Jóòbù
3 Lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí, Jóòbù bẹ̀rẹ̀ sí í sọ̀rọ̀, ó sì ń fi ọjọ́ tí wọ́n bí i gégùn-ún.*+ 2 Jóòbù sọ pé:
3 “Kí ọjọ́ tí wọ́n bí mi + ṣègbé,
Àti òru tí ẹnì kan sọ pé: ‘Wọ́n ti lóyún ọkùnrin kan!’
4 Kí ọjọ́ yẹn ṣókùnkùn.
Kí Ọlọ́run lókè má ka ọjọ́ yẹn sí;
Kí ìmọ́lẹ̀ má tàn sórí rẹ̀ rárá.
5 Kí òkùnkùn biribiri* gbà á pa dà.
Kí òjò ṣú bò ó.
Kí ohunkóhun tó ń mú ojúmọ́ ṣókùnkùn dẹ́rù bà á.
6 Kí ìṣúdùdù gba òru yẹn;+
Kó má ṣe yọ̀ láàárín àwọn ọjọ́ tó wà nínú ọdún,
Kí wọ́n má sì kà á mọ́ àwọn oṣù.
7 Àní, kí òru yẹn yàgàn!
Ká má ṣe gbọ́ igbe ayọ̀ kankan ní òru yẹn.
9 Kí àwọn ìràwọ̀ rẹ̀ ṣókùnkùn ní ìdájí;
Kó dúró de ìmọ́lẹ̀, àmọ́ kí ìrètí rẹ̀ já sí asán,
Kó má sì rí ìtànṣán ìmọ́lẹ̀ òwúrọ̀.
10 Torí kò ti àwọn ilẹ̀kùn ilé ọlẹ̀ ìyá mi;+
Kò sì pa ojú mi mọ́ kúrò nínú wàhálà.
11 Kí ló dé tí mi ò kú nígbà tí wọ́n bí mi?
Kí ló dé tí mi ò ṣègbé nígbà tí mo jáde látinú ikùn?+
12 Kí ló dé tí orúnkún tó gbà mí fi wà,
Tí ọmú tí màá mu sì wà?
13 Torí mi ò bá máa dùbúlẹ̀ báyìí láìsí ìyọlẹ́nu;+
Mi ò bá máa sùn, kí n sì máa sinmi+
14 Pẹ̀lú àwọn ọba ayé àti àwọn agbani-nímọ̀ràn wọn,
Tí wọ́n kọ́ àwọn ibi tó ti di àwókù báyìí fún ara wọn,*
15 Tàbí pẹ̀lú àwọn ìjòyè tó ní wúrà,
Àwọn tí fàdákà kún ilé wọn.
16 Àbí kí ló dé tí oyún mi ò ti bà jẹ́ kí wọ́n tó mọ̀,
Bí àwọn ọmọ tí kò rí ìmọ́lẹ̀ rárá?
17 Ibẹ̀ ni àwọn ẹni burúkú pàápàá ti bọ́ lọ́wọ́ ìdààmú;
Ibẹ̀ ni àwọn tí kò lókun ti ń sinmi.+
18 Ibẹ̀ ni ara ti tu àwọn ẹlẹ́wọ̀n pa pọ̀;
Wọn ò gbọ́ ohùn ẹni tó ń fipá kó wọn ṣiṣẹ́.
19 Ẹni kékeré àti ẹni ńlá ò jura wọn lọ níbẹ̀,+
Ẹrú sì dòmìnira lọ́wọ́ ọ̀gá rẹ̀.
21 Kí ló dé tí wọ́n ń retí ikú, àmọ́ tí kò dé?+
Wọ́n ń wá a ju bí wọ́n ṣe ń wá ìṣúra tó fara pa mọ́ sínú ilẹ̀,
22 Àwọn tí inú wọn ń dùn gidigidi,
Tí wọ́n ń yọ̀ nígbà tí wọ́n rí sàréè.
23 Kí ló dé tó fún ẹni tó ṣìnà ní ìmọ́lẹ̀,
Ẹni tí Ọlọ́run ti sé mọ́?+
25 Torí ohun tí mo bẹ̀rù ti dé bá mi,
Ohun tó sì ń já mi láyà ti ṣẹlẹ̀ sí mi.
26 Mi ò ní àlàáfíà, ọkàn mi ò balẹ̀, mi ò sì sinmi,
Síbẹ̀, wàhálà ò yéé dé bá mi.”