Sáàmù
Sí olùdarí; lọ́nà ti Máhálátì.* Másíkílì.* Ti Dáfídì.
“Kò sí Jèhófà.”+
Ìwà àìtọ́ wọn burú, ó sì jẹ́ ohun ìríra;
Kò sí ẹni tó ń ṣe rere.+
2 Àmọ́ Ọlọ́run ń bojú wo àwọn ọmọ èèyàn láti ọ̀run+
Láti rí i bóyá ẹnì kan wà tó ní ìjìnlẹ̀ òye, bóyá ẹnì kan wà tó ń wá Jèhófà.+
3 Gbogbo wọn ti kúrò lójú ọ̀nà;
Gbogbo wọn jẹ́ oníwà ìbàjẹ́.
Kò sí ẹni tó ń ṣe rere,
Kò tiẹ̀ sí ẹyọ kan.+
4 Ṣé kò yé ìkankan lára àwọn oníwà burúkú ni?
Wọ́n ń ya àwọn èèyàn mi jẹ bí ẹni ń jẹ búrẹ́dì.
Wọn ò ké pe Jèhófà.+
5 Àmọ́, jìnnìjìnnì á bò wọ́n,
Irú èyí tí kò ṣẹlẹ̀ sí wọn rí,*
Ọlọ́run yóò tú egungun àwọn tó ń gbéjà kò ọ́* ká.
Wàá dójú tì wọ́n, nítorí Jèhófà ti kọ̀ wọ́n sílẹ̀.
6 Ká ní ìgbàlà Ísírẹ́lì lè wá láti Síónì ni!+
Nígbà tí Jèhófà bá kó àwọn èèyàn rẹ̀ tó wà lóko ẹrú pa dà,
Kí inú Jékọ́bù dùn, kí Ísírẹ́lì sì yọ̀.