Sí olùdarí. Orin Dáfídì. Orin.
65 Ọlọ́run, ìyìn ń dúró dè ọ́ ní Síónì;+
A ó san ẹ̀jẹ́ wa fún ọ.+
2 Ìwọ Olùgbọ́ àdúrà, ọ̀dọ̀ rẹ ni onírúurú èèyàn yóò wá.+
3 Àwọn àṣìṣe mi ti bò mí mọ́lẹ̀,+
Àmọ́, o dárí àwọn ìṣìnà wa jì wá.+
4 Aláyọ̀ ni ẹni tí o yàn, tí o sì mú wá sọ́dọ̀ rẹ
Kí ó lè máa gbé inú àwọn àgbàlá rẹ.+
Àwọn ohun rere inú ilé rẹ yóò tẹ́ wa lọ́rùn,+
Ìyẹn àwọn ohun inú tẹ́ńpìlì mímọ́ rẹ.+
5 Wàá fi àwọn iṣẹ́ òdodo tó jẹ́ àgbàyanu dá wa lóhùn,+
Ìwọ Ọlọ́run ìgbàlà wa;
Ìwọ ni Ìgbẹ́kẹ̀lé gbogbo ayé+
Àti ti àwọn tó jìnnà réré lórí òkun.
6 O fìdí àwọn òkè múlẹ̀ ṣinṣin nípasẹ̀ agbára rẹ;
O gbé agbára ńlá wọ̀ bí aṣọ.+
7 O mú kí àwọn òkun tó ń ru gùdù rọlẹ̀+
Pẹ̀lú ariwo ìgbì wọn àti rúkèrúdò àwọn orílẹ̀-èdè.+
8 Àwọn iṣẹ́ àmì rẹ yóò mú kí ẹ̀rù rẹ ba àwọn tó ń gbé ibi tó jìnnà;+
Wàá mú kí àwọn tó wà ní ìlà oòrùn títí dé ìwọ̀ oòrùn kígbe ayọ̀.
9 Ò ń bójú tó ayé,
O mú kí ó ní ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ èso, kí ilẹ̀ rẹ̀ sì lọ́ràá dáadáa.+
Omi kún inú odò Ọlọ́run;
O pèsè oúnjẹ fún wọn,+
Nítorí bí o ṣe ṣètò ayé nìyẹn.
10 O fi omi rin àwọn poro rẹ̀, o sì mú kí ilẹ̀ rẹ̀ tí a tú tẹ́jú;
O fi ọ̀wààrà òjò mú un dẹ̀; o mú kí ọ̀gbìn rẹ̀ dàgbà.+
11 O fi oore rẹ dé ọdún ládé;
Àwọn ohun rere kún ojú ọ̀nà rẹ rẹpẹtẹ.+
12 Àwọn ibi ìjẹko tó wà ní aginjù kún,+
Àwọn òkè kéékèèké gbé ìdùnnú wọ̀ bí aṣọ.+
13 Àwọn agbo ẹran bo ibi ìjẹko,
Ọkà sì bo àwọn àfonífojì.+
Wọ́n ń kígbe ìṣẹ́gun, bẹ́ẹ̀ ni, wọ́n ń kọrin.+