Ìsíkíẹ́lì
23 Jèhófà tún bá mi sọ̀rọ̀, ó ní: 2 “Ọmọ èèyàn, àwọn obìnrin méjì kan wà tí wọ́n jẹ́ ọmọ ìyá kan náà.+ 3 Wọ́n di aṣẹ́wó ní Íjíbítì;+ láti kékeré ni wọ́n ti ń ṣe aṣẹ́wó. Wọ́n tẹ ọmú wọn níbẹ̀, wọ́n sì fọwọ́ pa wọ́n láyà nígbà tí wọn ò tíì mọ ọkùnrin. 4 Orúkọ ẹ̀gbọ́n ni Òhólà,* orúkọ àbúrò rẹ̀ sì ni Òhólíbà.* Wọ́n di tèmi, wọ́n sì bí àwọn ọmọ ọkùnrin àti obìnrin. Èyí tó ń jẹ́ Òhólà ni Samáríà,+ èyí tó sì ń jẹ́ Òhólíbà ni Jerúsálẹ́mù.
5 “Nígbà tí Òhólà ṣì jẹ́ tèmi, ó bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe aṣẹ́wó.+ Ọkàn rẹ̀ fà sí àwọn olólùfẹ́ rẹ̀ àtàtà,+ àwọn ará Ásíríà tó jẹ́ aládùúgbò rẹ̀ kó lè bá wọn ṣèṣekúṣe.+ 6 Gómìnà àti ìjòye ni wọ́n, wọ́n wọ aṣọ aláwọ̀ búlúù, gbogbo wọn jẹ́ géńdé tó dáa lọ́mọkùnrin, wọ́n ń gun ẹṣin. 7 Ó bá àwọn tó dáa jù lára àwọn ọmọkùnrin Ásíríà ṣèṣekúṣe, ó sì fi àwọn òrìṣà ẹ̀gbin* tó jẹ́ ti àwọn tí ọkàn rẹ̀ ń fà sí sọ ara rẹ̀ di ẹlẹ́gbin.+ 8 Kò jáwọ́ nínú iṣẹ́ aṣẹ́wó tó ṣe ní Íjíbítì, torí wọ́n ti bá a sùn nígbà èwe rẹ̀, wọ́n fọwọ́ pa á láyà nígbà tí kò tíì mọ ọkùnrin, wọ́n sì tẹ́ ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ wọn lọ́rùn lára rẹ̀.*+ 9 Torí náà, mo mú kí ọwọ́ àwọn olólùfẹ́ rẹ̀ àtàtà tẹ̀ ẹ́, àwọn ọmọ Ásíríà+ tí ọkàn rẹ̀ fà sí. 10 Wọ́n tú u sí ìhòòhò,+ wọ́n fi idà pa á, wọ́n sì mú àwọn ọmọ rẹ̀ ọkùnrin àti obìnrin.+ Ìwà burúkú rẹ̀ mú kó gbajúmọ̀ láàárín àwọn obìnrin, wọ́n sì dá a lẹ́jọ́.
11 “Nígbà tí Òhólíbà àbúrò rẹ̀ rí i, ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ọkàn rẹ̀ tún burú sí i, ìṣekúṣe rẹ̀ sì wá burú jáì ju ti ẹ̀gbọ́n rẹ̀ lọ.+ 12 Ọkàn rẹ̀ fà sí àwọn ọmọkùnrin Ásíríà tí wọ́n wà nítòsí rẹ̀,+ gómìnà àti ìjòyè ni wọ́n, wọ́n wọ aṣọ iyì, wọ́n sì ń gun ẹṣin, gbogbo wọn jẹ́ géńdé tó dáa lọ́mọkùnrin. 13 Nígbà tó ba ara rẹ̀ jẹ́, mo rí i pé ọ̀nà kan náà ni àwọn méjèèjì tọ̀.+ 14 Àmọ́, ó túbọ̀ ń ṣèṣekúṣe. Ó rí ère àwọn ọkùnrin tí wọ́n gbẹ́ sára ògiri, ère àwọn ará Kálídíà tí wọ́n kùn ní àwọ̀ pupa, 15 tí wọ́n de àmùrè mọ́ ìbàdí wọn, láwàní gígùn wà lórí wọn, wọ́n rí bíi jagunjagun, gbogbo wọn jọ àwọn ará Bábílónì, tí wọ́n bí ní ilẹ̀ àwọn ará Kálídíà. 16 Bó ṣe rí wọn, ṣe ni ọkàn rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í fà sí wọn láti bá wọn ṣèṣekúṣe, ó sì rán àwọn òjíṣẹ́ sí wọn ní Kálídíà.+ 17 Torí náà, àwọn ọmọ Bábílónì ń wá sórí ibùsùn tó ti ń ṣeré ìfẹ́, wọ́n sì fi ìṣekúṣe wọn sọ ọ́ di ẹlẹ́gbin. Lẹ́yìn tí wọ́n sọ ọ́ di ẹlẹ́gbin, ó* kórìíra wọn, ó sì fi wọ́n sílẹ̀.
18 “Nígbà tí kò fi iṣẹ́ aṣẹ́wó rẹ̀ bò mọ́, tó sì ń tú ara rẹ̀ sí ìhòòhò,+ mo kórìíra rẹ̀, mo sì fi í sílẹ̀, bí mo ṣe kórìíra ẹ̀gbọ́n rẹ̀ tí mo* sì fi í sílẹ̀.+ 19 Ìṣekúṣe rẹ̀ sì ń pọ̀ sí i,+ ó ń rántí ìgbà èwe rẹ̀, tó ṣe aṣẹ́wó ní ilẹ̀ Íjíbítì.+ 20 Ọkàn rẹ̀ fà sí wọn bíi wáhàrì* àwọn ọkùnrin tí nǹkan ọkùnrin wọn dà bíi ti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, tí ẹ̀yà ìbímọ wọn sì dà bíi ti ẹṣin. 21 Ó tún ń wù ọ́ láti máa hùwà àìnítìjú tí o hù ní Íjíbítì nígbà tí o wà léwe,+ tí wọ́n ń fọwọ́ pa ọ́ láyà, ìyẹn ọmú ìgbà èwe rẹ.+
22 “Torí náà, ìwọ Òhólíbà, ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí: ‘Èmi yóò ru àwọn olólùfẹ́ rẹ sókè,+ àwọn tí o* kórìíra tí o sì fi sílẹ̀, èmi yóò sì mú kí wọ́n kọjú ìjà sí ọ láti ibi gbogbo,+ 23 àwọn ọmọkùnrin Bábílónì+ àti gbogbo ará Kálídíà,+ àwọn ará Pékódù,+ Ṣóà àti Kóà, pẹ̀lú gbogbo ọmọkùnrin Ásíríà. Géńdé tó dáa lọ́mọkùnrin ni gbogbo wọn, wọ́n jẹ́ gómìnà àti ìjòyè, jagunjagun àti àwọn tí wọ́n yàn,* gbogbo wọn ń gun ẹṣin. 24 Wọ́n á gbéjà kò ọ́ pẹ̀lú àwọn kẹ̀kẹ́ ogun àti àgbá kẹ̀kẹ́ rẹpẹtẹ àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọmọ ogun, apata ńlá, asà* àti akoto.* Wọ́n á yí ọ ká, màá sì pàṣẹ pé kí wọ́n dá ọ lẹ́jọ́, wọ́n á sì ṣèdájọ́ rẹ bó ṣe tọ́ lójú wọn.+ 25 Èmi yóò bínú sí ọ, wọ́n á sì fi ìrunú bá ọ jà. Wọ́n á gé imú rẹ àti etí rẹ, idà ló sì máa pa àwọn tó bá ṣẹ́ kù nínú rẹ. Wọn yóò kó àwọn ọmọ rẹ ọkùnrin àti ọmọ rẹ obìnrin lọ, iná sì máa run àwọn tó bá ṣẹ́ kù nínú rẹ.+ 26 Wọ́n á bọ́ aṣọ lára rẹ,+ wọ́n á sì gba ohun ọ̀ṣọ́ rẹ.+ 27 Èmi yóò fòpin sí ìwà àìnítìjú tí ò ń hù àti iṣẹ́ aṣẹ́wó+ tí o bẹ̀rẹ̀ ní ilẹ̀ Íjíbítì.+ O ò ní wò wọ́n mọ́, o ò sì ní rántí Íjíbítì mọ́.’
28 “Ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí, ‘Mo máa tó mú kí ọwọ́ àwọn tí o kórìíra tẹ̀ ọ́, àwọn tó rí ọ lára, tí o* sì fi sílẹ̀.+ 29 Ìkórìíra ni wọ́n á fi bá ọ jà, wọ́n á kó gbogbo ohun tí o ti ṣe làálàá fún lọ,+ wọ́n á sì fi ọ́ sílẹ̀ ní ìhòòhò. Ìhòòhò rẹ tó ń tini lójú tí o fi ń ṣèṣekúṣe yóò hàn síta, bẹ́ẹ̀ náà ni ìwà àìnítìjú rẹ àti iṣẹ́ aṣẹ́wó rẹ.+ 30 Wọ́n á ṣe gbogbo nǹkan yìí sí ọ torí ò ń sáré tẹ̀ lé àwọn orílẹ̀-èdè bí aṣẹ́wó,+ torí o fi àwọn òrìṣà ẹ̀gbin wọn sọ ara rẹ di ẹlẹ́gbin.+ 31 Ohun tí ẹ̀gbọ́n rẹ ṣe ni ìwọ náà ń ṣe,+ màá sì fi ife rẹ̀ lé ọ lọ́wọ́.’+
32 “Ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí:
‘Ìwọ yóò mu nínú ife ẹ̀gbọ́n rẹ, ife tí inú rẹ̀ jìn, tó sì fẹ̀.+
Wọ́n á fi ọ́ ṣe yẹ̀yẹ́, wọ́n á sì fi ọ́ ṣẹlẹ́yà, èyí tó kún inú ife náà.+
33 Ìwọ yóò mu àmuyó, ìbànújẹ́ yóò sì bò ọ́,
Wàá mu látinú ife ìbẹ̀rù àti ti ahoro,
Ife Samáríà ẹ̀gbọ́n rẹ.
34 Ìwọ yóò mu nínú rẹ̀, ìwọ yóò mu ún gbẹ,+ wàá sì máa họ àpáàdì rẹ̀ jẹ,
Ìwọ yóò sì fa ọmú rẹ ya.
“Torí èmi alára ti sọ̀rọ̀,” ni Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí.’
35 “Torí náà, ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí, ‘Torí pé o ti gbàgbé mi, tí o sì ti pa mí tì pátápátá,*+ wàá jìyà ìwà àìnítìjú tí o hù àti iṣẹ́ aṣẹ́wó rẹ.’”
36 Jèhófà wá sọ fún mi pé: “Ọmọ èèyàn, ṣé o máa kéde ìdájọ́ fún Òhólà àti Òhólíbà,+ kí o sì gbé ọ̀rọ̀ nípa ohun tó ń ríni lára tí wọ́n ṣe kò wọ́n lójú? 37 Wọ́n ti ṣe àgbèrè,*+ ẹ̀jẹ̀ sì wà lọ́wọ́ wọn. Kì í ṣe pé wọ́n bá àwọn òrìṣà ẹ̀gbin wọn ṣe àgbèrè nìkan ni, wọ́n tún sun àwọn ọmọ tí wọ́n bí fún mi nínú iná kí wọ́n lè di oúnjẹ fún àwọn òrìṣà.+ 38 Ohun tí wọ́n tún ṣe nìyí: Wọ́n sọ ibi mímọ́ mi di ẹlẹ́gbin ní ọjọ́ yẹn, wọ́n sì sọ àwọn sábáàtì mi di aláìmọ́. 39 Lẹ́yìn tí wọ́n pa àwọn ọmọ wọn, tí wọ́n sì fi wọ́n rúbọ sí àwọn òrìṣà ẹ̀gbin wọn,+ wọ́n wá sínú ibi mímọ́ mi kí wọ́n lè sọ ọ́ di aláìmọ́+ ní ọjọ́ yẹn gan-an. Ohun tí wọ́n ṣe nínú ilé mi nìyẹn. 40 Wọ́n tún rán ẹnì kan sí àwọn èèyàn kí wọ́n lè wá láti ọ̀nà jíjìn.+ Nígbà tí wọ́n ń bọ̀, o wẹ̀, o kun ojú rẹ, o sì fi ohun ọ̀ṣọ́ ṣe ara rẹ lóge.+ 41 O jókòó sórí àga tìmùtìmù tó lọ́lá,+ wọ́n tẹ́ tábìlì síwájú àga náà,+ o sì gbé tùràrí mi + àti òróró mi sórí tábìlì náà.+ 42 Wọ́n gbọ́ ìró ọ̀pọ̀ èèyàn tí wọ́n ń jayé níbẹ̀, àwọn ọ̀mùtípara tí wọ́n mú wá láti aginjù wà lára wọn. Wọ́n fi ẹ̀gbà sọ́wọ́ àwọn obìnrin, wọ́n sì dé wọn ládé tó rẹwà.
43 “Mo wá sọ nípa obìnrin tí àgbèrè ti tán lókun pé: ‘Ní báyìí, kò ní jáwọ́ nínú iṣẹ́ aṣẹ́wó tó ń ṣe.’ 44 Wọ́n sì ń wọlé lọ bá a, bí ìgbà tí wọ́n ń lọ bá aṣẹ́wó. Bí wọ́n ṣe ń wọlé lọ bá Òhólà àti Òhólíbà nìyẹn, àwọn obìnrin tó ń hùwà àìnítìjú. 45 Àmọ́ ìdájọ́ tó tọ́ sí alágbèrè ni àwọn olódodo yóò ṣe fún un+ àti èyí tó tọ́ sí ẹni tó ń ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀;+ torí alágbèrè ni wọ́n, ẹ̀jẹ̀ sì wà ní ọwọ́ wọn.+
46 “Torí ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí, ‘Èmi yóò gbé àwọn ọmọ ogun dìde láti bá wọn jà, kí ìbẹ̀rù lè bò wọ́n, kí wọ́n sì kó wọn lẹ́rù.+ 47 Àwọn ọmọ ogun náà yóò sọ wọ́n ní òkúta,+ wọ́n á sì fi idà pa wọ́n. Wọ́n á pa àwọn ọmọ wọn ọkùnrin àti obìnrin,+ wọ́n á sì dáná sun àwọn ilé wọn.+ 48 Èmi yóò fòpin sí ìwà àìnítìjú tí wọ́n ń hù ní ilẹ̀ náà, èyí á kọ́ gbogbo obìnrin lẹ́kọ̀ọ́, wọn ò sì ní hùwà àìnítìjú bíi tiyín.+ 49 Wọ́n á mú ẹ̀san ìwà àìnítìjú yín wá sórí yín àti ẹ̀san àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tí ẹ dá pẹ̀lú àwọn òrìṣà ẹ̀gbin yín; ẹ ó sì wá mọ̀ pé èmi ni Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ.’”+