Ẹ́sítà
2 Lẹ́yìn àwọn nǹkan yìí, nígbà tí ìbínú Ọba Ahasuérúsì+ rọlẹ̀, ó rántí ohun tí Fáṣítì ṣe+ àti ohun tí wọ́n ti pinnu láti ṣe sí i.+ 2 Àwọn ẹmẹ̀wà* ọba wá sọ pé: “Jẹ́ kí a wá àwọn ọ̀dọ́bìnrin, àwọn wúńdíá tó rẹwà fún ọba. 3 Kí ọba yan àwọn kọmíṣọ́nnà ní gbogbo ìpínlẹ̀* tó wà lábẹ́ àkóso rẹ̀+ pé kí wọ́n kó gbogbo àwọn ọ̀dọ́bìnrin tó jẹ́ wúńdíá arẹwà jọ sí Ṣúṣánì* ilé ńlá,* ní ilé àwọn obìnrin.* Kí a fi wọ́n sábẹ́ àbójútó Hégáì+ ìwẹ̀fà ọba, olùtọ́jú àwọn obìnrin, kí wọ́n sì máa gba ìtọ́jú aṣaralóge.* 4 Ọ̀dọ́bìnrin tó bá wu ọba jù lọ ló máa di ayaba dípò Fáṣítì.”+ Àbá náà dára lójú ọba, ohun tó sì ṣe nìyẹn.
5 Ọkùnrin Júù kan wà ní Ṣúṣánì*+ ilé ńlá,* Módékáì+ lorúkọ rẹ̀, ó jẹ́ ọmọ Jáírì, ọmọ Ṣíméì, ọmọ Kíṣì, ọmọ Bẹ́ńjámínì,+ 6 ẹni tí wọ́n mú láti Jerúsálẹ́mù lọ sí ìgbèkùn pẹ̀lú àwọn èèyàn tí wọ́n kó mọ́ Jekonáyà*+ ọba Júdà, tí Nebukadinésárì ọba Bábílónì mú lọ sí ìgbèkùn. 7 Módékáì yìí ni alágbàtọ́* Hádásà,* ìyẹn Ẹ́sítà, tó jẹ́ ọmọ arákùnrin bàbá rẹ̀,+ torí kò ní bàbá àti ìyá. Ọ̀dọ́bìnrin náà lẹ́wà gan-an, ìrísí rẹ̀ sì fani mọ́ra, nígbà tí bàbá àti ìyá rẹ̀ kú, Módékáì mú un ṣe ọmọ. 8 Nígbà tí wọ́n kéde ọ̀rọ̀ ọba àti òfin rẹ̀, tí wọ́n sì kó ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́bìnrin jọ sí Ṣúṣánì* ilé ńlá* lábẹ́ àbójútó Hégáì,+ wọ́n mú Ẹ́sítà náà wá sí ilé* ọba lábẹ́ àbójútó Hégáì, olùtọ́jú àwọn obìnrin.
9 Ọ̀dọ́bìnrin náà dára lójú rẹ̀, ó sì rí ojú rere* rẹ̀, torí náà, ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ló ṣètò bí wọ́n á ṣe máa fún un ní ìtọ́jú aṣaralóge*+ àti oúnjẹ tí á máa jẹ, ó sì fún un ní àṣàyàn ọ̀dọ́bìnrin méje láti ilé ọba. Ó tún fi òun àti àwọn ìránṣẹ́bìnrin rẹ̀ sí ibi tó dára jù lọ ní ilé àwọn obìnrin.* 10 Ẹ́sítà ò sọ nǹkan kan nípa àwọn èèyàn rẹ̀+ tàbí nípa àwọn ìbátan rẹ̀, torí Módékáì+ ti sọ fún un pé kó má sọ fún ẹnikẹ́ni.+ 11 Ojoojúmọ́ ni Módékáì máa ń gba iwájú àgbàlá ilé àwọn obìnrin* kọjá, kó lè wo àlàáfíà Ẹ́sítà àti ohun tó ń ṣẹlẹ̀ sí i.
12 Ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ọ̀dọ́bìnrin náà ló ní ìgbà tí wọ́n máa wọlé sọ́dọ̀ Ọba Ahasuérúsì lẹ́yìn tí wọ́n bá ti parí ìtọ́jú olóṣù méjìlá tí wọ́n ní kí wọ́n fún àwọn obìnrin, nítorí ohun tí ìtọ́jú aṣaralóge* náà gbà nìyẹn, wọ́n á fi oṣù mẹ́fà lo òróró òjíá,+ wọ́n á sì fi oṣù mẹ́fà lo òróró básámù+ pẹ̀lú oríṣiríṣi òróró ìpara tí wọ́n fi ń ṣe ìtọ́jú aṣaralóge.* 13 Lẹ́yìn ìyẹn, ọ̀dọ́bìnrin náà ti ṣe tán láti wọlé sọ́dọ̀ ọba, ohunkóhun tó bá béèrè ni wọ́n máa fún un nígbà tó bá fẹ́ kúrò ní ilé àwọn obìnrin* lọ sí ilé ọba. 14 Ní ìrọ̀lẹ́, á wọlé, á sì pa dà ní àárọ̀ sí ilé kejì tó jẹ́ ti àwọn obìnrin* lábẹ́ àbójútó Ṣááṣígásì ìwẹ̀fà ọba,+ olùtọ́jú àwọn wáhàrì.* Kò tún ní wá sọ́dọ̀ ọba mọ́, àfi tí ọba bá dìídì fẹ́ràn rẹ̀, tó sì dárúkọ rẹ̀ pé kí wọ́n lọ pè é wá.+
15 Nígbà tó kan Ẹ́sítà ọmọ Ábíháílì arákùnrin òbí Módékáì, ẹni tó mú un ṣe ọmọ,+ láti wọlé lọ bá ọba, kò béèrè ohunkóhun lẹ́yìn ohun tí Hégáì ìwẹ̀fà ọba, olùtọ́jú àwọn obìnrin, fún un. (Ní gbogbo àkókò yìí, Ẹ́sítà ń rí ojú rere gbogbo àwọn tó rí i). 16 Wọ́n mú Ẹ́sítà lọ sọ́dọ̀ Ọba Ahasuérúsì ní ilé ọba ní oṣù kẹwàá, ìyẹn oṣù Tébétì,* ní ọdún keje+ ìjọba rẹ̀. 17 Ọba wá nífẹ̀ẹ́ Ẹ́sítà ju gbogbo àwọn obìnrin yòókù lọ, ó sì rí ojú rere àti ìtẹ́wọ́gbà* rẹ̀ ju gbogbo àwọn wúńdíá yòókù. Torí náà, ó fi ìwérí* ayaba sí i lórí, ó sì fi í ṣe ayaba+ dípò Fáṣítì.+ 18 Ọba se àsè ńlá fún gbogbo àwọn ìjòyè àti àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, àkànṣe àsè nítorí Ẹ́sítà. Lẹ́yìn náà, ó kéde ìtúsílẹ̀ ní àwọn ìpínlẹ̀,* ó sì ń fún àwọn èèyàn lẹ́bùn bí ọrọ̀ rẹ̀ ṣe pọ̀ tó.
19 Nígbà tí wọ́n kó àwọn wúńdíá*+ jọ nígbà kejì, Módékáì ń jókòó ní ẹnubodè ọba. 20 Ẹ́sítà kò sọ nǹkan kan nípa àwọn ìbátan rẹ̀ àti àwọn èèyàn rẹ̀,+ bí Módékáì ṣe pa á láṣẹ fún un; Ẹ́sítà ń ṣe ohun tí Módékáì sọ, bí ìgbà tó ṣì wà lábẹ́ àbójútó rẹ̀.+
21 Lákòókò yẹn, nígbà tí Módékáì ń jókòó ní ẹnubodè ọba,* inú bí méjì lára àwọn òṣìṣẹ́ ààfin ọba tó jẹ́ aṣọ́nà, Bígítánì àti Téréṣì, wọ́n sì gbìmọ̀ pọ̀ láti pa* Ọba Ahasuérúsì. 22 Àmọ́ Módékáì gbọ́ ohun tó ń lọ, ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ló sì sọ fún Ẹ́sítà Ayaba. Ẹ́sítà wá sọ fún ọba ní orúkọ Módékáì.* 23 Torí náà, wọ́n wádìí ọ̀rọ̀ náà, wọ́n sì rí i nígbà tó yá pé òótọ́ ni, wọ́n wá gbé àwọn méjèèjì kọ́ sórí òpó igi; wọ́n kọ gbogbo rẹ̀ sílẹ̀ níṣojú ọba, sínú ìwé ìtàn àkókò náà.+