Ìwé Kìíní sí Àwọn Ará Tẹsalóníkà
2 Ẹ̀yin ará, ẹ̀yin fúnra yín mọ̀ dájú pé ìbẹ̀wò tí a ṣe sọ́dọ̀ yín kò já sí asán.+ 2 Nítorí bó tilẹ̀ jẹ́ pé a ti kọ́kọ́ jìyà, tí wọ́n sì hùwà àfojúdi sí wa ní ìlú Fílípì,+ bí ẹ̀yin náà ṣe mọ̀, Ọlọ́run wa mú kí a mọ́kàn le* kí a lè sọ ìhìn rere Ọlọ́run+ fún yín lójú ọ̀pọ̀ àtakò.* 3 Nítorí ọ̀rọ̀ ìyànjú wa kò wá látinú ìṣìnà tàbí látinú ìwà àìmọ́ tàbí pẹ̀lú ẹ̀tàn, 4 àmọ́ gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run ṣe tẹ́wọ́ gbà wá pé kí ìhìn rere wà ní ìkáwọ́ wa, bẹ́ẹ̀ ni à ń sọ̀rọ̀, kì í ṣe torí ká lè wu èèyàn, àmọ́ torí ká lè wu Ọlọ́run, ẹni tó ń yẹ ọkàn wa wò.+
5 Kódà, ẹ mọ̀ pé kò sí ìgbà kankan tí a sọ ọ̀rọ̀ ìpọ́nni tàbí tí a ṣe ojú ayé nítorí ohun tí a fẹ́ rí gbà;*+ Ọlọ́run ni ẹlẹ́rìí! 6 Bẹ́ẹ̀ ni a kò máa wá ògo lọ́dọ̀ èèyàn, ì báà jẹ́ lọ́dọ̀ yín tàbí lọ́dọ̀ àwọn ẹlòmíì, bó tiẹ̀ jẹ́ pé gẹ́gẹ́ bí àpọ́sítélì Kristi, àwa fúnra wa lè sọ ara wa di ẹrù tó wúwo sí yín lọ́rùn.+ 7 Kàkà bẹ́ẹ̀, a di ẹni jẹ́jẹ́ láàárín yín, bí ìgbà tí abiyamọ ń tọ́jú* àwọn ọmọ rẹ̀. 8 Torí náà, bí a ṣe ní ìfẹ́ oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ sí yín, a ti pinnu* pé kì í ṣe ìhìn rere Ọlọ́run nìkan la máa fún yín, a tún máa fún yín ní ara* wa,+ torí ẹ ti di ẹni ọ̀wọ́n sí wa.+
9 Ẹ̀yin ará, ó dájú pé ẹ rántí òpò* àti làálàá wa. A ṣiṣẹ́ tọ̀sántòru ká má bàa di ẹrù wọ ìkankan nínú yín lọ́rùn,+ nígbà tí a wàásù ìhìn rere Ọlọ́run fún yín. 10 Ẹ̀yin ni ẹlẹ́rìí, Ọlọ́run náà sì jẹ́ ẹlẹ́rìí, bí a ṣe jẹ́ adúróṣinṣin àti olódodo àti aláìlẹ́bi sí ẹ̀yin onígbàgbọ́. 11 Ẹ mọ̀ dáadáa pé ṣe là ń gbà yín níyànjú, tí à ń tù yín nínú, tí a sì ń jẹ́rìí fún ẹnì kọ̀ọ̀kan yín,+ bí bàbá+ ṣe máa ń ṣe fún àwọn ọmọ rẹ̀, 12 kí ẹ lè máa rìn lọ́nà tó yẹ Ọlọ́run,+ ẹni tó ń pè yín sí Ìjọba+ àti ògo rẹ̀.+
13 Ní tòótọ́, ìdí nìyẹn tí àwa náà fi ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run nígbà gbogbo,+ torí nígbà tí ẹ gba ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, èyí tí ẹ gbọ́ lọ́dọ̀ wa, ẹ tẹ́wọ́ gbà á, kì í ṣe bí ọ̀rọ̀ èèyàn, àmọ́ gẹ́gẹ́ bó ṣe jẹ́ lóòótọ́, bí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, èyí tó tún wà lẹ́nu iṣẹ́ nínú ẹ̀yin onígbàgbọ́. 14 Ẹ̀yin ará ń fara wé àwọn ìjọ Ọlọ́run tó wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú Kristi Jésù ní Jùdíà, nítorí àwọn ará ìlú yín ń fìyà jẹ yín + bí àwọn Júù ṣe ń fìyà jẹ àwọn náà, 15 kódà wọ́n pa Jésù Olúwa+ àti àwọn wòlíì, wọ́n sì ṣe inúnibíni sí wa.+ Bákan náà, wọn ò ṣe ohun tó wu Ọlọ́run, wọn ò sì ní ire àwọn èèyàn lọ́kàn, 16 bí wọ́n ṣe ń gbìyànjú láti dí wa lọ́wọ́ ká má lè bá àwọn èèyàn orílẹ̀-èdè sọ̀rọ̀, kí wọ́n sì rí ìgbàlà.+ Ọ̀nà yìí ni wọ́n gbà ń mú kí ẹ̀ṣẹ̀ wọn pọ̀ sí i. Àmọ́ ìrunú Ọlọ́run ti dé tán sórí wọn.+
17 Ẹ̀yin ará, nígbà tí wọ́n yà wá kúrò lọ́dọ̀ yín* fún àkókò kúkúrú (nínú ara, tí kì í ṣe nínú ọkàn wa), àárò yín tó ń sọ wá gan-an mú ká sa gbogbo ipá wa láti rí yín lójúkojú.* 18 Torí náà, a fẹ́ wá sọ́dọ̀ yín, bẹ́ẹ̀ ni, èmi Pọ́ọ̀lù, gbìyànjú láti wá, kódà kì í ṣe ẹ̀ẹ̀kan, ẹ̀ẹ̀mejì ni; àmọ́ Sátánì dí wa lọ́nà. 19 Nítorí kí ni ìrètí tàbí ìdùnnú tàbí adé ayọ̀ wa níwájú Jésù Olúwa wa nígbà tó bá wà níhìn-ín? Ní tòótọ́, ṣé kì í ṣe ẹ̀yin ni?+ 20 Dájúdájú, ẹ̀yin ni ògo àti ìdùnnú wa.