Rúùtù
3 Náómì ìyá ọkọ rẹ̀ wá sọ fún un pé: “Ọmọ mi, ǹjẹ́ kò yẹ kí n wá ọkọ míì* fún ọ báyìí,+ kí nǹkan lè lọ dáadáa fún ọ? 2 Ṣé o rántí pé mọ̀lẹ́bí wa+ ni Bóásì tí o máa ń lọ sọ́dọ̀ àwọn òṣìṣẹ́ rẹ̀ obìnrin? Ó máa lọ fẹ́ ọkà bálì ní ibi ìpakà* ní alẹ́ òní. 3 Torí náà, wẹ̀, fi òróró olóòórùn dídùn para, wọ aṣọ,* kí o wá lọ sí ibi ìpakà náà. Má ṣe jẹ́ kó mọ̀ pé o wà níbẹ̀ títí tó fi máa jẹun tó sì máa mu. 4 Tó bá ti lọ sùn, kíyè sí ibi tó bá dùbúlẹ̀ sí, kí o lọ ká aṣọ kúrò ní ẹsẹ̀ rẹ̀, kí o sì dùbúlẹ̀ síbẹ̀. Ó máa sọ ohun tó yẹ kí o ṣe fún ọ.”
5 Rúùtù fèsì pé: “Gbogbo ohun tí o sọ fún mi ni màá ṣe.” 6 Torí náà, ó lọ sí ibi ìpakà, ó sì ṣe gbogbo ohun tí ìyá ọkọ rẹ̀ sọ fún un. 7 Ní gbogbo ìgbà yẹn, Bóásì ń jẹ, ó ń mu, inú rẹ̀ sì ń dùn. Lẹ́yìn náà, ó lọ dùbúlẹ̀ sí ẹ̀gbẹ́ ibi tí wọ́n kó ọkà jọ sí. Obìnrin náà sì yọ́ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ lọ síbẹ̀, ó ká aṣọ kúrò ní ẹsẹ̀ Bóásì, ó sì dùbúlẹ̀. 8 Ní ọ̀gànjọ́ òru, ọkùnrin náà bẹ̀rẹ̀ sí í gbọ̀n, ó dìde jókòó, ó rọra tẹ̀ síwájú, ó wá rí i pé obìnrin kan dùbúlẹ̀ síbi ẹsẹ̀ òun. 9 Ó bi í pé: “Ta nìyí?” Ó fèsì pé: “Èmi Rúùtù ìránṣẹ́ rẹ ni. Jọ̀ọ́ fi aṣọ rẹ* bo ìránṣẹ́ rẹ, torí ìwọ jẹ́ olùtúnrà.”+ 10 Ó wá sọ pé: “Kí Jèhófà bù kún ọ, ọmọ mi. Ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ tí o fi hàn lọ́tẹ̀ yìí dáa ju ti ìgbà àkọ́kọ́ lọ,+ torí pé o ò lọ wá ọ̀dọ́kùnrin, ì báà jẹ́ olówó tàbí tálákà. 11 Ọmọ mi, má bẹ̀rù. Gbogbo ohun tí o sọ ni màá ṣe fún ọ,+ kò kúkú sí ẹni tí kò mọ̀ ní ìlú yìí* pé obìnrin àtàtà ni ọ́. 12 Òótọ́ ni pé olùtúnrà+ ni mí, àmọ́ olùtúnrà kan wà tó bá ọ tan jù mí lọ.+ 13 Dúró síbí ní alẹ́ yìí, bó bá tún ọ rà ní àárọ̀ ọ̀la, kò burú! Jẹ́ kó tún ọ rà.+ Àmọ́ bí kò bá fẹ́ tún ọ rà, bí Jèhófà ti ń bẹ, màá tún ọ rà. Torí náà, sùn síbí di àárọ̀.”
14 Ó sì sùn síbi ẹsẹ̀ rẹ̀ títí di àárọ̀, lẹ́yìn náà, ó dìde kí ilẹ̀ tó mọ́ kí ẹnikẹ́ni má bàa rí i. Bóásì wá sọ pé: “Má ṣe jẹ́ kí ẹnì kankan mọ̀ pé obìnrin kan wá sí ibi ìpakà.” 15 Ó tún sọ fún un pé: “Mú ìborùn rẹ wá, kí o sì tẹ́ ẹ.” Torí náà, ó tẹ́ ẹ, ọkùnrin náà sì wọn ọkà bálì òṣùwọ̀n mẹ́fà* sínú ìborùn náà, ó sì gbé e rù ú. Lẹ́yìn èyí, ọkùnrin náà lọ sínú ìlú.
16 Rúùtù lọ sọ́dọ̀ ìyá ọkọ rẹ̀, ìyá ọkọ rẹ̀ sì bi í pé: “Báwo nibi tí o lọ,* ọmọ mi?” Ó sì sọ gbogbo ohun tí ọkùnrin náà ṣe fún un. 17 Ó tún sọ pé: “Ó fún mi ní ọkà bálì òṣùwọ̀n mẹ́fà yìí, ó wá sọ fún mi pé, ‘Má pa dà sọ́dọ̀ ìyá ọkọ rẹ lọ́wọ́ òfo.’” 18 Torí náà, Náómì sọ pé: “Jókòó síbí, ọmọ mi, títí wàá fi mọ ibi tí ọ̀rọ̀ náà máa já sí, torí ọkùnrin náà kò ní sinmi títí yóò fi yanjú ọ̀rọ̀ náà lónìí.”