Sáàmù
Sí olùdarí. Ti àwọn ọmọ Kórà.+ Orin.
47 Gbogbo ẹ̀yin èèyàn, ẹ pàtẹ́wọ́.
Ẹ fi ayọ̀ kígbe ìṣẹ́gun sí Ọlọ́run.
3 Ó tẹ àwọn èèyàn lórí ba lábẹ́ wa;
Ó fi àwọn orílẹ̀-èdè sábẹ́ ẹsẹ̀ wa.+
5 Ọlọ́run ti gòkè nígbà tí àwọn èèyàn ń kígbe ayọ̀,
Jèhófà ti gòkè nígbà tí àwọn èèyàn ń fun ìwo.*
6 Ẹ kọ orin ìyìn* sí Ọlọ́run, ẹ kọ orin ìyìn.
Ẹ kọ orin ìyìn sí Ọba wa, ẹ kọ orin ìyìn.
7 Nítorí Ọlọ́run ni Ọba gbogbo ayé;+
Ẹ kọ orin ìyìn, kí ẹ sì fi ìjìnlẹ̀ òye hàn.
8 Ọlọ́run ti di Ọba lórí àwọn orílẹ̀-èdè.+
Ọlọ́run jókòó lórí ìtẹ́ mímọ́ rẹ̀.
9 Àwọn olórí àwọn èèyàn ti kóra jọ
Pẹ̀lú àwọn èèyàn Ọlọ́run Ábúráhámù.
Nítorí àwọn alákòóso* ayé jẹ́ ti Ọlọ́run.
A ti gbé e ga sókè.+