Ìdárò
א [Áléfì]*
1 Ẹ wo bí Jerúsálẹ́mù tí àwọn èèyàn kún inú rẹ̀ tẹ́lẹ̀ ṣe wá dá páropáro!+
Ẹ wo bó ṣe dà bí opó, ìlú tó ti jẹ́ eléèyàn púpọ̀ rí láàárín àwọn orílẹ̀-èdè!+
Ẹ wo bí ẹni tó jẹ́ ọbabìnrin láàárín àwọn ìpínlẹ̀* ṣe wá di ẹrú!+
ב [Bétì]
2 Ó ń sunkún pẹ̀rẹ̀pẹ̀rẹ̀ ní òru,+ omijé sì ń dà ní ojú rẹ̀.
Kò sí ìkankan nínú gbogbo àwọn olólùfẹ́ rẹ̀ tó máa tù ú nínú.+
Gbogbo àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ ti dà á;+ wọ́n ti di ọ̀tá rẹ̀.
ג [Gímélì]
3 Júdà ti lọ sí ìgbèkùn+ nínú ìpọ́njú, ó sì ń ṣe ẹrú nínú ìnira.+
Ó gbọ́dọ̀ máa gbé láàárín àwọn orílẹ̀-èdè;+ kò rí ibi ìsinmi kankan.
Ọwọ́ gbogbo àwọn tó ń ṣe inúnibíni sí i ti tẹ̀ ẹ́ nínú ìdààmú rẹ̀.
ד [Dálétì]
4 Àwọn ọ̀nà tó lọ sí Síónì ń ṣọ̀fọ̀, nítorí kò sí ẹni tó ń bọ̀ wá sí àjọyọ̀.+
Gbogbo ẹnubodè rẹ̀ di ahoro;+ àwọn àlùfáà rẹ̀ ń kẹ́dùn.
Ẹ̀dùn ọkàn ti bá àwọn wúńdíá* rẹ̀, ó sì wà nínú ìbànújẹ́ ńlá.
ה [Híì]
5 Àwọn elénìní rẹ̀ ti wá di ọ̀gá* rẹ̀; àwọn ọ̀tá rẹ̀ kò sì ṣàníyàn.+
Jèhófà ti mú ẹ̀dùn ọkàn bá a nítorí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ tó pọ̀.+
Àwọn ọmọ rẹ̀ ti lọ sí oko ẹrú níwájú àwọn elénìní.+
ו [Wọ́ọ̀]
6 Gbogbo ògo ọmọbìnrin Síónì ti kúrò lára rẹ̀.+
Àwọn olórí rẹ̀ dà bí àwọn akọ àgbọ̀nrín tí kò rí ibi ìjẹko,
Àárẹ̀ ti mú wọn bí wọ́n ṣe ń rìn lọ níwájú ẹni tó ń lépa wọn.
ז [Sáyìn]
7 Ní ọjọ́ ìdààmú Jerúsálẹ́mù àti nígbà tí kò rílé gbé, ó rántí
Gbogbo ohun iyebíye tó ní látijọ́.+
Nígbà tí àwọn èèyàn rẹ̀ ṣubú sọ́wọ́ àwọn ọ̀tá, tí kò sì ní olùrànlọ́wọ́ kankan,+
ח [Hétì]
8 Jerúsálẹ́mù ti dá ẹ̀ṣẹ̀ tó pọ̀.+
Ìdí nìyẹn tó fi di ohun ìríra.
Gbogbo àwọn tó ń bọlá fún un tẹ́lẹ̀ ti wá ń fojú ẹ̀gàn wò ó, nítorí wọ́n ti rí ìhòòhò rẹ̀.+
Òun fúnra rẹ̀ kérora,+ ó sì yíjú pa dà pẹ̀lú ìtìjú.
ט [Tétì]
9 Àìmọ́ rẹ̀ wà lára aṣọ rẹ̀.
Kò ronú nípa ọjọ́ ọ̀la rẹ̀.+
Ìṣubú rẹ̀ yani lẹ́nu; kò sì ní ẹni tó máa tù ú nínú.
Jèhófà, wo ìpọ́njú mi, nítorí ọ̀tá ti gbé ara rẹ̀ ga.+
י [Yódì]
10 Elénìní ti kó gbogbo ìṣúra rẹ̀.+
Nítorí ìṣojú rẹ̀ ni àwọn orílẹ̀-èdè wá sínú ibi mímọ́ rẹ̀,+
Àwọn tí o pàṣẹ pé kí wọ́n má ṣe wá sínú ìjọ rẹ.
כ [Káfì]
11 Gbogbo àwọn èèyàn rẹ̀ ń kẹ́dùn; wọ́n ń wá oúnjẹ.*+
Wọ́n ti fi ohun iyebíye wọn pààrọ̀ oúnjẹ, kí wọ́n lè máa wà láàyè.*
Wò ó Jèhófà, wo bí mo ṣe dà bí obìnrin tí kò ní láárí.*
ל [Lámédì]
12 Ṣé kò já mọ́ nǹkan kan lójú gbogbo ẹ̀yin tó ń kọjá lójú ọ̀nà ni?
Ẹ wò ó, kí ẹ sì rí i!
Ǹjẹ́ ìrora kankan wà tó dà bí ìrora tí a mú kí ó dé bá mi,
Èyí tí Jèhófà mú kí n jìyà rẹ̀ ní ọjọ́ tí ìbínú rẹ̀ ń jó bí iná?+
מ [Mémì]
13 Láti ibi gíga ló ti rán iná sínú egungun mi,+ ó sì jó ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn.
Ó ti ta àwọ̀n fún ẹsẹ̀ mi; ó mú kí n pa dà sẹ́yìn.
Ó ti sọ mí di obìnrin tí a pa tì.
Láti àárọ̀ ṣúlẹ̀ ni mò ń ṣàìsàn.
נ [Núnì]
14 Ó fi ọwọ́ rẹ̀ so àwọn ìṣìnà mi pọ̀ bí àjàgà.
Ó fi wọ́n kọ́ ọrùn mi, mi ò sì lókun mọ́.
Jèhófà ti fi mí lé ọwọ́ àwọn tí mi ò lè dojú kọ.+
ס [Sámékì]
15 Jèhófà ti ti gbogbo àwọn alágbára tó wà láàárín mi sẹ́gbẹ̀ẹ́ kan.+
Ó ti pe àwọn èèyàn jọ sí mi kí wọ́n lè pa àwọn ọ̀dọ́kùnrin mi.+
Jèhófà ti tẹ wúńdíá ọmọbìnrin Júdà bí àjàrà níbi tí wọ́n ti ń fún wáìnì.+
ע [Áyìn]
16 Nítorí nǹkan wọ̀nyí ni mo ṣe ń sunkún;+ omijé sì ń dà lójú mi.
Nítorí ẹni tó lè tù mí nínú tàbí tó lè tù mí* lára ti jìnnà réré sí mi.
Àwọn ọmọ mi kò nírètí, nítorí ọ̀tá ti borí.
פ [Péè]
17 Síónì ti tẹ́ ọwọ́ rẹ̀;+ kò ní ẹni tó máa tù ú nínú.
Gbogbo àwọn tó yí Jékọ́bù ká ni Jèhófà ti pàṣẹ fún pé kí wọ́n máa bá a ṣọ̀tá.+
Jerúsálẹ́mù ti di ohun ìríra sí wọn.+
צ [Sádì]
18 Jèhófà jẹ́ olódodo,+ èmi ni mo ṣàìgbọràn sí àṣẹ* rẹ̀.+
Ẹ fetí sílẹ̀, gbogbo ẹ̀yin èèyàn, kí ẹ sì rí ìrora tí mò ń jẹ.
Àwọn wúńdíá* mi àti àwọn ọ̀dọ́kùnrin mi ti lọ sí oko ẹrú.+
ק [Kófì]
19 Mo pe àwọn olólùfẹ́ mi, àmọ́ wọ́n pa mí tì.+
Àwọn àlùfáà mi àti àwọn àgbààgbà mi ti ṣègbé nínú ìlú,
ר [Réṣì]
20 Wò ó, Jèhófà, mo wà nínú ìdààmú ńlá.
Inú* mi ń dà rú.
Ọkàn mi gbọgbẹ́, nítorí mo ti ya ọlọ̀tẹ̀ paraku.+
Idà ń pani ní ìta;+ ikú ń pani nínú ilé.
ש [Ṣínì]
21 Àwọn èèyàn ti gbọ́ bí mo ṣe ń kẹ́dùn; kò sí ẹnì kankan tó máa tù mí nínú.
Gbogbo àwọn ọ̀tá mi ti gbọ́ nípa àjálù tó dé bá mi.
Inú wọn dùn, nítorí o mú kí ó ṣẹlẹ̀.+
Àmọ́, o máa mú ọjọ́ tí o kéde wá,+ tí wọ́n á dà bí mo ṣe dà.+
ת [Tọ́ọ̀]
22 Kí gbogbo ìwà búburú wọn wá síwájú rẹ, kí o sì fìyà jẹ wọ́n,+
Bí o ṣe fìyà jẹ mí nítorí gbogbo àṣìṣe mi.
Nítorí ẹ̀dùn ọkàn mi pọ̀, ọkàn mi sì ń ṣàárẹ̀.