Jẹ́nẹ́sísì
28 Torí náà, Ísákì pe Jékọ́bù, ó súre fún un, ó sì pàṣẹ fún un pé: “O ò gbọ́dọ̀ fẹ́ ìyàwó láàárín àwọn ọmọ Kénáánì!+ 2 Lọ sí Padani-árámù, ní ilé Bẹ́túẹ́lì bàbá ìyá rẹ, kí o sì fẹ́ ìyàwó níbẹ̀ láàárín àwọn ọmọbìnrin Lábánì,+ arákùnrin ìyá rẹ. 3 Ọlọ́run Olódùmarè yóò bù kún ọ, yóò mú kí o bímọ tó pọ̀, yóò mú kí o pọ̀ gan-an, ó sì dájú pé ìwọ yóò di àwùjọ àwọn èèyàn.+ 4 Yóò bù kún ọ bó ṣe ṣèlérí fún Ábúráhámù,+ ìwọ àti àtọmọdọ́mọ* rẹ, kí ilẹ̀ tí ò ń gbé bí àjèjì, tí Ọlọ́run ti fún Ábúráhámù+ lè di ohun ìní rẹ.”
5 Ísákì wá ní kí Jékọ́bù máa lọ, ó sì forí lé Padani-árámù, ó lọ sọ́dọ̀ Lábánì ọmọ Bẹ́túẹ́lì ará Arémíà,+ arákùnrin Rèbékà + tó jẹ́ ìyá Jékọ́bù àti Ísọ̀.
6 Ísọ̀ mọ̀ pé Ísákì ti súre fún Jékọ́bù, ó sì ti ní kó lọ sí Padani-árámù, kó lọ fẹ́ ìyàwó níbẹ̀, ó mọ̀ pé nígbà tó súre fún un, ó pàṣẹ fún un pé: “Má lọ fẹ́ ìyàwó láàárín àwọn ọmọ Kénáánì,”+ 7 ó sì mọ̀ pé Jékọ́bù ṣe ohun tí bàbá àti ìyá rẹ̀ sọ, ó forí lé Padani-árámù.+ 8 Ìgbà yẹn ni Ísọ̀ wá rí i pé inú Ísákì+ bàbá òun ò dùn sí àwọn ọmọ Kénáánì, 9 torí náà, Ísọ̀ lọ sọ́dọ̀ Íṣímáẹ́lì ọmọ Ábúráhámù, ó sì fẹ́ Máhálátì ọmọ Íṣímáẹ́lì tó jẹ́ arábìnrin Nébáótì. Ó fẹ́ ẹ kún àwọn ìyàwó tó ti ní.+
10 Jékọ́bù kúrò ní Bíá-ṣébà, ó sì ń lọ sí agbègbè Háránì.+ 11 Nígbà tó yá, ó dé ibì kan, ó sì fẹ́ sun ibẹ̀ mọ́jú torí oòrùn ti wọ̀. Torí náà, ó gbé ọ̀kan lára àwọn òkúta tó wà níbẹ̀, ó gbé e sílẹ̀ kó lè gbórí lé e, ó sì dùbúlẹ̀ síbẹ̀.+ 12 Ó wá lá àlá, sì wò ó! àtẹ̀gùn* kan wà ní ayé, òkè rẹ̀ sì kan ọ̀run; àwọn áńgẹ́lì Ọlọ́run ń gòkè, wọ́n sì ń sọ̀ kalẹ̀ lórí rẹ̀.+ 13 Wò ó! Jèhófà wà lókè rẹ̀, ó sì sọ pé:
“Èmi ni Jèhófà Ọlọ́run Ábúráhámù bàbá rẹ àti Ọlọ́run Ísákì.+ Ìwọ àti àtọmọdọ́mọ*+ rẹ ni màá fún ní ilẹ̀ tí o dùbúlẹ̀ sí yìí. 14 Ó dájú pé àtọmọdọ́mọ* rẹ yóò pọ̀ bí erùpẹ̀ ilẹ̀,+ ìwọ yóò sì tàn káàkiri dé ìwọ̀ oòrùn àti ìlà oòrùn, dé àríwá àti gúúsù, ó sì dájú pé gbogbo ìdílé ayé yóò rí ìbùkún gbà*+ nípasẹ̀ ìwọ àti àtọmọdọ́mọ* rẹ. 15 Mo wà pẹ̀lú rẹ, màá dáàbò bò ọ́ ní gbogbo ibi tí o bá lọ, màá sì mú ọ pa dà sí ilẹ̀ yìí.+ Mi ò ní fi ọ́ sílẹ̀ títí màá fi ṣe ohun tí mo ṣèlérí fún ọ.”+
16 Jékọ́bù jí lójú oorun, ó sì sọ pé: “Jèhófà wà níbí lóòótọ́, mi ò sì mọ̀.” 17 Ẹ̀rù wá ń bà á, ó sì sọ pé: “Ibí yìí mà ń bani lẹ́rù o! Ó ní láti jẹ́ pé ilé Ọlọ́run+ ni ibí, ẹnubodè ọ̀run+ sì nìyí.” 18 Jékọ́bù wá jí ní àárọ̀ kùtù, ó sì gbé òkúta tó gbórí lé, ó gbé e dúró bí òpó, ó sì da òróró sórí rẹ̀.+ 19 Ó wá pe orúkọ ibẹ̀ ní Bẹ́tẹ́lì,* àmọ́ Lúsì+ ni ìlú náà ń jẹ́ tẹ́lẹ̀.
20 Jékọ́bù sì jẹ́ ẹ̀jẹ́ kan pé: “Tí Ọlọ́run ò bá fi mí sílẹ̀, tó dáàbò bò mí lẹ́nu ìrìn àjò mi, tó sì fún mi ní oúnjẹ tí màá jẹ àti aṣọ tí màá wọ̀, 21 tí mo sì pa dà sí ilé bàbá mi ní àlàáfíà, á jẹ́ pé Jèhófà ti fi hàn dájú pé òun ni Ọlọ́run mi. 22 Òkúta tí mo gbé kalẹ̀ bí òpó yìí yóò di ilé Ọlọ́run,+ ó sì dájú pé màá fún ọ ní ìdá mẹ́wàá gbogbo ohun tí o fún mi.”