Diutarónómì
19 “Tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ bá ti pa àwọn orílẹ̀-èdè yìí run, ìyẹn àwọn tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ fẹ́ fún ọ ní ilẹ̀ wọn, tí o ti lé wọn kúrò, tí o sì ti ń gbé inú àwọn ìlú wọn àti ilé wọn,+ 2 kí o ya ìlú mẹ́ta sọ́tọ̀ láàárín ilẹ̀ tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ fẹ́ fún ọ pé kó di tìrẹ.+ 3 Kí o pín àwọn ilẹ̀ tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ fún ọ pé kó di tìrẹ sí ọ̀nà mẹ́ta, kí o sì ṣe àwọn ọ̀nà, kí ẹnikẹ́ni tó bá pààyàn lè sá lọ sí ọ̀kan nínú àwọn ìlú náà.
4 “Ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sí apààyàn tó bá sá lọ síbẹ̀ kó má bàa kú nìyí: Tó bá ṣèèṣì pa ẹnì kejì rẹ̀, tí kò sì kórìíra rẹ̀ tẹ́lẹ̀;+ 5 bóyá òun àti ẹnì kejì rẹ̀ jọ lọ ṣa igi nínú igbó, tó wá gbé àáké sókè láti gé igi, àmọ́ tí irin àáké náà fò yọ, tó ba ẹnì kejì rẹ̀, tó sì kú, kí apààyàn náà sá lọ sí ọ̀kan lára àwọn ìlú yìí, kó má bàa kú.+ 6 Àìjẹ́ bẹ́ẹ̀, ẹni tó ń gbẹ̀san ẹ̀jẹ̀+ lè fi ìbínú* lé apààyàn náà bá, kó sì pa á, torí pé ọ̀nà ìlú náà ti jìn jù. Àmọ́ kò yẹ kó pa á, torí pé kò kórìíra ẹnì kejì rẹ̀ tẹ́lẹ̀.+ 7 Ìdí nìyẹn tí mo fi ń pa á láṣẹ fún ọ pé: ‘Ya ìlú mẹ́ta sọ́tọ̀.’
8 “Tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ bá mú kí ilẹ̀ rẹ pọ̀ sí i bó ṣe búra fún àwọn baba ńlá rẹ,+ tó sì ti fún ọ ní gbogbo ilẹ̀ tó ṣèlérí pé òun máa fún àwọn baba ńlá rẹ,+ 9 tí o bá ṣáà ti pa gbogbo àṣẹ yìí tí mò ń fún ọ lónìí mọ́ délẹ̀délẹ̀, pé kí o nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run rẹ, kí o sì máa rìn ní àwọn ọ̀nà rẹ̀ nígbà gbogbo,+ kí o fi ìlú mẹ́ta míì kún àwọn mẹ́ta yìí.+ 10 Èyí ò ní jẹ́ kí o ta ẹ̀jẹ̀ ẹni tí kò jẹ̀bi sílẹ̀+ ní ilẹ̀ tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ máa fún ọ pé kí o jogún, o ò sì ní jẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ kankan.+
11 “Àmọ́ tí ọkùnrin kan bá kórìíra ẹnì kejì rẹ̀,+ tó lúgọ dè é, tó ṣe é léṣe,* tó sì kú, tí ọkùnrin náà sì sá lọ sí ọ̀kan nínú àwọn ìlú yìí, 12 kí àwọn àgbààgbà ìlú rẹ̀ ránṣẹ́ pè é láti ibẹ̀, kí wọ́n sì fà á lé ẹni tó ń gbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ lọ́wọ́, ó gbọ́dọ̀ kú.+ 13 O* ò gbọ́dọ̀ káàánú rẹ̀, ṣe ni kí o mú ẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ ẹni tí kò mọwọ́ mẹsẹ̀ kúrò ní Ísírẹ́lì,+ kí nǹkan lè máa lọ dáadáa fún ọ.
14 “Tí o bá gba ogún rẹ ní ilẹ̀ tí Jèhófà Ọlọ́run fẹ́ fún ọ pé kó di tìrẹ, o ò gbọ́dọ̀ sún ààlà ọmọnìkejì rẹ sẹ́yìn + kúrò níbi tí àwọn baba ńlá fi sí.
15 “Ẹlẹ́rìí kan ṣoṣo kò tó láti dá ẹnì kan lẹ́bi* àṣìṣe tàbí ẹ̀ṣẹ̀ èyíkéyìí tó dá.+ Nípa ẹ̀rí* ẹni méjì tàbí ẹ̀rí ẹni mẹ́ta, kí ẹ fìdí ọ̀rọ̀ náà múlẹ̀.+ 16 Tí ẹlẹ́rìí èké kan bá jẹ́rìí lòdì sí ẹnì kan, tó sì fẹ̀sùn kàn án pé ó ṣe ohun tí kò dáa,+ 17 kí àwọn méjèèjì tó ń bára wọn fa ọ̀rọ̀ wá dúró níwájú Jèhófà, níwájú àwọn àlùfáà àti àwọn adájọ́ tí wọ́n á máa dájọ́ nígbà yẹn.+ 18 Kí àwọn adájọ́ náà wádìí ọ̀rọ̀ náà dáadáa,+ tó bá jẹ́ ẹlẹ́rìí èké ni ẹni tó jẹ́rìí sí ọ̀rọ̀ náà, tó sì fẹ̀sùn èké kan arákùnrin rẹ̀, 19 ohun tó gbèrò láti ṣe sí arákùnrin rẹ̀ ni kí ẹ ṣe sí i,+ kí ẹ sì mú ohun tó burú kúrò láàárín yín.+ 20 Tí àwọn yòókù bá gbọ́, ẹ̀rù á bà wọ́n, wọn ò sì ní ṣe irú ohun tó burú bẹ́ẹ̀ mọ́ láé láàárín rẹ.+ 21 O* ò gbọ́dọ̀ káàánú rẹ̀:+ Kí o gba ẹ̀mí* dípò ẹ̀mí,* ojú dípò ojú, eyín dípò eyín, ọwọ́ dípò ọwọ́, ẹsẹ̀ dípò ẹsẹ̀.+