Àwọn Ọba Kìíní
21 Lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí, ọ̀ràn kan ṣẹlẹ̀ tó dá lórí ọgbà àjàrà Nábótì ará Jésírẹ́lì. Ọgbà náà wà ní Jésírẹ́lì+ lẹ́gbẹ̀ẹ́ ààfin Áhábù ọba Samáríà. 2 Áhábù sọ fún Nábótì pé: “Fún mi ní ọgbà àjàrà rẹ kí n lè fi ṣe ibi tí màá máa gbin nǹkan sí torí pé ẹ̀gbẹ́ ilé mi ló wà. Màá fún ọ ní ọgbà àjàrà tí ó dára ju ìyẹn lọ láti fi rọ́pò rẹ̀. Tí o bá sì fẹ́, màá fún ọ ní owó rẹ̀.” 3 Àmọ́ Nábótì sọ fún Áhábù pé: “Jèhófà ò ní fẹ́ gbọ́ rárá pé mo fi ogún àwọn baba ńlá mi+ fún ọ.” 4 Torí náà, Áhábù wá sínú ilé rẹ̀, ó dì kunkun, ó sì dorí kodò nítorí èsì tí Nábótì ará Jésírẹ́lì fún un, nígbà tó sọ pé: “Mi ò ní fún ọ ní ogún àwọn baba ńlá mi.” Ó wá dùbúlẹ̀ sórí ibùsùn rẹ̀, ó gbé ojú sẹ́gbẹ̀ẹ́ kan, ó kọ̀, kò jẹun.
5 Jésíbẹ́lì+ ìyàwó rẹ̀ wá sọ́dọ̀ rẹ̀, ó sì béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé: “Kí ló dé tí inú rẹ fi bà jẹ́* débi pé o ò jẹun?” 6 Ó dá a lóhùn pé: “Torí mo sọ fún Nábótì ará Jésírẹ́lì pé, ‘Fún mi ní ọgbà àjàrà rẹ kí n san owó rẹ̀. Tí o bá sì fẹ́, jẹ́ kí n fún ọ ní ọgbà àjàrà míì dípò rẹ̀.’ Àmọ́, ó sọ pé, ‘Mi ò ní fún ọ ní ọgbà àjàrà mi.’” 7 Jésíbẹ́lì ìyàwó rẹ̀ sọ fún un pé: “Ìwọ kọ́ lò ń ṣàkóso lórí Ísírẹ́lì ni? Dìde, jẹun, kí o sì jẹ́ kí inú rẹ dùn. Màá fún ọ ní ọgbà àjàrà Nábótì ará Jésírẹ́lì.”+ 8 Torí náà, ó kọ àwọn lẹ́tà ní orúkọ Áhábù, ó gbé èdìdì ọba+ lé e, ó sì fi àwọn lẹ́tà náà ránṣẹ́ sí àwọn àgbààgbà+ àti àwọn èèyàn pàtàkì tó ń gbé ní ìlú Nábótì. 9 Ó kọ ọ́ sínú àwọn lẹ́tà náà pé: “Ẹ kéde ààwẹ̀, kí ẹ sì ní kí Nábótì jókòó sí iwájú gbogbo àwọn èèyàn náà. 10 Kí ẹ ní kí ọkùnrin méjì tí wọ́n jẹ́ aláìníláárí jókòó síwájú rẹ̀, kí wọ́n sì ta kò ó+ pé, ‘O ti sọ̀rọ̀ òdì sí Ọlọ́run àti sí ọba!’+ Lẹ́yìn náà, kí ẹ mú un jáde, kí ẹ sì sọ ọ́ lókùúta pa.”+
11 Torí náà, àwọn ọkùnrin ìlú rẹ̀, àwọn àgbààgbà àti àwọn èèyàn pàtàkì tó ń gbé ìlú rẹ̀ ṣe ohun tó wà nínú lẹ́tà tí Jésíbẹ́lì fi ránṣẹ́ sí wọn. 12 Wọ́n kéde ààwẹ̀, wọ́n sì ní kí Nábótì jókòó síwájú gbogbo àwọn èèyàn náà. 13 Ni méjì lára àwọn ọkùnrin aláìníláárí bá wọlé, wọ́n jókòó síwájú rẹ̀, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í ta ko Nábótì níwájú àwọn èèyàn náà, wọ́n ní: “Nábótì ti sọ̀rọ̀ òdì sí Ọlọ́run àti sí ọba!”+ Lẹ́yìn náà, wọ́n mú un lọ sí ẹ̀yìn ìlú, wọ́n sì sọ ọ́ lókùúta pa.+ 14 Wọ́n wá ránṣẹ́ sí Jésíbẹ́lì pé: “A ti sọ Nábótì lókùúta pa.”+
15 Gbàrà tí Jésíbẹ́lì gbọ́ pé wọ́n ti sọ Nábótì lókùúta pa, ó sọ fún Áhábù pé: “Dìde, lọ gba ọgbà àjàrà Nábótì ará Jésírẹ́lì,+ tí ó kọ̀ láti tà fún ọ, nítorí Nábótì kò sí láàyè mọ́. Ó ti kú.” 16 Bí Áhábù ṣe gbọ́ pé Nábótì ti kú, ó dìde, ó sì lọ sí ọgbà àjàrà Nábótì ará Jésírẹ́lì láti gbà á.
17 Àmọ́ Jèhófà bá Èlíjà+ ará Tíṣíbè sọ̀rọ̀, ó ní: 18 “Dìde, lọ pàdé Áhábù ọba Ísírẹ́lì tó wà ní Samáríà.+ Ó wà nínú ọgbà àjàrà Nábótì, níbi tí ó ti lọ gbà á. 19 Kí o sọ fún un pé, ‘Ohun tí Jèhófà sọ nìyí: “O ti pa ọkùnrin yìí+ o sì ti sọ nǹkan ìní rẹ̀ di tìrẹ,* àbí?”’+ Kí o wá sọ fún un pé, ‘Ohun tí Jèhófà sọ nìyí: “Ibi tí àwọn ajá ti lá ẹ̀jẹ̀ Nábótì, ni àwọn ajá ti máa lá ẹ̀jẹ̀ rẹ.”’”+
20 Áhábù sọ fún Èlíjà pé: “O ti wá mi kàn, ìwọ ọ̀tá mi!”+ Ó dáhùn pé: “Mo ti wá ọ kàn. ‘Nítorí o ti pinnu* láti máa ṣe ohun tó burú lójú Jèhófà,+ 21 màá mú àjálù bá ọ, màá gbá ọ dà nù bí ẹni gbálẹ̀, màá sì pa gbogbo ọkùnrin* ilé Áhábù run,+ títí kan àwọn aláìní àti àwọn aláìníláárí ní Ísírẹ́lì.+ 22 Màá sì ṣe ilé rẹ bí ilé Jèróbóámù+ ọmọ Nébátì àti bí ilé Bááṣà+ ọmọ Áhíjà, nítorí o ti mú mi bínú, o sì ti mú kí Ísírẹ́lì ṣẹ̀.’ 23 Ní ti Jésíbẹ́lì, Jèhófà sọ pé: ‘Àwọn ajá ló máa jẹ Jésíbẹ́lì lórí ilẹ̀ tó wà ní Jésírẹ́lì.+ 24 Èèyàn Áhábù èyíkéyìí tí ó bá kú sí ìlú ni àwọn ajá yóò jẹ, èyí tí ó bá sì kú sí pápá ni àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run yóò jẹ.+ 25 Ó dájú pé kò sí ẹni tó dà bí Áhábù,+ ẹni tó ti pinnu* láti máa ṣe ohun tó burú lójú Jèhófà, ẹni tí Jésíbẹ́lì+ ìyàwó rẹ̀ ń tì gbọ̀n-ọ́n gbọ̀n-ọ́n. 26 Ó hùwà ìríra tó burú jáì, torí ó tẹ̀ lé àwọn òrìṣà ẹ̀gbin,* bí gbogbo àwọn Ámórì ti ṣe, àwọn tí Jèhófà lé jáde kúrò níwájú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.’”+
27 Bí Áhábù ṣe gbọ́ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, ó fa ẹ̀wù ara rẹ̀ ya, ó sì gbé aṣọ ọ̀fọ̀* wọ̀; ó gbààwẹ̀, ó ń sùn lórí aṣọ ọ̀fọ̀,* ó sì ń rìn kiri nínú ìbànújẹ́. 28 Nígbà náà, Jèhófà bá Èlíjà ará Tíṣíbè sọ̀rọ̀, ó ní: 29 “Ṣé o rí bí Áhábù ṣe rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ nítorí mi?+ Torí pé ó rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ níwájú mi, mi ò ní mú àjálù náà wá nígbà ayé rẹ̀. Ìgbà ayé ọmọ rẹ̀ ni màá mú àjálù náà wá sórí ilé rẹ̀.”+