Àìsáyà
24 Wò ó! Jèhófà máa sọ ilẹ̀ náà* di òfìfo, ó sì máa sọ ọ́ di ahoro.+
Ó ń dojú rẹ̀ dé,*+ ó sì ń tú àwọn tó ń gbé inú rẹ̀ ká.+
2 Bákan náà ló máa rí fún gbogbo èèyàn:
Àwọn èèyàn àti àlùfáà,
Ìránṣẹ́kùnrin àti ọ̀gá rẹ̀ ọkùnrin,
Ìránṣẹ́bìnrin àti ọ̀gá rẹ̀ obìnrin,
Ẹni tó ń rà àti ẹni tó ń tà,
Ẹni tó ń yáni ní nǹkan àti ẹni tó ń yá nǹkan,
Ẹni tó ń yáni lówó àti ẹni tó ń yáwó.+
4 Ilẹ̀ náà ń ṣọ̀fọ̀;*+ ó ń joro.
Ilẹ̀ tó ń méso jáde ò lọ́ràá mọ́; ó ti ń ṣá.
Àwọn gbajúmọ̀ ilẹ̀ náà ti rẹ̀ dà nù.
Ìdí nìyẹn tí àwọn tó ń gbé ilẹ̀ náà fi dín kù,
Àwọn tó sì ṣẹ́ kù níbẹ̀ ò pọ̀ rárá.+
8 Ayọ̀ ìlù tanboríìnì ti dáwọ́ dúró;
Ariwo àwọn tó ń ṣe àríyá ti dópin;
Ìró ayọ̀ háàpù ti dáwọ́ dúró.+
9 Wọ́n ń mu wáìnì láìsí orin,
Ọtí sì ń korò lẹ́nu àwọn tó ń mu ún.
11 Wọ́n ń kígbe ní àwọn ojú ọ̀nà torí wáìnì.
Gbogbo ìdùnnú ti pòórá;
Ayọ̀ ilẹ̀ náà ti lọ.+
13 Bó ṣe máa rí ní ilẹ̀ náà nìyí, láàárín àwọn èèyàn náà:
14 Wọ́n máa gbóhùn sókè,
Wọ́n máa kígbe ayọ̀.
Wọ́n máa kéde títóbi Jèhófà láti òkun.*+
15 Ìdí nìyẹn tí wọ́n fi máa yin Jèhófà lógo ní agbègbè ìmọ́lẹ̀;*+
Ní àwọn erékùṣù òkun, wọ́n máa yin orúkọ Jèhófà, Ọlọ́run Ísírẹ́lì lógo.+
16 À ń gbọ́ àwọn orin láti ìkángun ayé pé:
Àmọ́ mo sọ pé: “Mò ń kú lọ, mò ń kú lọ!
Ó mà ṣe fún mi o! Àwọn ọ̀dàlẹ̀ ti dalẹ̀;
Ìwà ọ̀dàlẹ̀ wọn ni àwọn ọ̀dàlẹ̀ fi dalẹ̀.”+
17 Ìbẹ̀rù, kòtò àti pańpẹ́ ń dúró dè ọ́, ìwọ tó ń gbé ilẹ̀ náà.+
18 Ẹnikẹ́ni tó bá ń sá fún ìró ìbẹ̀rù á já sínú kòtò,
Pańpẹ́ sì máa mú ẹnikẹ́ni tó bá ń jáde látinú kòtò.+
Torí àwọn ibú omi ọ̀run máa ṣí,
Àwọn ìpìlẹ̀ ilẹ̀ sì máa mì tìtì.
20 Ilẹ̀ náà ń ta gọ̀ọ́gọ̀ọ́ bí ẹni tó mutí yó,
Ó sì ń fì síwá sẹ́yìn bí ahéré nínú afẹ́fẹ́.
Ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ wà lórí rẹ̀, ó sì wúwo gan-an,+
Ó máa ṣubú, débi pé kò ní dìde mọ́.
21 Ní ọjọ́ yẹn, Jèhófà máa yíjú sí àwọn ọmọ ogun ibi gíga lókè
Àti sí àwọn ọba ayé lórí ilẹ̀.
22 A máa kó wọn jọ
Bí àwọn ẹlẹ́wọ̀n tí wọ́n kó jọ sínú kòtò,
A máa tì wọ́n pa mọ́ inú àjà ilẹ̀;
Lẹ́yìn ọ̀pọ̀ ọjọ́, a máa rántí wọn.