10 Òwe Sólómọ́nì.+
Ọlọ́gbọ́n ọmọ ń mú inú bàbá rẹ̀ dùn,+
Àmọ́ òmùgọ̀ ọmọ ń kó ẹ̀dùn ọkàn bá ìyá rẹ̀.
2 Àwọn ìṣúra téèyàn fi ìwà ìkà kó jọ kò ní ṣe é láǹfààní,
Àmọ́ òdodo ló ń gbani lọ́wọ́ ikú.+
3 Jèhófà ò ní jẹ́ kí ebi pa olódodo,+
Bẹ́ẹ̀ sì ni kò ní jẹ́ kí ọwọ́ àwọn ẹni burúkú tẹ ohun tí wọ́n ń fẹ́.
4 Ọwọ́ tó dilẹ̀ ń sọni di òtòṣì,+
Àmọ́ ọwọ́ tó ń ṣiṣẹ́ kára ń sọni di ọlọ́rọ̀.+
5 Ọmọ tó ní ìjìnlẹ̀ òye ń kó irè oko jọ ní ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn,
Àmọ́ ọmọ tó ń dójú tini ń sùn fọnfọn nígbà ìkórè.+
6 Ìbùkún wà lórí olódodo,+
Àmọ́ ẹnu ẹni burúkú ń bo ìwà ipá mọ́lẹ̀.
7 Ìrántí olódodo yẹ fún ìbùkún,+
Àmọ́ orúkọ àwọn ẹni burúkú yóò jẹrà.+
8 Ọlọ́gbọ́n ọkàn yóò gba ẹ̀kọ́,+
Àmọ́ ẹni tó ń sọ̀rọ̀ òmùgọ̀ ni a ó tẹ̀ mọ́lẹ̀.+
9 Ẹni tó ń rìn nínú ìwà títọ́ yóò máa rìn nínú ààbò,+
Àmọ́ àṣírí ẹni tó ń sọ ọ̀nà ara rẹ̀ di wíwọ́ yóò tú.+
10 Ẹni tó ń dínjú ń fa ẹ̀dùn ọkàn,+
Ẹni tó sì ń sọ̀rọ̀ òmùgọ̀ ni a ó tẹ̀ mọ́lẹ̀.+
11 Ẹnu olódodo jẹ́ orísun ìyè,+
Àmọ́ ẹnu ẹni burúkú ń bo ìwà ipá mọ́lẹ̀.+
12 Ìkórìíra ló ń dá awuyewuye sílẹ̀,
Àmọ́ ìfẹ́ máa ń bo gbogbo àṣìṣe mọ́lẹ̀.+
13 Ọgbọ́n wà ní ètè olóye,+
Àmọ́ ọ̀pá wà fún ẹ̀yìn ẹni tí kò ní làákàyè.+
14 Àwọn ọlọ́gbọ́n máa ń fi ìmọ̀ ṣe ìṣúra,+
Àmọ́ ẹnu àwọn òmùgọ̀ máa ń fa ìparun.+
15 Ohun ìní ọlọ́rọ̀ ni ìlú olódi rẹ̀.
Ipò òṣì àwọn aláìní ni ìparun wọn.+
16 Iṣẹ́ olódodo ń yọrí sí ìyè;
Àmọ́ iṣẹ́ ọwọ́ ẹni burúkú ń yọrí sí ẹ̀ṣẹ̀.+
17 Ẹni tó ń gba ìbáwí jẹ́ ipa ọ̀nà ìyè fún àwọn èèyàn,
Àmọ́ ẹni tó ń kọ ìbáwí ń kó àwọn èèyàn ṣìnà.
18 Ẹni tó ń bo ìkórìíra rẹ̀ mọ́ra ń parọ́,+
Ẹni tó sì ń tan ọ̀rọ̀ ìbàjẹ́ ká jẹ́ òmùgọ̀.
19 Tí ọ̀rọ̀ bá ti pọ̀, àṣìṣe ò ní ṣàì wáyé,+
Àmọ́ ẹni tó bá ń ṣọ́ ẹnu rẹ̀ á máa fi ọgbọ́n hùwà.+
20 Ahọ́n olódodo dà bíi fàdákà tó dára jù lọ,+
Àmọ́ ọkàn ẹni burúkú kò fi bẹ́ẹ̀ já mọ́ nǹkan kan.
21 Ẹnu olódodo ń bọ́ ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn,+
Àmọ́ àwọn òmùgọ̀ ń kú nítorí wọn kò ní làákàyè.+
22 Ìbùkún Jèhófà ló ń sọni di ọlọ́rọ̀,+
Kì í sì í fi ìrora kún un.
23 Híhùwà àìnítìjú dà bí eré lójú òmùgọ̀,
Àmọ́ ọgbọ́n wà fún ẹni tó ní òye.+
24 Ohun tí ẹni burúkú ń bẹ̀rù yóò ṣẹlẹ̀ sí i;
Àmọ́ a ó ṣe ohun tí ọkàn àwọn olódodo fẹ́ fún wọn.+
25 Nígbà tí ẹ̀fúùfù bá fẹ́ kọjá, ẹni burúkú kò ní sí mọ́,+
Àmọ́ olódodo jẹ́ ìpìlẹ̀ títí láé.+
26 Bí ọtí kíkan ṣe ń ṣe eyín àti bí èéfín ṣe ń ṣe ojú,
Bẹ́ẹ̀ ni ọ̀lẹ ṣe rí sí ẹni tó rán an níṣẹ́.
27 Ìbẹ̀rù Jèhófà ń mú kí ẹ̀mí ẹni gùn,+
Àmọ́ ọdún àwọn ẹni burúkú ni a ó gé kúrú.+
28 Ìfojúsọ́nà àwọn olódodo ń mú ayọ̀ wá,+
Àmọ́ ìrètí àwọn ẹni burúkú yóò ṣègbé.+
29 Ọ̀nà Jèhófà jẹ́ ibi ààbò fún aláìlẹ́bi,+
Àmọ́ ìparun ló jẹ́ fún àwọn aṣebi.+
30 Kò sí ohun tó máa mú kí àwọn olódodo ṣubú,+
Àmọ́ àwọn ẹni burúkú ò ní gbé ilẹ̀ ayé mọ́.+
31 Ẹnu olódodo ń mú ọgbọ́n jáde,
Àmọ́, ahọ́n àyídáyidà ni a ó gé kúrò.
32 Ètè olódodo mọ ohun tó tọ́ láti sọ,
Àmọ́ ẹnu ẹni burúkú jẹ́ ẹ̀tàn.