Ẹ́sítà
7 Nígbà náà, ọba àti Hámánì+ wá sí ibi àsè Ẹ́sítà Ayaba. 2 Ọba tún béèrè lọ́wọ́ Ẹ́sítà ní ọjọ́ kejì nígbà tí wọ́n ń mu wáìnì lọ́wọ́ pé: “Ẹ́sítà Ayaba, kí lo fẹ́ tọrọ? A ó fi fún ọ. Kí lo sì fẹ́ béèrè? Kódà tí ó bá tó* ìdajì ìjọba mi, a ó ṣe é fún ọ!”+ 3 Ẹ́sítà Ayaba fèsì pé: “Tí mo bá rí ojú rere rẹ, ọba, tó bá sì wu ọba, ohun tí mo fẹ́ tọrọ ni pé kí a fún mi ní ẹ̀mí* mi, ohun tí mo sì fẹ́ béèrè ni pé kí a fún mi ní àwọn èèyàn mi.+ 4 Nítorí wọ́n ti ta+ èmi àti àwọn èèyàn mi, láti pa wá, láti run wá àti láti pa wá rẹ́.+ Ká ní wọ́n kàn tà wá bí ẹrúkùnrin àti ẹrúbìnrin nìkan ni, mi ò bá dákẹ́. Àmọ́ àjálù náà kò ní bọ́ sí i rárá torí pé ó máa pa ọba lára.”
5 Ọba Ahasuérúsì wá béèrè lọ́wọ́ Ẹ́sítà Ayaba pé: “Ta ni? Ibo lẹni tó gbójúgbóyà ṣerú èyí wà?” 6 Ẹ́sítà sọ pé: “Elénìní àti ọ̀tá náà ni Hámánì olubi yìí.”
Jìnnìjìnnì bo Hámánì nítorí ọba àti ayaba. 7 Ọba fi ìbínú dìde kúrò nídìí wáìnì, ó sì lọ sí ọgbà ààfin, àmọ́ Hámánì dìde láti bẹ Ẹ́sítà Ayaba nítorí ẹ̀mí* rẹ̀, torí ó mọ̀ pé ọba ti pinnu láti fìyà jẹ òun. 8 Ọba pa dà wá láti ọgbà ààfin sí ilé tí wọ́n ti ń mu wáìnì, ó sì rí Hámánì tó nà lé àga tìmùtìmù tí Ẹ́sítà wà. Ọba kọ hàà pé: “Ṣé ó tún fẹ́ fipá bá ayaba lò pọ̀ nínú ilé mi ni?” Bí ọba ṣe sọ ọ̀rọ̀ yìí tán, wọ́n bo Hámánì lójú. 9 Hábónà,+ ọ̀kan lára àwọn òṣìṣẹ́ ààfin ọba wá sọ pé: “Hámánì tún ṣe òpó igi kan fún Módékáì,+ ẹni tó sọ ohun tó gba ọba sílẹ̀.+ Òpó náà wà ní òró ní ilé Hámánì, àádọ́ta (50) ìgbọ̀nwọ́* ni gíga rẹ̀.” Ni ọba bá sọ pé: “Ẹ gbé e kọ́ sórí rẹ̀.” 10 Torí náà, wọ́n gbé Hámánì kọ́ sórí òpó igi tó ṣe fún Módékáì, ìbínú ọba sì rọlẹ̀.