Orin Ìgòkè.
121 Mo gbé ojú mi sókè sí àwọn òkè.+
Ibo ni ìrànlọ́wọ́ mi yóò ti wá?
2 Ọ̀dọ̀ Jèhófà ni ìrànlọ́wọ́ mi ti ń wá,+
Aṣẹ̀dá ọ̀run àti ayé.
3 Kò ní jẹ́ kí ẹsẹ̀ rẹ yọ̀.+
Ẹni tó ń ṣọ́ ọ kò ní tòògbé láé.
4 Wò ó! Ẹni tó ń ṣọ́ Ísírẹ́lì kì í tòògbé,
Bẹ́ẹ̀ ni kì í sùn.+
5 Jèhófà ń ṣọ́ ọ.
Jèhófà ni ibòji+ tó wà ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ.+
6 Oòrùn kò ní pa ọ́ lára ní ọ̀sán,+
Tàbí òṣùpá ní òru.+
7 Jèhófà yóò máa ṣọ́ ọ kí jàǹbá kankan má ṣe ọ́.+
Yóò máa ṣọ́ ẹ̀mí rẹ.+
8 Jèhófà yóò máa ṣọ́ ọ nínú gbogbo ohun tí o bá ń ṣe
Láti ìsinsìnyí lọ àti títí láé.