Jóṣúà
2 Jóṣúà ọmọ Núnì wá rán ọkùnrin méjì jáde ní bòókẹ́lẹ́ láti Ṣítímù,+ pé kí wọ́n lọ ṣe amí. Ó sọ fún wọn pé: “Ẹ lọ yẹ ilẹ̀ náà wò, pàápàá ilẹ̀ Jẹ́ríkò.” Torí náà, wọ́n lọ, wọ́n dé ilé aṣẹ́wó kan tó ń jẹ́ Ráhábù,+ wọ́n sì dúró sí ibẹ̀. 2 Àwọn kan sọ fún ọba Jẹ́ríkò pé: “Wò ó! Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ti wọlé wá síbí ní alẹ́ yìí láti ṣe amí ilẹ̀ yìí.” 3 Ni ọba Jẹ́ríkò bá ránṣẹ́ sí Ráhábù pé: “Mú àwọn ọkùnrin tó wá síbí jáde, àwọn tí wọ́n wà lọ́dọ̀ rẹ, torí ṣe ni wọ́n wá ṣe amí gbogbo ilẹ̀ yìí.”
4 Àmọ́ obìnrin náà mú àwọn ọkùnrin méjèèjì, ó sì fi wọ́n pa mọ́. Ó wá sọ pé: “Òótọ́ ni àwọn ọkùnrin náà wá sọ́dọ̀ mi, àmọ́ mi ò mọ ibi tí wọ́n ti wá. 5 Nígbà tí ilẹ̀ sì ṣú, tó kù díẹ̀ kí wọ́n ti ẹnubodè ìlú ni àwọn ọkùnrin náà jáde. Mi ò mọ ibi tí àwọn ọkùnrin náà lọ, àmọ́ tí ẹ bá tètè sá tẹ̀ lé wọn, ẹ máa bá wọn.” 6 (Àmọ́ obìnrin náà ti mú àwọn amí náà lọ sórí òrùlé, ó sì fi wọ́n pa mọ́ sáàárín pòròpórò ọ̀gbọ̀ tí wọ́n tò sórí òrùlé náà.) 7 Àwọn ọkùnrin náà bá sáré wá àwọn amí náà lọ, wọ́n gba ọ̀nà Jọ́dánì níbi tó ṣeé fẹsẹ̀ gbà kọjá nínú odò náà,+ wọ́n sì ti ẹnubodè ìlú lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ tí àwọn tó ń wá àwọn amí náà jáde.
8 Kí àwọn ọkùnrin náà tó dùbúlẹ̀ láti sùn, ó lọ bá wọn lórí òrùlé. 9 Ó sì sọ fún wọn pé: “Mo mọ̀ pé Jèhófà máa fún yín ní ilẹ̀ yìí+ àti pé ẹ̀rù yín ti ń bà wá.+ Ọkàn gbogbo àwọn tó ń gbé ilẹ̀ yìí sì ti domi nítorí yín,+ 10 torí a ti gbọ́ bí Jèhófà ṣe mú kí omi Òkun Pupa gbẹ níwájú yín nígbà tí ẹ kúrò ní Íjíbítì+ àti ohun tí ẹ ṣe sí àwọn ọba Ámórì méjèèjì, ìyẹn Síhónì+ àti Ógù+ tí ẹ pa run ní òdìkejì* Jọ́dánì. 11 Nígbà tí a gbọ́ nípa rẹ̀, ọkàn wa domi,* kò sì sẹ́ni tó ní ìgboyà* mọ́ nítorí yín, torí Jèhófà Ọlọ́run yín ni Ọlọ́run lókè ọ̀run àti lórí ilẹ̀ ayé.+ 12 Ní báyìí, ẹ jọ̀ọ́, ẹ fi Jèhófà búra fún mi pé ẹ̀yin náà máa fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ hàn sí agbo ilé bàbá mi, torí mo ti fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ hàn sí yín; kí ẹ fún mi ní àmì kan tó ṣeé gbára lé.* 13 Kí ẹ dá ẹ̀mí bàbá mi àti ìyá mi sí, àwọn arákùnrin mi àtàwọn arábìnrin mi àti gbogbo èèyàn wọn, kí ẹ sì gbà wá* lọ́wọ́ ikú.”+
14 Àwọn ọkùnrin náà sọ fún un pé: “A máa fi ẹ̀mí wa dí tiyín!* Tí o kò bá sọ ohun tí a wá ṣe, a máa fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ hàn, a sì máa jẹ́ olóòótọ́ sí ọ nígbà tí Jèhófà bá fún wa ní ilẹ̀ náà.” 15 Lẹ́yìn náà, ó fi okùn sọ̀ wọ́n kalẹ̀ láti ojú fèrèsé,* torí pé ẹ̀gbẹ́ kan lára ògiri ìlú náà ni ilé rẹ̀ wà. Kódà, orí ògiri náà ló ń gbé.+ 16 Ó wá sọ fún wọn pé: “Ẹ lọ sí agbègbè olókè, kí ẹ sì sá pa mọ́ síbẹ̀ fún ọjọ́ mẹ́ta, kí àwọn tó ń wá yín má bàa rí yín. Tí àwọn tó ń wá yín bá pa dà dé ni kí ẹ tó máa lọ.”
17 Àwọn ọkùnrin náà sọ fún un pé: “A ò ní jẹ̀bi ìbúra tí o mú ká ṣe yìí+ 18 àfi tí a bá dé ilẹ̀ yìí, tí o sì ti so okùn aláwọ̀ rírẹ̀dòdò yìí mọ́ ojú fèrèsé tí o gbà sọ̀ wá kalẹ̀. Kí o mú bàbá rẹ, ìyá rẹ, àwọn arákùnrin rẹ àti gbogbo agbo ilé bàbá rẹ wá sọ́dọ̀ rẹ nínú ilé.+ 19 Tí ẹnikẹ́ni bá wá kúrò nínú ilé rẹ, tó sì jáde sí ìta, òun fúnra rẹ̀ ló máa jẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ rẹ̀, ẹ̀bi náà ò ní sí lọ́rùn wa. Àmọ́ tí aburú bá ṣe* ẹnikẹ́ni tó wà nínú ilé lọ́dọ̀ rẹ, ẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ máa wà lọ́rùn wa. 20 Ṣùgbọ́n tí o bá sọ ohun tí a wá ṣe,+ a ò ní jẹ̀bi ìbúra tí o mú ká ṣe yìí.” 21 Ó fèsì pé: “Kó rí bí ẹ ṣe sọ gẹ́lẹ́.”
Ó wá ní kí wọ́n máa lọ, wọ́n sì lọ. Lẹ́yìn náà, ó so okùn aláwọ̀ rírẹ̀dòdò náà mọ́ ojú fèrèsé náà. 22 Ni wọ́n bá kúrò níbẹ̀, wọ́n lọ sí agbègbè olókè, wọ́n sì dúró síbẹ̀ fún ọjọ́ mẹ́ta, títí àwọn tó wá wọn lọ fi pa dà dé. Àwọn yìí ti wá wọn ní gbogbo ojú ọ̀nà, àmọ́ wọn ò rí wọn. 23 Àwọn ọkùnrin méjèèjì wá sọ̀ kalẹ̀ láti agbègbè olókè, wọ́n sì sọdá odò lọ bá Jóṣúà ọmọ Núnì. Wọ́n ròyìn gbogbo ohun tó ṣẹlẹ̀ sí wọn fún un. 24 Wọ́n sọ fún Jóṣúà pé: “Jèhófà ti fi gbogbo ilẹ̀ náà lé wa lọ́wọ́.+ Kódà, ọkàn gbogbo àwọn tó ń gbé ilẹ̀ náà ti domi nítorí wa.”+