ÌWÉ KẸRIN
(Sáàmù 90-106)
Àdúrà Mósè, èèyàn Ọlọ́run tòótọ́.+
90 Jèhófà, ìwọ ni ibùgbé+ wa láti ìran dé ìran.
2 Kí a tó bí àwọn òkè
Tàbí kí o tó dá ayé àti ilẹ̀ tó ń méso jáde,+
Láti ayérayé dé ayérayé, ìwọ ni Ọlọ́run.+
3 O mú kí ẹni kíkú pa dà sínú erùpẹ̀;
O sọ pé: “Ẹ pa dà, ẹ̀yin ọmọ èèyàn.”+
4 Nítorí bí ẹgbẹ̀rún ọdún bá kọjá, á dà bí àná lójú rẹ,+
Bí ìṣọ́ kan ní òru.
5 O gbá wọn lọ;+ wọ́n dà bí oorun lásán;
Ní àárọ̀, wọ́n dà bíi koríko tó yọ.+
6 Ní àárọ̀, ó yọ ìtànná, ó sì dọ̀tun,
Àmọ́ ní ìrọ̀lẹ́, ó rọ, ó sì gbẹ dà nù.+
7 Nítorí pé ìbínú rẹ ti pa wá run,+
Ìrunú rẹ sì ti da jìnnìjìnnì bò wá.
8 O gbé àwọn àṣìṣe wa sí iwájú rẹ;+
Ìmọ́lẹ̀ ojú rẹ tú àwọn àṣírí wa.+
9 Àwọn ọjọ́ ayé wa ń dín kù nítorí ìbínú ńlá rẹ;
Àwọn ọdún wa ń lọ sí òpin bí ọ̀rọ̀ wúyẹ́wúyẹ́.
10 Àádọ́rin (70) ọdún ni gígùn ọjọ́ ayé wa,
Tàbí kó jẹ́ ọgọ́rin (80) ọdún+ tí èèyàn bá lókun tó ṣàrà ọ̀tọ̀.
Síbẹ̀, wàhálà àti ìbànújẹ́ ló kún inú wọn;
Wọ́n á kọjá lọ kíákíá, a ó sì fò lọ.+
11 Ta ló lè fòye mọ bí ìbínú rẹ ṣe le tó?
Bí ìbínú ńlá rẹ ṣe pọ̀ ni ẹ̀rù tó yẹ ọ́ ṣe pọ̀.+
12 Kọ́ wa bí a ó ṣe máa ka àwọn ọjọ́ wa+
Ká lè ní ọkàn ọgbọ́n.
13 Pa dà, Jèhófà!+ Ìgbà wo ni èyí máa dópin?+
Ṣàánú àwọn ìránṣẹ́ rẹ.+
14 Fi ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀+ tẹ́ wa lọ́rùn ní àárọ̀,
Ká lè máa kígbe ayọ̀, kí inú wa sì máa dùn+ ní gbogbo ọjọ́ ayé wa.
15 Jẹ́ kí ọjọ́ tí inú wa yóò fi máa dùn pọ̀ bí iye ọjọ́ tí o fi fìyà jẹ wá,+
Kí ó sì pọ̀ bí àwọn ọdún tí àjálù fi bá wa.+
16 Kí àwọn ìránṣẹ́ rẹ rí iṣẹ́ rẹ,
Kí àwọn ọmọ wọn sì rí ọlá ńlá rẹ.+
17 Kí ojú rere Jèhófà Ọlọ́run wa wà lára wa;
Mú kí iṣẹ́ ọwọ́ wa yọrí sí rere.
Bẹ́ẹ̀ ni, mú kí iṣẹ́ ọwọ́ wa yọrí sí rere.+