Sáàmù
Sí olùdarí. Orin. Orin atunilára.
66 Gbogbo ayé, ẹ kígbe ìṣẹ́gun sí Ọlọ́run.+
2 Ẹ fi orin yin* orúkọ rẹ̀ ológo.
Ẹ mú kí ìyìn rẹ̀ ní ògo.+
3 Ẹ sọ fún Ọlọ́run pé: “Àwọn iṣẹ́ rẹ mà bani lẹ́rù o!+
Nítorí agbára ńlá rẹ,
Àwọn ọ̀tá rẹ yóò ba búrúbúrú níwájú rẹ.+
4 Gbogbo ayé yóò forí balẹ̀ fún ọ;+
Wọ́n á kọ orin ìyìn sí ọ,
Wọ́n á sì kọ orin ìyìn sí orúkọ rẹ.”+ (Sélà)
5 Ẹ wá wo àwọn iṣẹ́ Ọlọ́run.
Àwọn ohun tó ṣe fún àwọn ọmọ èèyàn jẹ́ àgbàyanu.+
Ojú rẹ̀ ń wo àwọn orílẹ̀-èdè.+
Kí àwọn alágídí má ṣe gbé ara wọn ga.+ (Sélà)
8 Ẹ yin Ọlọ́run wa,+
Ẹ sì jẹ́ kí a gbọ́ ohùn ìyìn rẹ̀.
10 Ìwọ Ọlọ́run, o ti yẹ̀ wá wò;+
O ti yọ́ wa mọ́ bí ẹni yọ́ fàdákà mọ́.
11 O fi àwọ̀n rẹ mú wa;
O gbé ẹrù tó ń wọni lọ́rùn lé wa lórí.*
14 Èyí tí ètè mi ṣèlérí,+
Tí ẹnu mi sì sọ nígbà tí mo wà nínú ìdààmú.
15 Màá fi àwọn ẹran àbọ́sanra rú ẹbọ sísun sí ọ
Pẹ̀lú èéfín àwọn àgbò tí a fi rúbọ.
Màá fi àwọn akọ màlúù pẹ̀lú àwọn òbúkọ rúbọ. (Sélà)
16 Ẹ wá gbọ́, gbogbo ẹ̀yin tó bẹ̀rù Ọlọ́run,
17 Mo fi ẹnu mi ké pè é,
Mo sì fi ahọ́n mi yìn ín lógo.
18 Ká ní mo ti gbèrò ohun búburú lọ́kàn mi,
Jèhófà kò ní gbọ́ mi.+
20 Ìyìn ni fún Ọlọ́run, ẹni tí kò kọ àdúrà mi,
Tí kò sì fawọ́ ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ sẹ́yìn lórí mi.