Diutarónómì
3 “Lẹ́yìn náà, a pa dà, a sì lọ gba Ọ̀nà Báṣánì. Ógù ọba Báṣánì àti gbogbo àwọn èèyàn rẹ̀ sì jáde wá gbéjà kò wá ní Édíréì.+ 2 Jèhófà wá sọ fún mi pé, ‘Má bẹ̀rù rẹ̀, torí màá fi òun àti gbogbo èèyàn rẹ̀ àti ilẹ̀ rẹ̀ lé ọ lọ́wọ́; ohun tí o sì ṣe sí Síhónì, ọba àwọn Ámórì tó gbé ní Hẹ́ṣíbónì ni wàá ṣe sí i.’ 3 Torí náà, Jèhófà Ọlọ́run wa tún fi Ógù ọba Báṣánì àti gbogbo èèyàn rẹ̀ lé wa lọ́wọ́, a sì bá a jà títí ìkankan nínú àwọn èèyàn rẹ̀ ò fi ṣẹ́ kù. 4 A wá gba gbogbo ìlú rẹ̀. Kò sí ìlú tí a kò gbà lọ́wọ́ wọn, ọgọ́ta (60) ìlú ní gbogbo agbègbè Ágóbù, ilẹ̀ ọba Ógù ní Báṣánì.+ 5 Gbogbo ìlú yìí ni wọ́n mọ odi gàgàrà yí ká, wọ́n ní ẹnubodè àtàwọn ọ̀pá ìdábùú, pẹ̀lú ọ̀pọ̀lọpọ̀ àrọko. 6 Àmọ́, a pa wọ́n run,+ bí a ṣe ṣe sí Síhónì ọba Hẹ́ṣíbónì gẹ́lẹ́, tí a pa gbogbo ìlú wọn run, títí kan àwọn ọkùnrin, obìnrin àtàwọn ọmọdé.+ 7 A sì kó gbogbo ẹran ọ̀sìn àtàwọn ohun tí a rí nínú ìlú náà fún ara wa.
8 “Ìgbà yẹn la gba ilẹ̀ ọba àwọn Ámórì méjèèjì + tí wọ́n wà ní agbègbè Jọ́dánì, láti Àfonífojì Áánónì títí dé Òkè Hámónì+ 9 (òkè yìí ni àwọn ọmọ Sídónì máa ń pè ní Síríónì, tí àwọn Ámórì sì máa ń pè ní Sénírì), 10 gbogbo ìlú tó wà lórí ilẹ̀ tó tẹ́jú,* gbogbo Gílíádì àti gbogbo Báṣánì títí dé Sálékà àti Édíréì,+ àwọn ìlú tó jẹ́ ti ilẹ̀ ọba Ógù ní Báṣánì. 11 Ógù ọba Báṣánì ló ṣẹ́ kù nínú àwọn Réfáímù. Irin* ni wọ́n fi ṣe àga ìgbókùú* rẹ̀, ó ṣì wà ní Rábà ti àwọn ọmọ Ámónì. Gígùn rẹ̀ jẹ́ ìgbọ̀nwọ́* mẹ́sàn-án, fífẹ̀ rẹ̀ sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́rin, wọ́n lo ìgbọ̀nwọ́ tó péye. 12 Nígbà yẹn, a gba ilẹ̀ yìí: láti Áróérì,+ èyí tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ Àfonífojì Áánónì àti ìdajì agbègbè olókè Gílíádì, mo sì ti fún àwọn ọmọ Rúbẹ́nì àti àwọn ọmọ Gádì+ ní àwọn ìlú rẹ̀. 13 Mo tún ti fún ààbọ̀ ẹ̀yà Mánásè+ ní ibi tó ṣẹ́ kù ní Gílíádì àti gbogbo Báṣánì tó jẹ́ ilẹ̀ ọba Ógù. Gbogbo agbègbè Ágóbù, tó jẹ́ ti Báṣánì, ni wọ́n mọ̀ sí ilẹ̀ àwọn Réfáímù.
14 “Jáírì+ ọmọ Mánásè gba gbogbo agbègbè Ágóbù+ títí dé ààlà àwọn ará Géṣúrì àti àwọn ará Máákátì,+ ó sì sọ àwọn abúlé Báṣánì yẹn ní orúkọ ara rẹ̀, ìyẹn Hafotu-jáírì*+ títí di òní olónìí. 15 Mo tún ti fún Mákírù ní Gílíádì.+ 16 Mo sì ti fún àwọn ọmọ Rúbẹ́nì àti àwọn ọmọ Gádì+ ní Gílíádì títí dé Àfonífojì Áánónì, àárín àfonífojì náà sì ni ààlà rẹ̀, títí lọ dé Jábókù, àfonífojì tó jẹ́ ààlà àwọn ọmọ Ámónì, 17 pẹ̀lú Árábà àti Jọ́dánì àti ààlà náà, láti Kínérétì sí Òkun Árábà, Òkun Iyọ̀,* ní ìsàlẹ̀ àwọn gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ Písígà sí apá ìlà oòrùn.+
18 “Mo wá pa àṣẹ yìí fún yín pé: ‘Jèhófà Ọlọ́run yín ti fún yín ní ilẹ̀ yìí kó lè di tiyín. Kí gbogbo ọkùnrin yín tó jẹ́ akọni gbé ohun ìjà, kí wọ́n sì sọdá níwájú àwọn arákùnrin yín, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.+ 19 Àwọn ìyàwó yín àti àwọn ọmọ yín nìkan ni yóò máa gbé inú àwọn ìlú tí mo fún yín, títí kan àwọn ẹran ọ̀sìn yín (mo mọ̀ dáadáa pé ẹ ní ẹran ọ̀sìn tó pọ̀), 20 títí Jèhófà fi máa fún àwọn arákùnrin yín ní ìsinmi, bíi tiyín, tí wọ́n á sì gba ilẹ̀ tí Jèhófà Ọlọ́run yín máa fún wọn ní òdìkejì Jọ́dánì. Lẹ́yìn náà, kí kálukú yín pa dà sí ilẹ̀ rẹ̀ tí mo fún yín.’+
21 “Mo pa àṣẹ yìí fún Jóṣúà+ nígbà yẹn pé: ‘O ti fi ojú ara rẹ rí ohun tí Jèhófà Ọlọ́run yín ṣe sí àwọn ọba méjì yìí. Ohun kan náà ni Jèhófà máa ṣe sí gbogbo ìjọba tí o máa bá pàdé tí o bá sọdá.+ 22 Ẹ ò gbọ́dọ̀ bẹ̀rù wọn, torí Jèhófà Ọlọ́run yín ló ń jà fún yín.’+
23 “Nígbà yẹn, mo bẹ Jèhófà pé, 24 ‘Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ, o ti ń fi títóbi rẹ àti ọwọ́ agbára rẹ han ìránṣẹ́ rẹ,+ àbí ọlọ́run wo ní ọ̀run tàbí ní ayé ló ń ṣe àwọn iṣẹ́ àrà bíi tìrẹ?+ 25 Jọ̀ọ́, jẹ́ kí n sọdá, kí n sì rí ilẹ̀ dáradára tó wà ní òdìkejì Jọ́dánì, agbègbè olókè tó dáa yìí àti Lẹ́bánónì.’+ 26 Àmọ́ Jèhófà ṣì ń bínú sí mi gidigidi nítorí yín,+ kò sì dá mi lóhùn. Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ni Jèhófà sọ fún mi pé, ‘Ó tó gẹ́ẹ́! O ò gbọ́dọ̀ bá mi sọ̀rọ̀ yìí mọ́. 27 Gun orí Písígà lọ,+ kí o wo ìwọ̀ oòrùn, àríwá, gúúsù àti ìlà oòrùn, kí o sì fi ojú ara rẹ rí ilẹ̀ náà, torí pé o ò ní sọdá Jọ́dánì yìí.+ 28 Fa iṣẹ́ lé Jóṣúà lọ́wọ́,+ kí o fún un ní ìṣírí, kí o sì mú un lọ́kàn le, torí òun ló máa kó àwọn èèyàn yìí sọdá,+ òun ló sì máa mú kí wọ́n jogún ilẹ̀ tí wàá rí.’ 29 Ìgbà tí à ń gbé ní àfonífojì tó wà níwájú Bẹti-péórì+ ni gbogbo èyí ṣẹlẹ̀.