Sáàmù
Sí olùdarí; kí a yí i sí “Àdàbà Tó Dákẹ́ Tó Jìnnà Réré.” Ti Dáfídì. Míkítámù.* Nígbà tí àwọn Filísínì mú un ní Gátì.+
56 Ṣojú rere sí mi, Ọlọ́run, nítorí ẹni kíkú ń gbéjà kò mí.*
Láti àárọ̀ ṣúlẹ̀, wọ́n ń bá mi jà, wọ́n sì ń ni mí lára.
2 Àwọn ọ̀tá mi ń kù gìrì mọ́ mi láti àárọ̀ ṣúlẹ̀;
Ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń gbéra ga sí mi, tí wọ́n sì ń bá mi jà.
3 Nígbà tí ẹ̀rù ń bà mí,+ mo gbẹ́kẹ̀ lé ọ.+
4 Ìwọ Ọlọ́run, ẹni tí mò ń yin ọ̀rọ̀ rẹ̀,
Ìwọ ni mo gbẹ́kẹ̀ lé; ẹ̀rù ò bà mí.
Kí ni èèyàn* lásánlàsàn lè fi mí ṣe?+
5 Láti àárọ̀ ṣúlẹ̀, wọn ò jẹ́ kí n gbádùn ayé mi;
Bí wọ́n ṣe máa ṣe mí léṣe ni wọ́n ń rò ṣáá.+
6 Wọ́n fara pa mọ́ láti gbéjà kò mí;
Wọ́n ń ṣọ́ gbogbo ìrìn ẹsẹ̀ mi,+
7 Kọ̀ wọ́n sílẹ̀ nítorí ìwà ìkà wọn.
Mú àwọn orílẹ̀-èdè balẹ̀ nínú ìbínú rẹ, Ọlọ́run.+
8 Ò ń kíyè sí bí mo ṣe ń rìn kiri.+
Gba omijé mi sínú ìgò awọ rẹ.+
Ǹjẹ́ kò wà lákọsílẹ̀ nínú ìwé rẹ?+
9 Àwọn ọ̀tá mi á sá pa dà ní ọjọ́ tí mo bá ké pè ọ́ fún ìrànlọ́wọ́.+
Ó dá mi lójú pé: Ọlọ́run wà pẹ̀lú mi.+
10 Ìwọ Ọlọ́run, ẹni tí mò ń yin ọ̀rọ̀ rẹ̀,
Ìwọ Jèhófà, ẹni tí mò ń yin ọ̀rọ̀ rẹ̀,
11 Ìwọ Ọlọ́run ni mo gbẹ́kẹ̀ lé; ẹ̀rù ò bà mí.+
Kí ni èèyàn lásánlàsàn lè fi mí ṣe?+
Kí n lè máa rìn níwájú Ọlọ́run nínú ìmọ́lẹ̀ alààyè.+