Hósíà
13 “Nígbà tí Éfúrémù sọ̀rọ̀, ẹ̀rù ba àwọn èèyàn;
Torí pé ẹni ńlá ni ní Ísírẹ́lì.+
Àmọ́, ó jẹ̀bi nítorí ó sin Báálì,+ ó sì kú.
2 Ní báyìí, wọ́n dá ẹ̀ṣẹ̀ kún ẹ̀ṣẹ̀
Wọ́n sì fi fàdákà+ wọn ṣe ère onírin;*
Wọ́n ṣe àwọn òrìṣà lọ́nà tó já fáfá, gbogbo rẹ̀ sì jẹ́ ohun tí oníṣẹ́ ọnà ṣe.
Wọ́n sọ nípa wọn pé, ‘Kí àwọn tó wá rúbọ fi ẹnu ko àwọn ọmọ màlúù lẹ́nu.’+
3 Torí náà, wọ́n á dà bí ìkùukùu òwúrọ̀,
Bí ìrì tó tètè ń pòórá,
Bí ìyàngbò* tí ìjì gbé lọ kúrò ní ibi ìpakà
Àti bí èéfín tó jáde látinú ihò òrùlé.
4 Ṣùgbọ́n èmi ni Jèhófà Ọlọ́run rẹ láti ilẹ̀ Íjíbítì wá;+
Ìwọ kò sì mọ Ọlọ́run mìíràn àfi èmi,
Lẹ́yìn mi kò sí olùgbàlà kankan.+
5 Mo mọ̀ ọ́ ní aginjù,+ ní ilẹ̀ aláìlómi.
Torí náà, wọ́n gbàgbé mi.+
7 Màá dà bí ọmọ kìnnìún sí wọn,+
Bí àmọ̀tẹ́kùn tó lúgọ sí ẹ̀gbẹ́ ọ̀nà.
8 Màá bẹ́ mọ́ wọn bíi bíárì tí àwọn ọmọ rẹ̀ sọ nù,
Màá sì fa àyà* wọn ya.
Màá jẹ wọ́n níbẹ̀ bíi kìnnìún;
Ẹran inú igbó yóò fà wọ́n ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ.
9 Yóò pa ọ́ run, ìwọ Ísírẹ́lì,
Torí pé o ti kẹ̀yìn sí èmi olùrànlọ́wọ́ rẹ.
10 Ibo wá ni ọba rẹ wà, kí ó lè gbà ọ́ ní gbogbo ìlú rẹ+
Àti àwọn alákòóso* rẹ, tí o sọ nípa wọn pé,
‘Fún mi ní ọba àti àwọn ìjòyè’?+
12 A ti di* àṣìṣe Éfúrémù pa mọ́;
A sì ti to ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ jọ.
13 Ìrora ìgbà ìbímọ yóò dé bá a.
Àmọ́, ọmọ tí kò gbọ́n ni;
Ó kọ̀ láti jáde nígbà tí ìyá rẹ̀ fẹ́ bí i.
Ìwọ Ikú, oró rẹ dà?+
Ìwọ Isà Òkú, ìpanirun rẹ dà?+
Síbẹ̀, mi ò ní fojú àánú wò wọ́n.*
15 Bó bá tiẹ̀ gbilẹ̀ láàárín àwọn esùsú,*
Ẹ̀fúùfù ìlà oòrùn yóò wá, ẹ̀fúùfù Jèhófà,
Yóò wá láti aṣálẹ̀, yóò sì mú kí kànga àti odò rẹ̀ gbẹ.
Ẹnì kan máa wá kó gbogbo ohun iyebíye tó wà ní ilé ìṣúra rẹ̀.+
16 A ó dá Samáríà lẹ́bi,+ torí pé ó ti ṣọ̀tẹ̀ sí Ọlọ́run rẹ̀.+