Émọ́sì
4 “Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí, ẹ̀yin abo màlúù Báṣánì,
Tó wà lórí òkè Samáríà,+
Ẹ̀yin obìnrin tó ń lu àwọn aláìní ní jìbìtì,+ tó sì ń ni àwọn tálákà lára,
Tó ń sọ fún àwọn ọkọ* wọn pé, ‘Ẹ gbé ọtí wá ká mu!’
2 Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ ti fi ìjẹ́mímọ́ rẹ̀ búra pé,
‘“Wò ó! Ọjọ́ ń bọ̀ nígbà tó máa fi ìkọ́ alápatà gbé yín sókè
Tí á sì fi ìwọ̀ ẹja gbé àwọn tó ṣẹ́ kù lára yín.
3 Kálukú yín máa gba àlàfo ara ògiri tó wà níwájú rẹ̀ jáde lọ;
A ó sì lé yín sí Hámọ́nì,” ni Jèhófà wí.’
5 Ẹ fi búrẹ́dì tó ní ìwúkàrà rú ẹbọ ìdúpẹ́;+
Ẹ sì kéde àwọn ọrẹ àtinúwá yín!
Nítorí ohun tí ẹ fẹ́ nìyẹn, ẹ̀yin ọmọ Ísírẹ́lì,’ ni Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí.
6 ‘Ní tèmi, mo mú kí eyín yín mọ́ nítorí àìsí oúnjẹ* ní gbogbo àwọn ìlú yín
Mi ò sì jẹ́ kí oúnjẹ wà ní gbogbo ilé yín;+
Síbẹ̀, ẹ kò pa dà sọ́dọ̀ mi,’+ ni Jèhófà wí.
7 ‘Mo tún fawọ́ òjò sẹ́yìn kúrò lọ́dọ̀ yín nígbà tí ìkórè ṣì ku oṣù mẹ́ta;+
Mo mú kí òjò rọ̀ sí ìlú kan àmọ́ mi ò jẹ́ kó rọ̀ sí ìlú míì.
Òjò máa rọ̀ sí ilẹ̀ kan,
Àmọ́ ilẹ̀ tí òjò kò rọ̀ sí máa gbẹ.
8 Àwọn èèyàn ìlú méjì tàbí mẹ́ta ń rọ́ lọ sí ìlú kan ṣoṣo kí wọ́n lè mu omi,+
Àmọ́ kò tẹ́ wọn lọ́rùn;
Síbẹ̀, ẹ kò pa dà sọ́dọ̀ mi,’+ ni Jèhófà wí.
9 ‘Mo fi ooru tó ń jóni àti èbíbu* kọ lù yín.+
Ẹ̀ ń mú kí àwọn ọgbà yín àti oko àjàrà yín di púpọ̀,+
Ṣùgbọ́n eéṣú ló jẹ igi ọ̀pọ̀tọ́ yín àti igi ólífì yín run;
Síbẹ̀, ẹ kò pa dà sọ́dọ̀ mi,’+ ni Jèhófà wí.
10 ‘Mo rán àjàkálẹ̀ àrùn sáàárín yín bíi ti Íjíbítì.+
Mo fi idà pa àwọn ọ̀dọ́kùnrin yín,+ mo sì gba àwọn ẹṣin yín.+
Mo mú kí òórùn àwọn tó kú ní ibùdó yín gba afẹ́fẹ́ kan;+
Síbẹ̀, ẹ kò pa dà sọ́dọ̀ mi,’ ni Jèhófà wí.
11 ‘Mo pa ilẹ̀ yín run
Bí Ọlọ́run ṣe pa Sódómù àti Gòmórà run.+
Ẹ sì dà bí igi tí a fà yọ kúrò nínú iná;
Síbẹ̀, ẹ kò pa dà sọ́dọ̀ mi,’+ ni Jèhófà wí.
12 Torí náà, màá tún fìyà jẹ ọ́, ìwọ Ísírẹ́lì.
Nítorí ohun tí màá ṣe sí ọ yìí,
Múra sílẹ̀ láti pàdé Ọlọ́run rẹ, ìwọ Ísírẹ́lì.