Sáàmù
Sí olùdarí. Kí a yí i sí orin “Má Ṣe Pa Á Run.” Ti Ásáfù.+ Orin.
75 A fi ọpẹ́ fún ọ, Ọlọ́run, a fi ọpẹ́ fún ọ;
Orúkọ rẹ wà nítòsí,+
Àwọn èèyàn sì ń kéde àwọn iṣẹ́ àgbàyanu rẹ.
2 O sọ pé: “Tí mo bá dá àkókò kan,
Màá ṣe ìdájọ́ bó ṣe tọ́.
3 Nígbà tí ayé àti gbogbo àwọn tó ń gbé inú rẹ̀ yọ́,
Èmi ni kò jẹ́ kí àwọn òpó rẹ̀ yẹ̀.” (Sélà)
4 Mo sọ fún àwọn tó ń fọ́nnu pé, “Ẹ má ṣe fọ́nnu,”
Mo sì sọ fún àwọn ẹni burúkú pé, “Ẹ má ṣe gbéra ga nítorí agbára* yín.
6 Nítorí pé kì í ṣe
Ìlà oòrùn tàbí ìwọ̀ oòrùn tàbí gúúsù ni ìgbéga ti ń wá.
7 Nítorí Ọlọ́run jẹ́ onídàájọ́.+
Á rẹ ẹnì kan wálẹ̀, á sì gbé ẹlòmíì ga.+
8 Ife kan wà ní ọwọ́ Jèhófà;+
Wáìnì inú rẹ̀ ń ru, wọ́n sì pò ó pọ̀ dáadáa.
Ó dájú pé yóò dà á jáde,
Gbogbo àwọn ẹni burúkú ayé yóò mu ún tòun ti gẹ̀dẹ̀gẹ́dẹ̀ rẹ̀.”+
9 Àmọ́ ní tèmi, màá kéde rẹ̀ títí láé;
Màá fi orin yin* Ọlọ́run Jékọ́bù.