Diutarónómì
14 “Ọmọ Jèhófà Ọlọ́run yín lẹ jẹ́. Ẹ ò gbọ́dọ̀ kọ ara yín ní abẹ+ tàbí kí ẹ fá iwájú orí yín* torí òkú.+ 2 Torí èèyàn mímọ́ lẹ jẹ́+ fún Jèhófà Ọlọ́run yín, Jèhófà sì ti yàn yín kí ẹ lè di èèyàn rẹ̀, ohun ìní rẹ̀ pàtàkì,* nínú gbogbo èèyàn tó wà láyé.+
3 “O ò gbọ́dọ̀ jẹ ohunkóhun tó ń ríni lára.+ 4 Àwọn ẹran tí ẹ lè jẹ nìyí:+ akọ màlúù, àgùntàn, ewúrẹ́, 5 àgbọ̀nrín, egbin, èsúwó, ẹ̀kìrì,* ẹtu, àgùntàn igbó àti àgùntàn orí àpáta. 6 Ẹ lè jẹ ẹran èyíkéyìí tí pátákò rẹ̀ là sí méjì, tó sì ń jẹ àpọ̀jẹ. 7 Àmọ́, ẹ ò gbọ́dọ̀ jẹ àwọn ẹran yìí tí wọ́n ń jẹ àpọ̀jẹ tàbí tí pátákò wọn là nìkan: ràkúnmí, ehoro àti gara orí àpáta, torí pé wọ́n ń jẹ àpọ̀jẹ ṣùgbọ́n pátákò wọn ò là. Aláìmọ́ ni wọ́n jẹ́ fún yín.+ 8 Bákan náà ni ẹlẹ́dẹ̀, torí pátákò rẹ̀ là, àmọ́ kì í jẹ àpọ̀jẹ. Aláìmọ́ ló jẹ́ fún yín. Ẹ ò gbọ́dọ̀ jẹ ẹran wọn, ẹ ò sì gbọ́dọ̀ fọwọ́ kan òkú wọn.
9 “Nínú gbogbo ohun tó ń gbé inú omi, èyí tí ẹ lè jẹ nìyí: Ẹ lè jẹ ohunkóhun tó bá ní lẹ́bẹ́ àti ìpẹ́.+ 10 Àmọ́ ẹ ò gbọ́dọ̀ jẹ ohunkóhun tí kò bá ní lẹ́bẹ́ àti ìpẹ́. Aláìmọ́ ló jẹ́ fún yín.
11 “Ẹ lè jẹ ẹyẹ èyíkéyìí tó bá mọ́. 12 Àmọ́ ẹ ò gbọ́dọ̀ jẹ àwọn ẹyẹ yìí: idì, idì ajẹja, igún dúdú,+ 13 àwòdì pupa, àwòdì dúdú, onírúurú ẹyẹ aṣọdẹ, 14 gbogbo onírúurú ẹyẹ ìwò, 15 ògòǹgò, òwìwí, ẹyẹ àkẹ̀, onírúurú àṣáǹwéwé, 16 òwìwí kékeré, òwìwí elétí gígùn, ògbùgbú, 17 ẹyẹ òfú, igún, ẹyẹ àgò, 18 ẹyẹ àkọ̀, onírúurú ẹyẹ wádòwádò, àgbìgbò àti àdán. 19 Gbogbo ẹ̀dá abìyẹ́ tó ń gbá yìn-ìn* pẹ̀lú jẹ́ aláìmọ́ fún yín. Ẹ ò gbọ́dọ̀ jẹ wọ́n. 20 Ẹ lè jẹ ẹ̀dá èyíkéyìí tó ń fò, tó sì mọ́.
21 “Ẹ ò gbọ́dọ̀ jẹ òkú ẹran èyíkéyìí.+ Ẹ lè fún àjèjì tó wà nínú àwọn ìlú* yín, kó sì jẹ ẹ́ tàbí kí ẹ tà á fún àjèjì. Torí pé èèyàn mímọ́ lẹ jẹ́ fún Jèhófà Ọlọ́run yín.
“Ẹ ò gbọ́dọ̀ se ọmọ ewúrẹ́ nínú wàrà ìyá rẹ̀.+
22 “O gbọ́dọ̀ rí i pé ò ń san ìdá mẹ́wàá gbogbo ohun tí irúgbìn rẹ bá ń mú jáde lọ́dọọdún.+ 23 Iwájú Jèhófà Ọlọ́run rẹ ni kí o ti máa jẹ ìdá mẹ́wàá ọkà rẹ, wáìnì tuntun rẹ, òróró rẹ àti àwọn àkọ́bí nínú ọ̀wọ́ ẹran àti agbo ẹran rẹ, ní ibi tó yàn pé kí orúkọ rẹ̀ máa wà,+ kí o lè kọ́ láti máa bẹ̀rù Jèhófà Ọlọ́run rẹ nígbà gbogbo.+
24 “Àmọ́ tí ọ̀nà ibẹ̀ bá jìn jù fún ọ, tó ò sì lè gbé e lọ sí ibi tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ yàn pé kí orúkọ rẹ̀ máa wà+ torí pé ibẹ̀ jìnnà sí ọ, (torí pé Jèhófà Ọlọ́run rẹ máa bù kún ọ,) 25 o lè sọ ọ́ di owó, kí o wá mú owó náà dání, kí o sì rìnrìn àjò lọ sí ibi tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ máa yàn. 26 O lè wá fi owó náà ra ohunkóhun tó bá wù ọ́,* bíi màlúù, àgùntàn, ewúrẹ́, wáìnì àtàwọn ohun mímu míì tó ní ọtí àti ohunkóhun tí o bá fẹ́;* kí o jẹ ẹ́ níbẹ̀ níwájú Jèhófà Ọlọ́run rẹ, kí o sì máa yọ̀, ìwọ àti agbo ilé rẹ.+ 27 O ò gbọ́dọ̀ gbàgbé ọmọ Léfì tó wà nínú àwọn ìlú rẹ,+ torí wọn ò fún un ní ìpín tàbí ogún kankan pẹ̀lú rẹ.+
28 “Ní òpin ọdún mẹ́ta-mẹ́ta, kí o kó gbogbo ìdá mẹ́wàá èso rẹ ní ọdún yẹn jáde, kí o sì kó o sínú àwọn ìlú rẹ.+ 29 Ọmọ Léfì tí wọn ò fún ní ìpín tàbí ogún kankan pẹ̀lú rẹ, àjèjì, ọmọ aláìníbaba* àti opó tí wọ́n wà nínú àwọn ìlú rẹ máa wá, wọ́n á sì jẹun yó,+ kí Jèhófà Ọlọ́run rẹ lè máa bù kún ọ nínú gbogbo ohun tí ò ń ṣe.+