Òwe
31 Àwọn ọ̀rọ̀ Ọba Lémúẹ́lì, ọ̀rọ̀ pàtàkì tí ìyá rẹ̀ fi dá a lẹ́kọ̀ọ́:+
4 Lémúẹ́lì, kò tọ́ sí àwọn ọba,
Kò tọ́ kí àwọn ọba máa mu wáìnì
Tàbí kí àwọn alákòóso máa sọ pé, “Ọtí mi dà?”+
5 Kí wọ́n má bàa mutí tán, kí wọ́n wá gbàgbé àṣẹ tó wà nílẹ̀,
Kí wọ́n sì fi ẹ̀tọ́ àwọn aláìní dù wọ́n.
7 Kí wọ́n mu, kí wọ́n gbàgbé ipò òṣì wọn;
Kí wọ́n má sì rántí ìdààmú wọn mọ́.
8 Gba ọ̀rọ̀ sọ fún ẹni tí kò lè sọ̀rọ̀;
Gbèjà ẹ̀tọ́ gbogbo àwọn tó ń kú lọ.+
א [Áléfì]
10 Ta ló ti rí aya tó dáńgájíá?*+
Ó níye lórí lọ́pọ̀lọpọ̀ ju iyùn.*
ב [Bétì]
ג [Gímélì]
12 Ohun rere ni obìnrin náà fi ń san án lẹ́san, kì í ṣe búburú,
Ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀.*
ד [Dálétì]
ה [Híì]
ו [Wọ́ọ̀]
15 Bákan náà, ó máa ń dìde nígbà tí ilẹ̀ kò tíì mọ́,
Láti wá oúnjẹ sílẹ̀ fún agbo ilé rẹ̀
Àti èyí tó máa fún àwọn ìránṣẹ́bìnrin rẹ̀.+
ז [Sáyìn]
ח [Hétì]
ט [Tétì]
18 Ó rí i pé òwò òun ń mérè wọlé;
Fìtílà rẹ̀ kì í kú ní òru.
י [Yódì]
כ [Káfì]
20 Ó la àtẹ́lẹwọ́ rẹ̀ sí aláìní,
Ó sì la ọwọ́ rẹ̀ sí àwọn tálákà.+
ל [Lámédì]
21 Kò dààmú nípa agbo ilé rẹ̀ pé yìnyín ń já bọ́,
Nítorí pé gbogbo agbo ilé rẹ̀ ti wọ ẹ̀wù òtútù.*
מ [Mémì]
22 Ó ṣe àwọn aṣọ ìtẹ́lébùsùn rẹ̀.
Aṣọ rẹ̀ jẹ́ aṣọ ọ̀gbọ̀* àti olówùú pọ́pù.
נ [Núnì]
23 Àwọn èèyàn mọ ọkọ rẹ̀ dáadáa ní àwọn ẹnubodè ìlú,+
Níbi tó máa ń jókòó sí láàárín àwọn àgbààgbà ilẹ̀ náà.
ס [Sámékì]
ע [Áyìn]
25 Ó fi agbára àti ògo ṣe aṣọ wọ̀,
Ọkàn rẹ̀ sì balẹ̀* bó ṣe ń wo ọjọ́ iwájú.
פ [Péè]
צ [Sádì]
ק [Kófì]
28 Àwọn ọmọ rẹ̀ dìde, wọ́n sì pè é ní aláyọ̀;
Ọkọ rẹ̀ dìde, ó sì yìn ín.
ר [Réṣì]
ש [Ṣínì]
ת [Tọ́ọ̀]
31 Ẹ fún un ní èrè ohun tó ṣe,*+
Kí àwọn iṣẹ́ rẹ̀ sì máa yìn ín ní àwọn ẹnubodè ìlú.+