Jóòbù
34 Élíhù ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ pé:
2 “Ẹ fetí sí ọ̀rọ̀ mi, ẹ̀yin ọlọ́gbọ́n;
Ẹ gbọ́ mi, ẹ̀yin tí ẹ mọ nǹkan púpọ̀.
3 Torí etí máa ń dán ọ̀rọ̀ wò,
Bí ahọ́n* ṣe ń tọ́ oúnjẹ wò.
4 Ẹ jẹ́ ká fúnra wa ṣàyẹ̀wò ohun tó tọ́;
Ẹ jẹ́ ká pinnu ohun tó dáa láàárín ara wa.
6 Ṣé màá parọ́ nípa ẹjọ́ tó yẹ kí wọ́n dá fún mi ni?
Ọgbẹ́ mi ò ṣeé wò sàn, bí mi ò tiẹ̀ dá ẹ̀ṣẹ̀ kankan.’+
7 Èèyàn míì wo ló dà bíi Jóòbù,
Tó ń mu ẹ̀gàn bí ẹni mu omi?
8 Ó ń bá àwọn aṣebi kẹ́gbẹ́,
Ó sì ń bá àwọn èèyàn burúkú ṣe wọlé wọ̀de.+
9 Torí o sọ pé, ‘Èèyàn kì í jèrè
Tó bá ń gbìyànjú láti ṣe ohun tí Ọlọ́run fẹ́.’+
10 Torí náà, ẹ fetí sí mi, ẹ̀yin tí ẹ ní òye:*
11 Torí ó máa fi ohun tí èèyàn bá ṣe san án lẹ́san,+
Ó sì máa mú kó jèrè iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀.
13 Ta ló fi ayé sí ìkáwọ́ rẹ̀,
Ta ló sì fi ṣe olórí gbogbo ayé?*
14 Tó bá fiyè* sí wọn,
Tó bá kó ẹ̀mí àti èémí wọn jọ sọ́dọ̀ ara rẹ̀,+
15 Gbogbo èèyàn* jọ máa ṣègbé,
Aráyé á sì pa dà sí erùpẹ̀.+
16 Torí náà, tí o bá ní òye, fiyè sí èyí;
Fetí sí ọ̀rọ̀ mi dáadáa.
17 Ṣé ó yẹ kí ẹni tó kórìíra ìdájọ́ òdodo jẹ́ olórí,
Àbí o máa dá alágbára tó jẹ́ olódodo lẹ́bi?
18 Ṣé o máa sọ fún ọba pé, ‘O ò wúlò fún ohunkóhun,’
Àbí fún àwọn èèyàn pàtàkì pé, ‘Ẹni burúkú ni yín’?+
19 Ẹnì kan wà tí kì í ṣe ojúsàájú àwọn olórí,
Tí kì í sì í ka ọlọ́rọ̀ sí ju aláìní lọ,*+
Torí iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀ ni gbogbo wọn.+
20 Wọ́n lè kú lójijì,+ láàárín òru;+
Wọ́n gbọ̀n rìrì, wọ́n sì gbẹ́mìí mì;
A mú àwọn alágbára pàápàá kúrò, àmọ́ kì í ṣe iṣẹ́ ọwọ́ èèyàn.+
21 Torí ojú Ọlọ́run ń wo àwọn ọ̀nà èèyàn,+
Ó sì ń rí gbogbo ìṣísẹ̀ rẹ̀.
23 Torí Ọlọ́run kò yan àkókò fún èèyàn kankan
Pé kó wá síwájú òun fún ìdájọ́.
24 Ó ń fọ́ àwọn alágbára túútúú láì ṣẹ̀ṣẹ̀ máa ṣèwádìí,
Ó sì ń fi àwọn míì rọ́pò wọn.+
26 Ó kọ lù wọ́n torí ìwà burúkú wọn,
Níbi tí gbogbo ojú ti lè rí i,+
27 Torí wọ́n ti yí pa dà, wọn ò tẹ̀ lé e mọ́,+
Wọn ò sì ka àwọn ọ̀nà rẹ̀ sí;+
28 Wọ́n mú kí àwọn aláìní ké pè é,
Tó fi gbọ́ igbe àwọn tí kò ní olùrànlọ́wọ́.+
29 Tí Ọlọ́run bá dákẹ́, ta ló lè dá a lẹ́bi?
Tó bá fojú pa mọ́, ta ló lè rí i?
Ì báà jẹ́ sí orílẹ̀-èdè tàbí èèyàn, ibì kan náà ló máa já sí,
30 Kí ẹni tí kò mọ Ọlọ́run* má bàa ṣàkóso,+
Tàbí kó dẹkùn fún àwọn èèyàn.
31 Ṣé ẹnikẹ́ni máa sọ fún Ọlọ́run pé,
‘Mo ti jìyà, bó tiẹ̀ jẹ́ pé mi ò ṣẹ̀ rárá;+
32 Jẹ́ kí n mọ ohun tí mi ò mọ̀;
Tí mo bá ti ṣe ohunkóhun tí kò dáa, mi ò ní ṣe bẹ́ẹ̀ mọ́’?
33 Ṣé ó máa san ọ́ lẹ́san bí o ṣe fẹ́, nígbà tó jẹ́ pé o kọ ìdájọ́ rẹ̀?
Ìwọ lo máa pinnu, kì í ṣe èmi.
Torí náà, sọ ohun tí o mọ̀ dáadáa fún mi.
34 Àwọn tó ní òye,* ọlọ́gbọ́n èyíkéyìí tó ń gbọ́ mi,
Máa sọ fún mi pé,
35 ‘Jóòbù ń sọ̀rọ̀ láìní ìmọ̀,+
Kò sì fi ìjìnlẹ̀ òye sọ̀rọ̀.’
36 Kí a* dán Jóòbù wò títí dé òpin,
Torí èsì rẹ̀ dà bíi ti àwọn èèyàn burúkú!