Jóṣúà
23 Lẹ́yìn ọ̀pọ̀ ọjọ́ tí Jèhófà ti fún Ísírẹ́lì ní ìsinmi+ lọ́wọ́ gbogbo àwọn ọ̀tá tó yí wọn ká, tí Jóṣúà ti darúgbó, tó sì ti lọ́jọ́ lórí,+ 2 Jóṣúà pe gbogbo Ísírẹ́lì jọ,+ àwọn àgbààgbà wọn, àwọn olórí, àwọn onídàájọ́ àtàwọn aṣojú wọn,+ ó sì sọ fún wọn pé: “Mo ti darúgbó; mo sì ti lọ́jọ́ lórí. 3 Ẹ̀yin fúnra yín ti rí gbogbo ohun tí Jèhófà Ọlọ́run yín ṣe sí gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè yìí nítorí yín, torí pé Jèhófà Ọlọ́run yín ló ń jà fún yín.+ 4 Ẹ wò ó, mo fi kèké+ pín* ilẹ̀ àwọn orílẹ̀-èdè tó ṣẹ́ kù fún yín pé kó jẹ́ ogún àwọn ẹ̀yà yín,+ mo sì tún pín ilẹ̀ gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè tí mo pa run fún yín,+ láti Jọ́dánì dé Òkun Ńlá* ní ìwọ̀ oòrùn.* 5 Jèhófà Ọlọ́run yín ló ń tì wọ́n kúrò níwájú yín, ó lé wọn kúrò* fún yín,+ ẹ sì gba ilẹ̀ wọn, bí Jèhófà Ọlọ́run yín ti ṣèlérí fún yín gẹ́lẹ́.+
6 “Torí náà, ẹ jẹ́ onígboyà gidigidi kí ẹ lè máa pa gbogbo ohun tí a kọ sínú ìwé Òfin+ Mósè mọ́, kí ẹ sì máa tẹ̀ lé e, kí ẹ má ṣe yà kúrò nínú rẹ̀ sí ọ̀tún tàbí sí òsì,+ 7 ẹ má ṣe bá àwọn orílẹ̀-èdè tó ṣẹ́ kù pẹ̀lú yín yìí ṣe wọlé-wọ̀de.+ Ẹ ò tiẹ̀ gbọ́dọ̀ dárúkọ àwọn ọlọ́run wọn,+ ẹ ò gbọ́dọ̀ fi wọ́n búra, ẹ ò gbọ́dọ̀ sìn wọ́n láé, ẹ ò sì gbọ́dọ̀ forí balẹ̀ fún wọn.+ 8 Àmọ́ kí ẹ rọ̀ mọ́ Jèhófà Ọlọ́run yín,+ bí ẹ ṣe ṣe títí dòní. 9 Jèhófà máa lé àwọn orílẹ̀-èdè tó tóbi tó sì lágbára kúrò níwájú yín,+ torí kò tíì sí ẹni tó lè dojú kọ yín títí dòní.+ 10 Ẹnì kan péré nínú yín máa lé ẹgbẹ̀rún (1,000),+ torí Jèhófà Ọlọ́run yín ń jà fún yín+ bó ṣe ṣèlérí fún yín.+ 11 Torí náà, ẹ máa ṣọ́ra ní gbogbo ìgbà,*+ kí ẹ máa nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run yín.+
12 “Àmọ́ tí ẹ bá yí pa dà pẹ́nrẹ́n, tí ẹ sì rọ̀ mọ́ ìyókù àwọn orílẹ̀-èdè yìí, tí wọ́n ṣẹ́ kù+ pẹ̀lú yín, tí ẹ bá wọn dána,*+ tí ẹ sì ń bára yín ṣọ̀rẹ́, 13 kí ẹ mọ̀ dájú pé Jèhófà Ọlọ́run yín kò ní bá yín lé àwọn orílẹ̀-èdè yìí kúrò* mọ́.+ Wọ́n máa di pańpẹ́ àti ìdẹkùn fún yín, wọ́n máa di pàṣán ní ẹ̀gbẹ́ yín+ àti ẹ̀gún ní ojú yín, títí ẹ fi máa pa run lórí ilẹ̀ dáradára tí Jèhófà Ọlọ́run yín fún yín.
14 “Ẹ wò ó! Mi ò ní pẹ́ kú,* ẹ sì mọ̀ dáadáa pẹ̀lú gbogbo ọkàn yín àti gbogbo ara* yín pé kò sí ìkankan nínú gbogbo ìlérí tó dáa tí Jèhófà Ọlọ́run yín ṣe fún yín tí kò ṣẹ. Gbogbo wọn ló ṣẹ fún yín. Ìkankan nínú wọn ò kùnà.+ 15 Àmọ́ bí gbogbo ìlérí tó dáa tí Jèhófà Ọlọ́run yín ṣe fún yín ṣe ṣẹ sí yín lára,+ bẹ́ẹ̀ ni Jèhófà máa mú gbogbo àjálù tó ṣèlérí* wá sórí yín, ó sì máa pa yín run lórí ilẹ̀ dáradára tí Jèhófà Ọlọ́run yín fún yín.+ 16 Tí ẹ bá da májẹ̀mú Jèhófà Ọlọ́run yín tó pa láṣẹ pé kí ẹ máa pa mọ́, tí ẹ bá sì lọ ń sin àwọn ọlọ́run míì, tí ẹ̀ ń forí balẹ̀ fún wọn, Jèhófà máa bínú sí yín gidigidi,+ ẹ sì máa pa run kíákíá lórí ilẹ̀ dáradára tó fún yín.”+