Sámúẹ́lì Kìíní
9 Ọkùnrin ará Bẹ́ńjámínì kan wà tó ń jẹ́ Kíṣì,+ ọmọ Ábíélì, ọmọ Sérórì, ọmọ Békórátì, ọmọ Áfíà, ọmọ ẹ̀yà Bẹ́ńjámínì,+ ó ní ọrọ̀ gan-an. 2 Ó ní ọmọkùnrin kan tó ń jẹ́ Sọ́ọ̀lù,+ ọ̀dọ́ ni, ó sì rẹwà, kò sí ọkùnrin kankan lára àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó rẹwà tó o; tí ó bá dúró, kò sí ẹnì kankan lára àwọn èèyàn náà tó ga dé èjìká rẹ̀.
3 Nígbà tí àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́* Kíṣì bàbá Sọ́ọ̀lù sọ nù, Kíṣì sọ fún Sọ́ọ̀lù ọmọ rẹ̀ pé: “Jọ̀wọ́, mú ọ̀kan lára àwọn ìránṣẹ́ dání, kí o sì lọ wá àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà.” 4 Ni wọ́n bá gba agbègbè olókè Éfúrémù kọjá àti ilẹ̀ Ṣálíṣà, àmọ́ wọn ò rí wọn. Wọ́n rin ìrìn àjò dé ilẹ̀ Ṣáálímù, àmọ́ àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà ò sí níbẹ̀. Gbogbo ilẹ̀ àwọn ọmọ Bẹ́ńjámínì ni wọ́n dé, síbẹ̀ wọn ò rí wọn.
5 Wọ́n dé ilẹ̀ Súfì, Sọ́ọ̀lù wá sọ fún ìránṣẹ́ rẹ̀ tó wà pẹ̀lú rẹ̀ pé: “Wá, jẹ́ ká pa dà, kí bàbá mi má bàa bẹ̀rẹ̀ sí í dààmú nípa wa dípò àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà.”+ 6 Àmọ́ ìránṣẹ́ náà fèsì pé: “Wò ó, èèyàn Ọlọ́run kan wà ní ìlú yìí, ẹni iyì sì ni ọkùnrin náà. Gbogbo ohun tó bá sọ ló dájú pé á ṣẹ.+ Jẹ́ ká lọ síbẹ̀ báyìí. Bóyá ó lè sọ ibi tí a máa wá wọn sí fún wa.” 7 Ni Sọ́ọ̀lù bá sọ fún ìránṣẹ́ rẹ̀ pé: “Tí a bá máa lọ, kí ni a máa fún ọkùnrin náà? Kò sí oúnjẹ kankan nínú àpò wa; kò sí ẹ̀bùn kankan tí a lé lọ fún èèyàn Ọlọ́run tòótọ́ náà. Kí la ní lọ́wọ́?” 8 Ìránṣẹ́ náà tún dá Sọ́ọ̀lù lóhùn pé: “Wò ó! Ìdá mẹ́rin ṣékélì* fàdákà wà lọ́wọ́ mi. Màá fún èèyàn Ọlọ́run tòótọ́ náà, yóò sì sọ ibi tí a máa wá wọn sí fún wa.” 9 (Láyé àtijọ́ ní Ísírẹ́lì, ohun tí ẹni tó bá fẹ́ wá Ọlọ́run máa sọ nìyí: “Ẹ wá, ẹ jẹ́ ká lọ sọ́dọ̀ aríran.”+ Nítorí àwọn tí wọ́n ń pè ní aríran láyé àtijọ́ ni à ń pè ní wòlíì lóde òní.) 10 Sọ́ọ̀lù wá sọ fún ìránṣẹ́ rẹ̀ pé: “Ọ̀rọ̀ rẹ dára. Jẹ́ ká lọ.” Torí náà, wọ́n lọ sí ìlú tí èèyàn Ọlọ́run tòótọ́ náà wà.
11 Bí wọ́n ṣe ń gòkè lọ sí ìlú náà, wọ́n pàdé àwọn ọmọbìnrin tí wọ́n fẹ́ lọ pọn omi. Torí náà, wọ́n béèrè lọ́wọ́ wọn pé: “Ṣé aríran+ wà ní ibí yìí?” 12 Wọ́n ní: “Ó wà níbí. Ẹ wò ó, ó wà lọ́hùn-ún yẹn níwájú yín. Ẹ ṣe kíá, torí pé ó wà ní ìlú yìí lónìí, nítorí àwọn èèyàn máa rú ẹbọ+ lónìí ní ibi gíga.+ 13 Gbàrà tí ẹ bá ti wọ ìlú náà, ẹ máa rí i kó tó gòkè lọ sí ibi gíga láti jẹun. Àwọn èèyàn náà kò ní jẹun títí á fi dé, nítorí òun ló máa gbàdúrà* sí ẹbọ náà. Ẹ̀yìn ìyẹn ni àwọn tí a pè tó lè jẹun. Torí náà, ẹ tètè gòkè lọ, ẹ máa rí i.” 14 Ni wọ́n bá gòkè lọ sí ìlú náà. Bí wọ́n ṣe ń dé àárín ìlú náà, Sámúẹ́lì rèé tó ń bọ̀ wá pàdé wọn láti gòkè lọ sí ibi gíga.
15 Ní ọjọ́ tó ṣáájú ọjọ́ tí Sọ́ọ̀lù dé, Jèhófà ti sọ fún Sámúẹ́lì* pé: 16 “Ní ìwòyí ọ̀la, màá rán ọkùnrin kan láti ilẹ̀ Bẹ́ńjámínì sí ọ.+ Kí o fòróró yàn án ṣe aṣáájú lórí àwọn èèyàn mi Ísírẹ́lì,+ yóò sì gba àwọn èèyàn mi lọ́wọ́ àwọn Filísínì. Nítorí mo ti rí ìpọ́njú àwọn èèyàn mi, igbe ẹkún wọn sì ti dé ọ̀dọ̀ mi.”+ 17 Nígbà tí Sámúẹ́lì rí Sọ́ọ̀lù, Jèhófà sọ fún un pé: “Ọkùnrin tí mo sọ nípa rẹ̀ fún ọ nìyí pé, ‘Òun ló máa ṣàkóso àwọn èèyàn mi.’”*+
18 Ìgbà náà ni Sọ́ọ̀lù sún mọ́ Sámúẹ́lì ní àárín ẹnubodè, ó sì sọ pé: “Jọ̀wọ́, sọ fún mi, ibo ni ilé aríran wà?” 19 Sámúẹ́lì dá Sọ́ọ̀lù lóhùn pé: “Èmi ni aríran náà. Máa gòkè lọ níwájú mi sí ibi gíga, ẹ ó sì bá mi jẹun lónìí.+ Màá jẹ́ kí ẹ máa lọ láàárọ̀ ọ̀la, màá sì sọ gbogbo ohun tí o fẹ́ mọ̀* fún ọ. 20 Ní ti àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ tó sọ nù lọ́jọ́ mẹ́ta sẹ́yìn,+ má dààmú nípa wọn, nítorí wọ́n ti rí wọn. Ó ṣe tán, ta ló ni gbogbo ohun tó ṣeyebíye ní Ísírẹ́lì? Ǹjẹ́ kì í ṣe ìwọ àti gbogbo ilé bàbá rẹ ni?”+ 21 Ni Sọ́ọ̀lù bá dáhùn pé: “Ṣebí ọmọ Bẹ́ńjámínì tó kéré jù nínú àwọn ẹ̀yà Ísírẹ́lì ni mí,+ tó sì jẹ́ pé ìdílé mi kò já mọ́ nǹkan kan láàárín gbogbo ìdílé ẹ̀yà Bẹ́ńjámínì? Torí náà, kí nìdí tí o fi bá mi sọ irú ọ̀rọ̀ yìí?”
22 Lẹ́yìn náà, Sámúẹ́lì mú Sọ́ọ̀lù àti ìránṣẹ́ rẹ̀ wá sí gbọ̀ngàn ìjẹun, ó fi wọ́n sí àyè tó ṣe pàtàkì jù láàárín àwọn tí a pè. Nǹkan bí ọgbọ̀n (30) ọkùnrin ni wọ́n. 23 Sámúẹ́lì sọ fún alásè pé: “Mú ìpín tí mo fún ọ wá, èyí tí mo sọ fún ọ pé, ‘Fi í pa mọ́.’” 24 Ni alásè náà bá gbé ẹsẹ̀ ẹran àti àwọn ohun tó wà lórí rẹ̀ síwájú Sọ́ọ̀lù. Sámúẹ́lì sì sọ pé: “Ohun tí a tọ́jú dè ọ́ ló wà níwájú rẹ yìí. Jẹ ẹ́, nítorí àkókò pàtàkì yìí ni wọ́n ṣe tọ́jú rẹ̀ dè ọ́. Mo ti sọ fún wọn pé, ‘mò ń retí àwọn àlejò.’” Torí náà, Sọ́ọ̀lù bá Sámúẹ́lì jẹun ní ọjọ́ yẹn. 25 Lẹ́yìn náà, wọ́n sọ̀ kalẹ̀ láti ibi gíga+ lọ sí ìlú náà, ó sì ń bá Sọ́ọ̀lù sọ̀rọ̀ ní orí ilé. 26 Wọ́n dìde ní kùtùkùtù, nígbà tí ilẹ̀ sì mọ́, Sámúẹ́lì pe Sọ́ọ̀lù ní orí ilé pé: “Múra, kí n lè sìn ọ́ dé ọ̀nà.” Torí náà, Sọ́ọ̀lù múra, òun àti Sámúẹ́lì sì jáde síta. 27 Bí wọ́n ṣe ń sọ̀ kalẹ̀ lọ sí ẹ̀yìn ìlú náà, Sámúẹ́lì sọ fún Sọ́ọ̀lù pé: “Sọ fún ìránṣẹ́+ yìí pé kó kọjá síwájú wa,” torí náà, ó lọ síwájú. “Àmọ́ ìwọ, dúró sí ibí yìí, kí n lè sọ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fún ọ.”