Jẹ́nẹ́sísì
48 Lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí, wọ́n sọ fún Jósẹ́fù pé: “Wò ó, ara bàbá rẹ ò yá.” Ló bá mú àwọn ọmọ rẹ̀ méjèèjì dání lọ síbẹ̀, ìyẹn Mánásè àti Éfúrémù.+ 2 Wọ́n sì sọ fún Jékọ́bù pé: “Jósẹ́fù ọmọ rẹ ti dé.” Torí náà, Ísírẹ́lì tiraka, ó sì dìde jókòó lórí ibùsùn rẹ̀. 3 Jékọ́bù wá sọ fún Jósẹ́fù pé:
“Ọlọ́run Olódùmarè fara hàn mí ní Lúsì nílẹ̀ Kénáánì, ó sì súre fún mi.+ 4 Ó sọ fún mi pé, ‘Màá mú kí o bímọ, màá sì mú kí o di púpọ̀, màá sọ ọ́ di àwùjọ àwọn èèyàn,+ màá sì fún àtọmọdọ́mọ* rẹ ní ilẹ̀ yìí kó lè di ohun ìní wọn títí láé.’+ 5 Tèmi+ ni àwọn ọmọ rẹ méjèèjì tí o bí ní ilẹ̀ Íjíbítì kí n tó wá sọ́dọ̀ rẹ ní Íjíbítì. Éfúrémù àti Mánásè yóò di tèmi bí Rúbẹ́nì àti Síméónì ṣe jẹ́ tèmi.+ 6 Àmọ́ àwọn ọmọ tí o bá bí lẹ́yìn wọn yóò jẹ́ tìrẹ. Orúkọ àwọn ẹ̀gbọ́n wọn ni wọ́n á máa fi pe ogún wọn.+ 7 Ní tèmi, nígbà tí mò ń bọ̀ láti Pádánì, Réṣẹ́lì kú+ lẹ́gbẹ̀ẹ́ mi nílẹ̀ Kénáánì, nígbà tí ọ̀nà ṣì jìn sí Éfúrátì.+ Mo sì sin ín níbẹ̀ lójú ọ̀nà Éfúrátì, ìyẹn Bẹ́tílẹ́hẹ́mù.”+
8 Lẹ́yìn náà, Ísírẹ́lì rí àwọn ọmọ Jósẹ́fù, ó sì bi í pé: “Àwọn wo nìyí?” 9 Jósẹ́fù dá a lóhùn pé: “Àwọn ọmọ tí Ọlọ́run fún mi níbí+ ni.” Ni Ísírẹ́lì bá sọ pé: “Jọ̀ọ́ mú wọn wá sọ́dọ̀ mi, kí n lè súre fún wọn.”+ 10 Ojú Ísírẹ́lì ti di bàìbàì torí ó ti darúgbó, kò sì ríran dáadáa. Jósẹ́fù mú wọn sún mọ́ ọ̀dọ̀ Ísírẹ́lì. Ísírẹ́lì fi ẹnu kò wọ́n lẹ́nu, ó sì gbá wọn mọ́ra. 11 Ísírẹ́lì sọ fún Jósẹ́fù pé: “Mi ò rò pé mo lè rí ọ mọ́,+ àmọ́ Ọlọ́run ti jẹ́ kí n tún rí ọmọ* rẹ.” 12 Jósẹ́fù wá gbé wọn kúrò ní orúnkún Ísírẹ́lì, ó tẹrí ba, ó sì wólẹ̀.
13 Jósẹ́fù wá mú àwọn méjèèjì, ó mú Éfúrémù+ sí ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ tó jẹ́ apá òsì Ísírẹ́lì, ó sì mú Mánásè+ sí ọwọ́ òsì rẹ̀ tó jẹ́ apá ọ̀tún Ísírẹ́lì, ó mú wọn sún mọ́ ọ̀dọ̀ Ísírẹ́lì. 14 Àmọ́ Ísírẹ́lì gbé ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ lé orí Éfúrémù bó tiẹ̀ jẹ́ pé òun ni àbúrò, ó sì gbé ọwọ́ òsì rẹ̀ lé orí Mánásè. Ó mọ̀ọ́mọ̀ ṣe bẹ́ẹ̀ ni, torí Mánásè ni àkọ́bí.+ 15 Ó wá súre fún Jósẹ́fù, ó sì sọ pé:+
“Ọlọ́run tòótọ́, tí àwọn bàbá mi Ábúráhámù àti Ísákì bá rìn,+
Ọlọ́run tòótọ́ tó ń bójú tó mi ní gbogbo ọjọ́ ayé mi títí dòní,+
16 Áńgẹ́lì tó ń gbà mí lọ́wọ́ gbogbo àjálù,+ jọ̀ọ́ bù kún àwọn ọmọ+ yìí.
Jẹ́ kí wọ́n máa fi orúkọ mi pè wọ́n àti orúkọ àwọn bàbá mi, Ábúráhámù àti Ísákì,
Jẹ́ kí wọ́n pọ̀ rẹpẹtẹ ní ayé.”+
17 Nígbà tí Jósẹ́fù rí i pé bàbá òun ò gbé ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ kúrò lórí Éfúrémù, kò dùn mọ́ ọn nínú, ó sì gbìyànjú láti mú ọwọ́ bàbá rẹ̀ kúrò lórí Éfúrémù, kó sì gbé e sórí Mánásè. 18 Jósẹ́fù sọ fún bàbá rẹ̀ pé: “Bẹ́ẹ̀ kọ́ bàbá mi, àkọ́bí+ nìyí. Gbé ọwọ́ ọ̀tún rẹ lé e lórí.” 19 Àmọ́ bàbá rẹ̀ ò gbà, ó sì sọ pé: “Mo mọ̀, ọmọ mi, mo mọ̀. Òun náà á di èèyàn púpọ̀, yóò sì di ẹni ńlá. Àmọ́, àbúrò rẹ̀ máa jù ú lọ,+ àwọn ọmọ* rẹ̀ yóò sì pọ̀ bí àwọn orílẹ̀-èdè.”+ 20 Ó sì súre fún wọn ní ọjọ́+ yẹn, ó ní:
“Kí Ísírẹ́lì máa fi orúkọ rẹ súre pé,
‘Kí Ọlọ́run mú kí o dà bí Éfúrémù àti Mánásè.’”
Ó wá ń fi Éfúrémù ṣáájú Mánásè.
21 Lẹ́yìn náà, Ísírẹ́lì sọ fún Jósẹ́fù pé: “Wò ó, mi ò ní pẹ́ kú,+ àmọ́ ó dájú pé Ọlọ́run ò ní fi yín sílẹ̀, yóò sì mú yín pa dà sí ilẹ̀ àwọn baba ńlá+ yín. 22 Ní tèmi, ilẹ̀* tí mo fún ọ fi ọ̀kan ju ti àwọn arákùnrin rẹ lọ, èyí tí mo fi idà àti ọrun mi gbà lọ́wọ́ àwọn Ámórì.”