Sáàmù
115 Kì í ṣe àwa, Jèhófà, kì í ṣe àwa,*
Àmọ́ orúkọ rẹ ni ògo yẹ+
Nítorí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ àti òtítọ́ rẹ.+
2 Ṣé ó yẹ kí àwọn orílẹ̀-èdè sọ pé:
“Ọlọ́run wọn dà?”+
3 Ọlọ́run wa wà ní ọ̀run;
Ó ń ṣe ohun tí ó bá fẹ́.
4 Àwọn òrìṣà wọn jẹ́ fàdákà àti wúrà,
Iṣẹ́ ọwọ́ èèyàn.+
5 Wọ́n ní ẹnu, àmọ́ wọn ò lè sọ̀rọ̀;+
Wọ́n ní ojú, àmọ́ wọn ò lè ríran;
6 Wọ́n ní etí, àmọ́ wọn ò lè gbọ́ràn;
Wọ́n ní imú, àmọ́ wọn ò lè gbóòórùn;
7 Wọ́n ní ọwọ́, àmọ́ wọn ò lè fọwọ́ ba nǹkan;
Wọ́n ní ẹsẹ̀, àmọ́ wọn ò lè rìn;+
Wọn ò lè mú ìró kankan jáde láti ọ̀fun wọn.+
8 Àwọn tó ń ṣe wọ́n yóò dà bíi wọn gẹ́lẹ́,+
Bẹ́ẹ̀ ló sì ṣe máa rí fún gbogbo àwọn tó gbẹ́kẹ̀ lé wọn.+
10 Ilé Áárónì,+ ẹ gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà
—Òun ni olùrànlọ́wọ́ wọn àti apata wọn.
13 Á bù kún àwọn tó bẹ̀rù Jèhófà,
Àti ẹni kékeré àti ẹni ńlá.
18 Àmọ́ a ó máa yin Jáà
Láti ìsinsìnyí lọ àti títí láé.
Ẹ yin Jáà!*