Jóòbù
26 Jóòbù wá fèsì pé:
2 “Wo bí o ṣe ran ẹni tí kò lágbára lọ́wọ́!
Wo bí o ṣe gba apá tí kò lókun là!+
3 Wo ìmọ̀ràn tó dáa gan-an tí o fún ẹni tí kò gbọ́n!+
Wo bí o ṣe fi ọgbọ́n rẹ tó gbéṣẹ́* hàn ní fàlàlà!*
4 Ta lò ń gbìyànjú láti bá sọ̀rọ̀,
Ta ló sì mí sí ọ tí o fi ń sọ àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀?*
5 Jìnnìjìnnì bá àwọn tí ikú ti pa;*
Wọ́n tiẹ̀ tún rẹlẹ̀ ju omi àtàwọn tó ń gbénú wọn.
7 Ó na òfúrufú apá àríwá* sórí ibi tó ṣófo,*+
Ó fi ayé rọ̀ sórí òfo;
8 Ó wé omi mọ́ inú àwọsánmà* rẹ̀,+
Débi pé àwọsánmà ò bẹ́, bí wọ́n tiẹ̀ wúwo;
9 Ó bo ìtẹ́ rẹ̀ ká má bàa rí i,
Ó na sánmà rẹ̀ bò ó.+
11 Àní àwọn òpó ọ̀run mì tìtì;
Ìbáwí rẹ̀ mú wọn wárìrì.
14 Wò ó! Bíńtín lèyí jẹ́ lára àwọn ọ̀nà rẹ̀;+
Ọ̀rọ̀ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ lásán ló ta sí wa létí nípa rẹ̀!
Ta ló wá lè lóye ààrá ńlá rẹ̀?”+