Ìsíkíẹ́lì
12 Jèhófà tún bá mi sọ̀rọ̀, ó ní: 2 “Ọmọ èèyàn, àárín ọlọ̀tẹ̀ ilé lò ń gbé. Wọ́n ní ojú láti rí, àmọ́ wọn ò ríran, wọ́n ní etí láti gbọ́, àmọ́ wọn ò gbọ́ràn,+ torí ọlọ̀tẹ̀ ilé ni wọ́n.+ 3 Ní tìrẹ, ọmọ èèyàn, di ẹrù tí wàá gbé lọ sí ìgbèkùn. Kí o wá lọ sí ìgbèkùn ní ojúmọmọ níṣojú wọn. Lọ sí ìgbèkùn láti ilé rẹ sí ibòmíì níṣojú wọn. Bóyá wọ́n á kíyè sí i, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọlọ̀tẹ̀ ilé ni wọ́n. 4 Gbé ẹrù tí o fẹ́ kó lọ sí ìgbèkùn jáde ní ojúmọmọ níṣojú wọn, tó bá sì di ìrọ̀lẹ́, kí o kúrò nílé níṣojú wọn bí ẹni tí wọ́n ń mú lọ sí ìgbèkùn.+
5 “Dá ògiri lu níṣojú wọn, kí o sì gbé ẹrù rẹ gba inú ihò náà.+ 6 Gbé ẹrù rẹ lé èjìká níṣojú wọn, kí o sì gbé e jáde nínú òkùnkùn. Bo ojú rẹ kí o má bàa rí ilẹ̀, torí èmi yóò fi ọ́ ṣe àmì fún ilé Ísírẹ́lì.”+
7 Mo ṣe ohun tó pa láṣẹ fún mi. Ní ojúmọmọ, mo gbé ẹrù mi jáde bí ẹrù ẹni tó ń lọ sí ìgbèkùn, mo sì fi ọwọ́ dá ògiri náà lu ní ìrọ̀lẹ́. Nígbà tí ilẹ̀ sì ṣú, ìṣojú wọn gan-an ni mo ṣe gbé ẹrù mi jáde lórí èjìká mi.
8 Nígbà tí ilẹ̀ mọ́, Jèhófà tún bá mi sọ̀rọ̀, ó ní: 9 “Ọmọ èèyàn, ṣebí ilé Ísírẹ́lì tí wọ́n jẹ́ ọlọ̀tẹ̀ ilé bi ọ́ pé, ‘Kí lò ń ṣe?’ 10 Sọ fún wọn pé, ‘Ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí: “Ọ̀rọ̀ yìí kan ìjòyè+ Jerúsálẹ́mù àti gbogbo ilé Ísírẹ́lì tó wà nínú ìlú náà.”’
11 “Sọ pé, ‘Àmì ni mo jẹ́ fún yín.+ Ohun tí mo ṣe ni wọ́n á ṣe sí wọn. Wọn yóò lọ sí ìgbèkùn, wọ́n á kó wọn lẹ́rú.+ 12 Ìjòyè àárín wọn yóò gbé ẹrù rẹ̀ lé èjìká, yóò sì lọ nínú òkùnkùn. Ó máa dá ògiri lu, yóò sì gbé ẹrù rẹ̀ gba inú ihò náà.+ Ó máa bo ojú rẹ̀ kó má bàa rí ilẹ̀.’ 13 Èmi yóò ju àwọ̀n mi sí i láti fi mú un.+ Màá wá mú un lọ sí Bábílónì, sí ilẹ̀ àwọn ará Kálídíà, àmọ́ kò ní rí i; ibẹ̀ ló sì máa kú sí.+ 14 Gbogbo àwọn tó yí i ká, àwọn olùrànlọ́wọ́ rẹ̀ àti àwọn ọmọ ogun rẹ̀ ni màá fọ́n káàkiri;+ èmi yóò sì fa idà yọ kí n lè lé wọn bá.+ 15 Wọ́n á sì wá mọ̀ pé èmi ni Jèhófà nígbà tí mo bá fọ́n wọn káàkiri àwọn orílẹ̀-èdè, tí mo sì tú wọn ká sí àwọn ilẹ̀ náà. 16 Àmọ́ màá gba díẹ̀ lára wọn lọ́wọ́ idà, ìyàn àti àjàkálẹ̀ àrùn, kí wọ́n lè ròyìn gbogbo ohun tó ń ríni lára tí wọ́n ṣe láàárín àwọn orílẹ̀-èdè tí wọn yóò lọ; wọ́n á sì wá mọ̀ pé èmi ni Jèhófà.”
17 Jèhófà tún bá mi sọ̀rọ̀, ó ní: 18 “Ọmọ èèyàn, máa gbọ̀n rìrì bí o ṣe ń jẹ oúnjẹ rẹ, kí ẹ̀rù máa bà ọ́, kí ọkàn rẹ má sì balẹ̀ bí o ṣe ń mu omi rẹ.+ 19 Sọ fún àwọn èèyàn ilẹ̀ náà pé, ‘Ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ fún àwọn tó ń gbé Jerúsálẹ́mù ní ilẹ̀ Ísírẹ́lì nìyí: “Ọkàn wọn ò ní balẹ̀ bí wọ́n ṣe ń jẹ oúnjẹ wọn, ẹ̀rù á sì máa bà wọ́n bí wọ́n ṣe ń mu omi wọn, torí ilẹ̀ wọn á di ahoro pátápátá+ torí ìwà ipá gbogbo àwọn tó ń gbé ibẹ̀.+ 20 Àwọn ìlú tí wọ́n ń gbé yóò di ahoro, ilẹ̀ náà yóò sì ṣófo;+ ẹ ó sì wá mọ̀ pé èmi ni Jèhófà.”’”+
21 Jèhófà tún sọ fún mi pé: 22 “Ọmọ èèyàn, òwe wo ni wọ́n ń pa ní Ísírẹ́lì yìí, pé, ‘Ọjọ́ ń lọ, gbogbo ìran ò ṣẹ’?+ 23 Torí náà, sọ fún wọn pé, ‘Ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí: “Mi ò ní jẹ́ kí wọ́n sọ ọ̀rọ̀ yìí mọ́ ní Ísírẹ́lì, wọn ò sì ní pa á lówe mọ́.”’ Àmọ́ sọ fún wọn pé, ‘Ọjọ́ ń sún mọ́lé,+ gbogbo ìran yóò sì ṣẹ.’ 24 Torí kò ní sí ìran èké tàbí ìwoṣẹ́ ẹ̀tàn mọ́ nínú ilé Ísírẹ́lì.+ 25 ‘“Torí èmi Jèhófà, yóò sọ̀rọ̀. Ohun tí mo bá sọ sì máa ṣẹ láìjáfara.+ Ìwọ ọlọ̀tẹ̀ ilé, ní àwọn ọjọ́ rẹ,+ ni èmi yóò sọ ọ̀rọ̀ náà, màá sì mú un ṣẹ,” ni Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí.’”
26 Jèhófà tún bá mi sọ̀rọ̀, ó ní: 27 “Ọmọ èèyàn, ohun tí àwọn èèyàn* Ísírẹ́lì ń sọ nìyí, ‘Ìran tó ń rí ṣì máa pẹ́ kó tó ṣẹ, ó sì ń sọ tẹ́lẹ̀ nípa ọjọ́ iwájú tó ṣì jìnnà gan-an.’+ 28 Torí náà, sọ fún wọn pé, ‘Ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí: “‘Kò sí èyí tó máa falẹ̀ nínú gbogbo ọ̀rọ̀ mi; gbogbo ohun tí mo bá sọ ló máa ṣẹ,’ ni Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí.”’”