Àìsáyà
12 Ní ọjọ́ yẹn, ó dájú pé o máa sọ pé:
“Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ, Jèhófà,
Torí bó tiẹ̀ jẹ́ pé o bínú sí mi,
Ìbínú rẹ ti wá rọlẹ̀, o sì tù mí nínú.+
2 Wò ó! Ọlọ́run ni ìgbàlà mi.+
Màá gbẹ́kẹ̀ lé e, ẹ̀rù ò sì ní bà mí;+
Torí Jáà* Jèhófà ni okun mi àti agbára mi,
Ó sì ti wá di ìgbàlà mi.”+
3 Tayọ̀tayọ̀ lẹ máa fa omi
Látinú àwọn ìsun ìgbàlà.+
4 Ní ọjọ́ yẹn, ẹ máa sọ pé:
“Ẹ fi ọpẹ́ fún Jèhófà, ẹ ké pe orúkọ rẹ̀,
Ẹ jẹ́ kí àwọn èèyàn mọ àwọn ohun tí ó ṣe!+
Ẹ kéde pé a ti gbé orúkọ rẹ̀ ga.+
5 Ẹ kọrin ìyìn sí* Jèhófà,+ torí ó ti ṣe àwọn ohun tó yani lẹ́nu.+
Ẹ jẹ́ kí gbogbo ayé mọ èyí.