ò sì ní sí mọ́ títí láé.”’”+
20 Jèhófà tún bá mi sọ̀rọ̀, ó ní: 21 “Ọmọ èèyàn, yíjú rẹ sọ́dọ̀ Sídónì,+ kí o sì sọ àsọtẹ́lẹ̀ sórí rẹ̀. 22 Kí o sọ pé, ‘Ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí:
“Màá bá ọ jà, ìwọ Sídónì, wọ́n á sì yìn mí lógo láàárín rẹ;
Àwọn èèyàn á sì wá mọ̀ pé èmi ni Jèhófà nígbà tí mo bá dá a lẹ́jọ́, tí mo sì fi hàn pé mo jẹ́ mímọ́ nínú rẹ̀.
23 Màá fi àjàkálẹ̀ àrùn kọ lù ú, ẹ̀jẹ̀ á sì ṣàn ní àwọn ojú ọ̀nà rẹ̀.
Àwọn tí wọ́n pa yóò ṣubú láàárín rẹ̀ nígbà tí idà bá dojú kọ ọ́ láti ibi gbogbo;
Wọ́n á sì wá mọ̀ pé èmi ni Jèhófà.+
24 “‘“Ẹ̀gún tó ń ṣeni léṣe àti òṣùṣú tó ń roni lára kò ní yí ilé Ísírẹ́lì ká mọ́,+ àwọn ló ń fi ilé Ísírẹ́lì ṣe ẹlẹ́yà; àwọn èèyàn á sì wá mọ̀ pé èmi ni Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ.”’
25 “‘Ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí: “Nígbà tí mo bá tún kó ilé Ísírẹ́lì jọ láti àárín àwọn èèyàn tí wọ́n fọ́n ká sí,+ màá fi hàn pé mo jẹ́ mímọ́ láàárín wọn lójú àwọn orílẹ̀-èdè.+ Wọ́n á sì máa gbé lórí ilẹ̀ wọn+ tí mo fún Jékọ́bù ìránṣẹ́ mi.+ 26 Wọn yóò máa gbé ibẹ̀, ààbò yóò sì wà lórí wọn,+ wọ́n á kọ́ ilé, wọ́n á gbin ọgbà àjàrà,+ nígbà tí mo bá ṣèdájọ́ gbogbo àwọn tó yí wọn ká tó ń fi wọ́n ṣẹlẹ́yà,+ ààbò yóò wà lórí wọn; wọ́n á sì wá mọ̀ pé èmi ni Jèhófà Ọlọ́run wọn.”’”