Lẹ́tà Jémíìsì
5 Ẹ gbọ́, ẹ̀yin ọlọ́rọ̀, ẹ sunkún, kí ẹ sì pohùn réré ẹkún torí ìbànújẹ́ tó máa bá yín.+ 2 Ọrọ̀ yín ti jẹrà, òólá* sì ti jẹ àwọn aṣọ yín.+ 3 Wúrà àti fàdákà yín ti dípẹtà, ìpẹtà wọn máa jẹ́ ẹ̀rí lòdì sí yín, ó sì máa jẹ ẹran ara yín. Ohun tí ẹ kó jọ máa dà bí iná ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn.+ 4 Wò ó! Owó iṣẹ́ tí ẹ ò san fún àwọn òṣìṣẹ́ tó kórè oko yín ń ké jáde ṣáá, igbe tí àwọn olùkórè ń ké fún ìrànwọ́ sì ti dé etí Jèhófà* Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun.+ 5 Ẹ ti gbé ìgbé ayé gbẹdẹmukẹ, ẹ sì ti tẹ́ ara yín lọ́rùn ní ayé. Ẹ ti bọ́ ọkàn yín yó ní ọjọ́ pípa.+ 6 Ẹ ti dáni lẹ́bi; ẹ ti pa olódodo. Ṣebí ó ń ta kò yín?
7 Nítorí náà, ẹ̀yin ará, ẹ ní sùúrù, títí di ìgbà tí Olúwa máa wà níhìn-ín.+ Ẹ wò ó! Àgbẹ̀ máa ń dúró kí ilẹ̀ mú èso tó ṣeyebíye jáde, ó máa ń ní sùúrù títí òjò àkọ́rọ̀ àti òjò àrọ̀kẹ́yìn á fi rọ̀.+ 8 Kí ẹ̀yin náà ní sùúrù;+ ẹ mọ́kàn le, torí ìgbà tí Olúwa máa wà níhìn-ín ti sún mọ́lé.+
9 Ẹ̀yin ará, ẹ má ṣàríwísí* ara yín, kí a má bàa dá yín lẹ́jọ́.+ Ẹ wò ó! Onídàájọ́ ti wà lẹ́nu ilẹ̀kùn. 10 Ẹ̀yin ará, ẹ jẹ́ kí àwọn wòlíì tó sọ̀rọ̀ ní orúkọ Jèhófà*+ jẹ́ àpẹẹrẹ fún yín nínú jíjìyà ibi+ àti níní sùúrù.+ 11 Ẹ wò ó! A ka àwọn tó ní ìfaradà sí aláyọ̀.*+ Ẹ ti gbọ́ nípa ìfaradà Jóòbù,+ ẹ sì ti rí ibi tí Jèhófà* jẹ́ kó yọrí sí,+ pé Jèhófà* ní ìfẹ́ oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ tó pọ̀ gan-an,* ó sì jẹ́ aláàánú.+
12 Ju gbogbo rẹ̀ lọ ẹ̀yin ará mi, ẹ má ṣe búra mọ́, ì báà jẹ́ ọ̀run tàbí ayé lẹ fi búra tàbí ìbúra èyíkéyìí míì. Àmọ́ kí “Bẹ́ẹ̀ ni” yín jẹ́ bẹ́ẹ̀ ni, kí “Bẹ́ẹ̀ kọ́” yín sì jẹ́ bẹ́ẹ̀ kọ́,+ kí a má bàa dá yín lẹ́jọ́.
13 Ṣé ẹnikẹ́ni wà láàárín yín tí nǹkan nira fún? Kó má ṣe dákẹ́ àdúrà.+ Ṣé ẹnikẹ́ni wà láàárín yín tí inú rẹ̀ ń dùn? Kó máa kọ sáàmù.+ 14 Ṣé ẹnikẹ́ni ń ṣàìsàn láàárín yín? Kó pe àwọn alàgbà+ ìjọ, kí wọ́n gbàdúrà lé e lórí, kí wọ́n fi òróró pa á+ ní orúkọ Jèhófà.* 15 Àdúrà ìgbàgbọ́ sì máa mú aláìsàn náà* lára dá, Jèhófà* máa gbé e dìde. Tó bá sì ti dẹ́ṣẹ̀, a máa dárí jì í.
16 Nítorí náà, ẹ máa jẹ́wọ́ àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yín+ fún ara yín láìfi ohunkóhun pa mọ́, kí ẹ sì máa gbàdúrà fún ara yín, ká lè mú yín lára dá. Ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ olódodo lágbára gan-an.*+ 17 Ẹni tó máa ń mọ nǹkan lára bíi tiwa ni Èlíjà, síbẹ̀, nígbà tó gbàdúrà taratara pé kí òjò má rọ̀, òjò ò rọ̀ sórí ilẹ̀ náà fún ọdún mẹ́ta àti oṣù mẹ́fà.+ 18 Ó tún gbàdúrà, òjò sì rọ̀ láti ọ̀run, ilẹ̀ wá mú èso jáde.+
19 Ẹ̀yin ará mi, tí a bá mú ẹnikẹ́ni láàárín yín ṣìnà kúrò nínú òtítọ́, tí ẹlòmíì sì yí i pa dà, 20 kí ẹ mọ̀ pé ẹni tó bá yí ẹlẹ́ṣẹ̀ pa dà kúrò nínú ìṣìnà+ rẹ̀ máa gbà á* lọ́wọ́ ikú, ó sì máa bo ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀ṣẹ̀ mọ́lẹ̀.+