Àwọn Ọba Kìíní
3 Sólómọ́nì bá Fáráò ọba Íjíbítì dána. Ó fẹ́* ọmọbìnrin Fáráò,+ ó sì mú un wá sí Ìlú Dáfídì+ títí ó fi kọ́ ilé rẹ̀ parí+ àti ilé Jèhófà+ pẹ̀lú ògiri tó yí Jerúsálẹ́mù ká.+ 2 Àmọ́ àwọn èèyàn náà ṣì ń rúbọ ní àwọn ibi gíga,+ nítorí títí di àkókò yẹn, wọn ò tíì kọ́ ilé fún orúkọ Jèhófà.+ 3 Ìfẹ́ Jèhófà wà lọ́kàn Sólómọ́nì bó ṣe ń rìn nínú òfin Dáfídì bàbá rẹ̀, kìkì pé ó ń rúbọ ní àwọn ibi gíga, ó sì ń mú àwọn ọrẹ rú èéfín níbẹ̀.+
4 Ọba lọ sí Gíbíónì láti rúbọ níbẹ̀, nítorí ibẹ̀ ni ibi gíga+ tí àwọn èèyàn mọ̀* jù lọ. Ẹgbẹ̀rún kan (1,000) ẹbọ sísun ni Sólómọ́nì rú lórí pẹpẹ náà.+ 5 Ní Gíbíónì, Jèhófà fara han Sólómọ́nì lójú àlá ní òru, Ọlọ́run sì sọ pé: “Béèrè ohun tí wàá fẹ́ kí n fún ọ.”+ 6 Ni Sólómọ́nì bá sọ pé: “O ti fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ hàn sí ìránṣẹ́ rẹ, Dáfídì bàbá mi, lọ́nà tó ga, bó ṣe rìn níwájú rẹ ní òtítọ́ àti ní òdodo pẹ̀lú ọkàn tó dúró ṣinṣin. Títí di òní yìí, ò ń fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ kan náà hàn sí i lọ́nà tó ga tí o fi fún un ní ọmọkùnrin kan láti jókòó sórí ìtẹ́ rẹ̀.+ 7 Ní báyìí, Jèhófà Ọlọ́run mi, o ti fi ìránṣẹ́ rẹ jọba ní ipò Dáfídì bàbá mi, bó tiẹ̀ jẹ́ pé ọ̀dọ́* ni mí, tí mi ò sì ní ìrírí.*+ 8 Ìránṣẹ́ rẹ wà lára àwọn èèyàn rẹ tí o yàn,+ àwọn èèyàn tó pọ̀ gan-an débi pé wọn ò níye, wọn ò sì ṣeé kà. 9 Torí náà, fún ìránṣẹ́ rẹ ní ọkàn tó ń gbọ́ràn láti máa fi ṣe ìdájọ́ àwọn èèyàn rẹ,+ láti fi mọ ìyàtọ̀ láàárín rere àti búburú,+ torí ta ló lè ṣe ìdájọ́ àwọn èèyàn rẹ tó pọ̀ gan-an* yìí?”
10 Ohun tí Sólómọ́nì béèrè yìí dára lójú Jèhófà.+ 11 Ọlọ́run wá sọ fún un pé: “Nítorí o kò béèrè ẹ̀mí gígùn* fún ara rẹ tàbí ọrọ̀ tàbí ikú* àwọn ọ̀tá rẹ, àmọ́ o béèrè òye láti máa gbọ́ àwọn ẹjọ́,+ 12 màá ṣe ohun tí o béèrè.+ Màá fún ọ ní ọkàn ọgbọ́n àti òye,+ tó fi jẹ́ pé bí kò ṣe sí ẹni tó dà bí rẹ ṣáájú, bẹ́ẹ̀ ni kò ní sí ẹni tó máa dà bí rẹ mọ́.+ 13 Yàtọ̀ síyẹn, màá fún ọ ní ohun tí o kò béèrè,+ àti ọrọ̀ àti ògo,+ tó fi jẹ́ pé kò ní sí ọba míì tó máa dà bí rẹ ní gbogbo ọjọ́ ayé* rẹ.+ 14 Tí o bá sì rìn ní àwọn ọ̀nà mi, tí ò ń pa àwọn ìlànà àti àṣẹ mi mọ́, bí Dáfídì bàbá rẹ ṣe rìn,+ màá tún fún ọ ní ẹ̀mí gígùn.”*+
15 Nígbà tí Sólómọ́nì jí, ó rí i pé àlá ni. Lẹ́yìn náà, ó lọ sí Jerúsálẹ́mù, ó dúró níwájú àpótí májẹ̀mú Jèhófà, ó rú àwọn ẹbọ sísun àti àwọn ẹbọ ìrẹ́pọ̀,+ ó sì se àsè fún gbogbo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀.
16 Ní àkókò yẹn, àwọn aṣẹ́wó méjì wá sọ́dọ̀ ọba, wọ́n sì dúró níwájú rẹ̀. 17 Obìnrin àkọ́kọ́ sọ pé: “Jọ̀ọ́, olúwa mi, inú ilé kan náà ni èmi àti obìnrin yìí ń gbé, ó sì wà nílé nígbà tí mo bímọ. 18 Ọjọ́ kẹta lẹ́yìn tí mo bímọ, obìnrin yìí náà bímọ. Àwa méjèèjì nìkan la wà nílé; kò sí ẹlòmíì tó wà pẹ̀lú wa. 19 Ọmọ obìnrin yìí kú ní òru, torí pé ó sùn lé e. 20 Torí náà, ó dìde láàárín òru, ó sì gbé ọmọ mi lẹ́gbẹ̀ẹ́ mi nígbà tí ẹrúbìnrin rẹ ń sùn lọ́wọ́, ó tẹ́ ẹ sí àyà rẹ̀, ó sì tẹ́ ọmọ rẹ̀ tó ti kú sí àyà mi. 21 Nígbà tí mo dìde láàárọ̀ láti tọ́jú ọmọ mi, mo rí i pé ó ti kú. Torí náà, mo yẹ̀ ẹ́ wò fínnífínní ní àárọ̀ yẹn, mo sì rí i pé kì í ṣe ọmọ tí mo bí.” 22 Ṣùgbọ́n obìnrin kejì sọ pé: “Rárá, ọmọ tèmi ló wà láàyè, ọmọ tìrẹ ló kú!” Síbẹ̀ obìnrin àkọ́kọ́ ń sọ pé: “Rárá o, ọmọ tèmi ló wà láàyè, ọmọ tìrẹ ló kú.” Bí wọ́n ṣe ń bá ara wọn jiyàn nìyẹn níwájú ọba.
23 Níkẹyìn, ọba sọ pé: “Ẹni tibí ń sọ pé, ‘Ọmọ tó wà láàyè ni ọmọ mi, èyí tó ti kú ni ọmọ tìrẹ!’ ẹni tọ̀hún sì ń sọ pé, ‘Rárá, ọmọ tìrẹ ló kú, ọmọ tèmi ló wà láàyè!’” 24 Ọba wá sọ pé: “Ẹ bá mi mú idà kan wá.” Torí náà, wọ́n mú idà kan wá fún ọba. 25 Ni ọba bá sọ pé: “Ẹ la ààyè ọmọ náà sí méjì, kí ẹ fún obìnrin àkọ́kọ́ ní ìdajì, kí ẹ sì fún èkejì ní ìdajì.” 26 Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, obìnrin tó ni ààyè ọmọ náà bẹ ọba torí pé ara ọmọ ta á. Ó sọ pé: “Jọ̀wọ́, olúwa mi! Ẹ fún un ní ààyè ọmọ náà! Ẹ má pa á!” Àmọ́ obìnrin kejì ń sọ pé: “Kò ní jẹ́ tèmi, bẹ́ẹ̀ ni kò ní jẹ́ tìrẹ! Ẹ là á sí méjì!” 27 Ni ọba bá dáhùn pé: “Ẹ fún obìnrin àkọ́kọ́ ní ààyè ọmọ náà! Ẹ má pa á, torí òun ni ìyá rẹ̀.”
28 Nítorí náà, gbogbo Ísírẹ́lì gbọ́ ìdájọ́ tí ọba ṣe, ohun tí ọba ṣe yìí sì jọ wọ́n lójú gidigidi,*+ torí wọ́n rí i pé ó ń fi ọgbọ́n Ọlọ́run ṣe ìdájọ́ lọ́nà òdodo.+