Àkọsílẹ̀ Máàkù
3 Ó tún wọ inú sínágọ́gù kan, ọkùnrin kan tí ọwọ́ rẹ̀ rọ sì wà níbẹ̀.+ 2 Wọ́n wá ń ṣọ́ ọ lójú méjèèjì, wọ́n ń wò ó bóyá ó máa wo ọkùnrin náà sàn ní Sábáàtì, kí wọ́n lè fẹ̀sùn kàn án. 3 Ó sọ fún ọkùnrin tí ọwọ́ rẹ̀ rọ náà pé: “Dìde, máa bọ̀ ní àárín.” 4 Lẹ́yìn náà, ó bi wọ́n pé: “Ṣé ó bófin mu ní Sábáàtì láti ṣe rere tàbí láti ṣe ibi, láti gba ẹ̀mí* là tàbí láti pa á?”+ Àmọ́ wọn ò sọ̀rọ̀. 5 Lẹ́yìn tó wò wọ́n yí ká tìbínútìbínú, tí ẹ̀dùn ọkàn bá a gidigidi torí pé ọkàn wọn ti yigbì,+ ó sọ fún ọkùnrin náà pé: “Na ọwọ́ rẹ.” Ó na ọwọ́ rẹ̀, ọwọ́ rẹ̀ sì pa dà sí bó ṣe wà tẹ́lẹ̀. 6 Ni àwọn Farisí bá jáde lọ, ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í bá àwọn ọmọ ẹgbẹ́ Hẹ́rọ́dù+ gbìmọ̀ pọ̀, kí wọ́n lè pa á.
7 Àmọ́ Jésù kúrò níbẹ̀ lọ sí òkun, pẹ̀lú àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀, ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn láti Gálílì àti Jùdíà sì tẹ̀ lé e.+ 8 Kódà, nígbà tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn gbọ́ nípa ọ̀pọ̀ nǹkan tó ń ṣe, wọ́n wá bá a láti Jerúsálẹ́mù, Ídúmíà, òdìkejì Jọ́dánì àti agbègbè Tírè àti Sídónì. 9 Ó sì sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé kí wọ́n bá òun ṣètò ọkọ̀ ojú omi kékeré kan, kí àwọn èrò náà má bàa há òun mọ́. 10 Torí pé ó wo ọ̀pọ̀ èèyàn sàn, gbogbo àwọn tí àìsàn wọn le gan-an ń ṣùrù bò ó kí wọ́n lè fọwọ́ kàn án.+ 11 Nígbàkigbà tí àwọn ẹ̀mí àìmọ́+ pàápàá bá rí i, wọ́n á wólẹ̀ níwájú rẹ̀, wọ́n á sì ké jáde pé: “Ìwọ ni Ọmọ Ọlọ́run.”+ 12 Àmọ́ lọ́pọ̀ ìgbà, ó kìlọ̀ fún wọn gidigidi pé kí wọ́n má ṣe jẹ́ kí àwọn èèyàn mọ òun.+
13 Ó gun òkè kan, ó pe àwọn tó fẹ́ yàn,+ wọ́n sì wá bá a.+ 14 Ó wá kó àwọn méjìlá (12) jọ,* ó tún pè wọ́n ní àpọ́sítélì, àwọn yìí ló máa wà pẹ̀lú rẹ̀, tó sì máa rán lọ wàásù, 15 wọ́n máa ní àṣẹ láti lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde.+
16 Àwọn méjìlá (12)+ tó kó jọ* ni Símónì, tó tún pè ní Pétérù,+ 17 Jémíìsì ọmọ Sébédè àti Jòhánù arákùnrin Jémíìsì (ó tún ń pe àwọn yìí ní Bóánágè, tó túmọ̀ sí “Àwọn Ọmọ Ààrá”),+ 18 Áńdérù, Fílípì, Bátólómíù, Mátíù, Tọ́másì, Jémíìsì ọmọ Áfíọ́sì, Tádéọ́sì, Símónì tó jẹ́ Kánánéánì* 19 àti Júdásì Ìsìkáríọ́tù, ẹni tó dà á lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn.
Lẹ́yìn náà, ó wọ inú ilé kan, 20 àwọn èrò bá tún kóra jọ, débi pé wọn ò ráyè jẹun pàápàá. 21 Àmọ́ nígbà tí àwọn mọ̀lẹ́bí rẹ̀ gbọ́ nípa rẹ̀, wọ́n jáde lọ, kí wọ́n lè mú un, torí wọ́n ń sọ pé: “Orí rẹ̀ ti yí.”+ 22 Bákan náà, àwọn akọ̀wé òfin, tí wọ́n wá láti Jerúsálẹ́mù ń sọ pé: “Ó ní Béélísébúbù,* agbára alákòóso àwọn ẹ̀mí èṣù ló sì fi ń lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde.”+ 23 Torí náà, lẹ́yìn tó pè wọ́n sọ́dọ̀, ó fi àwọn àpèjúwe bá wọn sọ̀rọ̀ pé: “Báwo ni Sátánì ṣe lè lé Sátánì jáde? 24 Tí ìjọba kan bá pínyà sí ara rẹ̀, ìjọba yẹn ò ní lè dúró;+ 25 tí ilé kan bá sì pínyà sí ara rẹ̀, ilé yẹn ò ní lè dúró. 26 Bákan náà, tí Sátánì bá dìde, tó ta ko ara rẹ̀, tó sì pínyà, kò ní lè dúró, ṣe ló máa pa run. 27 Àní, kò sí ẹni tó lè wọ ilé ọkùnrin alágbára, tó máa lè jí àwọn ohun ìní rẹ̀, àfi tó bá kọ́kọ́ de ọkùnrin alágbára náà mọ́lẹ̀. Ìgbà yẹn ló máa tó lè kó o lẹ́rù nínú ilé rẹ̀. 28 Lóòótọ́ ni mo sọ fún yín pé, ohun gbogbo la máa dárí rẹ̀ ji àwọn ọmọ èèyàn, ẹ̀ṣẹ̀ èyíkéyìí tí wọ́n bá dá àti ọ̀rọ̀ òdì èyíkéyìí tí wọ́n bá sọ. 29 Àmọ́, ẹnikẹ́ni tó bá sọ̀rọ̀ òdì sí ẹ̀mí mímọ́, kò lè ní ìdáríjì kankan títí láé,+ àmọ́ ó máa jẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ àìnípẹ̀kun.”+ 30 Torí wọ́n ń sọ pé: “Ó ní ẹ̀mí àìmọ́,” ló ṣe sọ èyí.+
31 Ìyá rẹ̀ àti àwọn arákùnrin rẹ̀+ wá, wọ́n dúró síta, wọ́n sì ní kí ẹnì kan lọ pè é wá.+ 32 Torí àwọn èrò jókòó yí i ká, wọ́n sọ fún un pé: “Wò ó! Ìyá rẹ àti àwọn arákùnrin rẹ wà níta, wọ́n ń béèrè rẹ.”+ 33 Àmọ́ ó dá wọn lóhùn pé: “Ta ni ìyá mi àti àwọn arákùnrin mi?” 34 Ó wá wo àwọn tó jókòó yí i ká, ó sì sọ pé: “Ẹ wò ó, ìyá mi àti àwọn arákùnrin mi!+ 35 Ẹnikẹ́ni tó bá ń ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run, ẹni yẹn ni arákùnrin mi, arábìnrin mi àti ìyá mi.”+