Rúùtù
4 Bóásì wá lọ sí ẹnubodè ìlú,+ ó sì jókòó síbẹ̀. Sì wò ó, olùtúnrà tí Bóásì sọ̀rọ̀ rẹ̀+ ń kọjá lọ. Ni Bóásì bá sọ pé: “Èèyàn mi,* wá jókòó.” Torí náà, ó yà, ó sì jókòó. 2 Bóásì sì pe mẹ́wàá lára àwọn àgbààgbà ìlú náà,+ ó sọ pé: “Ẹ jókòó.” Wọ́n sì jókòó.
3 Bóásì wá sọ fún olùtúnrà+ náà pé: “Ó di dandan pé kí Náómì tó pa dà láti ilẹ̀ Móábù+ ta ilẹ̀ Élímélékì+ arákùnrin wa. 4 Torí náà, mo rò pé ó yẹ kí n sọ fún ọ nípa rẹ̀ pé, ‘Rà á níṣojú àwọn ará ìlú àti àwọn àgbààgbà àwọn èèyàn mi.+ Tí o bá máa tún un rà, tún un rà. Ṣùgbọ́n tí o kò bá ní tún un rà, jọ̀ọ́ sọ fún mi, kí n lè mọ̀, torí ìwọ lo lẹ́tọ̀ọ́ láti tún un rà, èmi ló sì tẹ̀ lé ọ.’” Ó dáhùn pé: “Màá tún un rà.”+ 5 Torí náà, Bóásì sọ pé: “Ní ọjọ́ tí o bá ra ilẹ̀ náà lọ́wọ́ Náómì, o tún gbọ́dọ̀ rà á lọ́wọ́ Rúùtù ará Móábù, aya ọkùnrin tó ti kú náà, kí o lè dá orúkọ ọkùnrin tó ti kú náà pa dà sórí ogún rẹ̀.”+ 6 Olùtúnrà náà fèsì pé: “Mi ò lè tún un rà, torí kí n má bàa run ogún tèmi. Mo yọ̀ǹda fún ọ láti tún un rà, torí mi ò ní lè tún un rà.”
7 Nígbà àtijọ́ ní Ísírẹ́lì, ohun tí wọ́n máa ń ṣe láti mọ ẹni tó ní ẹ̀tọ́ láti ṣe àtúnrà àti pàṣípààrọ̀ kí wọ́n lè fìdí káràkátà èyíkéyìí múlẹ̀ ni pé: Ẹnì kan ní láti bọ́ bàtà rẹ̀,+ kó sì fún ẹnì kejì. Bí wọ́n ṣe máa ń fìdí àdéhùn múlẹ̀* ní Ísírẹ́lì nìyẹn. 8 Torí náà, nígbà tí olùtúnrà náà sọ fún Bóásì pé, “Ìwọ ni kí o rà á,” ó bọ́ bàtà rẹ̀. 9 Bóásì wá sọ fún àwọn àgbààgbà àti gbogbo èèyàn náà pé: “Ẹ̀yin ni ẹlẹ́rìí+ mi lónìí pé mò ń ra gbogbo ohun tó jẹ́ ti Élímélékì àti gbogbo ohun tó jẹ́ ti Kílíónì àti Málónì lọ́wọ́ Náómì. 10 Mo tún ń fi Rúùtù ará Móábù, ìyàwó Málónì, ṣe aya kí n lè dá orúkọ ọkùnrin tó ti kú náà pa dà sórí ogún rẹ̀,+ kí orúkọ ọkùnrin tó ti kú náà má bàa pa rẹ́ ní ìdílé rẹ̀, kó má sì pa rẹ́ ní ẹnubodè ìlú. Ẹ̀yin ni ẹlẹ́rìí mi lónìí.”+
11 Torí náà, gbogbo àwọn tó wà ní ẹnubodè ìlú àti àwọn àgbààgbà sọ pé: “Àwa jẹ́rìí sí i! Kí Jèhófà jẹ́ kí ìyàwó tó máa tó wọ ilé rẹ dà bíi Réṣẹ́lì àti Líà, àwọn méjì tó kọ́ ilé Ísírẹ́lì.+ Kí nǹkan máa lọ dáadáa fún ọ ní Éfúrátà,+ kí o sì ní orúkọ rere* ní Bẹ́tílẹ́hẹ́mù.+ 12 Kí ọmọ tí Jèhófà yóò fún ọ látọ̀dọ̀ obìnrin yìí+ mú kí ilé rẹ dà bí ilé Pérésì,+ tí Támárì bí fún Júdà.”
13 Lẹ́yìn náà, Bóásì fẹ́ Rúùtù, ó sì di ìyàwó rẹ̀. Ó bá a ní àṣepọ̀, Jèhófà jẹ́ kó lóyún, ó sì bí ọmọkùnrin kan. 14 Àwọn obìnrin wá ń sọ fún Náómì pé: “Jèhófà ni ìyìn yẹ, òun ló jẹ́ kí o rí olùtúnrà lónìí. Kí òkìkí ọmọ náà kàn ní Ísírẹ́lì! 15 Ó* ti mú kí o lókun, yóò sì tọ́jú rẹ tí o bá darúgbó, torí ìyàwó ọmọ rẹ ló bí i. Ìyàwó náà nífẹ̀ẹ́ rẹ,+ ó sì sàn fún ọ ju ọmọkùnrin méje lọ.” 16 Náómì gbé ọmọ náà sí àyà rẹ̀, ó sì ń tọ́jú rẹ̀. 17 Ìgbà náà ni àwọn obìnrin tó wà ládùúgbò fún ọmọ náà ní orúkọ. Wọ́n sọ pé, “Náómì ti ní ọmọkùnrin kan.” Wọ́n sì pe orúkọ rẹ̀ ní Óbédì.+ Òun ló wá bí Jésè,+ bàbá Dáfídì.
18 Ìlà ìdílé* Pérésì+ nìyí: Pérésì bí Hésírónì;+ 19 Hésírónì bí Rámù; Rámù bí Ámínádábù;+ 20 Ámínádábù+ bí Náṣónì; Náṣónì bí Sálímọ́nì; 21 Sálímọ́nì bí Bóásì; Bóásì bí Óbédì; 22 Óbédì bí Jésè;+ Jésè sì bí Dáfídì.+