Diutarónómì
23 “Ọkùnrin èyíkéyìí tí wọ́n bá tẹ̀ lọ́dàá, tí wọ́n fọ́ kórópọ̀n rẹ̀ tàbí tí wọ́n gé ẹ̀yà ìbímọ rẹ̀ kúrò kò gbọ́dọ̀ wá sínú ìjọ Jèhófà.+
2 “Ọmọ àlè kankan ò gbọ́dọ̀ wá sínú ìjọ Jèhófà.+ Àní títí dé ìran rẹ̀ kẹwàá, àtọmọdọ́mọ rẹ̀ kankan ò gbọ́dọ̀ wá sínú ìjọ Jèhófà.
3 “Ọmọ Ámónì tàbí ọmọ Móábù kankan ò gbọ́dọ̀ wá sínú ìjọ Jèhófà.+ Àní títí dé ìran wọn kẹwàá, àtọmọdọ́mọ wọn kankan ò gbọ́dọ̀ wá sínú ìjọ Jèhófà láé, 4 torí pé wọn ò fún yín ní oúnjẹ àti omi láti fi ràn yín lọ́wọ́ nígbà tí ẹ kúrò ní Íjíbítì,+ wọ́n sì tún gba Báláámù ọmọ Béórì láti Pétórì ti Mesopotámíà pé kó wá gégùn-ún fún* yín.+ 5 Àmọ́ Jèhófà Ọlọ́run rẹ ò gbọ́ ti Báláámù.+ Kàkà bẹ́ẹ̀, Jèhófà Ọlọ́run rẹ yí ègún náà pa dà sí ìbùkún fún ọ,+ torí Jèhófà Ọlọ́run rẹ nífẹ̀ẹ́ rẹ.+ 6 O ò gbọ́dọ̀ wá ire wọn tàbí ìtẹ̀síwájú wọn ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ.+
7 “O ò gbọ́dọ̀ kórìíra ọmọ Édómù, torí arákùnrin rẹ ni.+
“O ò gbọ́dọ̀ kórìíra ọmọ Íjíbítì, torí o di àjèjì ní ilẹ̀ rẹ̀.+ 8 Ìran kẹta àwọn ọmọ tí wọ́n bá bí fún wọn lè wá sínú ìjọ Jèhófà.
9 “Tí o bá pàgọ́ láti gbógun ja àwọn ọ̀tá rẹ, kí o yẹra fún ohunkóhun tí kò dáa.*+ 10 Tí ọkùnrin kan bá di aláìmọ́ torí pé àtọ̀ dà lára rẹ̀ ní òru,+ kó kúrò nínú ibùdó, kó má sì pa dà síbẹ̀. 11 Tó bá di ìrọ̀lẹ́, kó fi omi wẹ̀, tí oòrùn bá sì ti wọ̀, kó pa dà sínú ibùdó.+ 12 Kí ibi ìkọ̀kọ̀* kan wà tí wàá máa lò lẹ́yìn ibùdó, ibẹ̀ sì ni kí o lọ. 13 Kí igi tó ṣeé fi gbẹ́lẹ̀ wà lára àwọn ohun èlò rẹ. Tí o bá lóṣòó ní ìta láti yàgbẹ́, kí o fi igi náà gbẹ́lẹ̀, kí o sì bo ìgbẹ́ rẹ. 14 Torí Jèhófà Ọlọ́run rẹ ń rìn kiri nínú ibùdó rẹ+ láti gbà ọ́, kó sì fi àwọn ọ̀tá rẹ lé ọ lọ́wọ́. Kí ibùdó rẹ máa wà ní mímọ́,+ kó má bàa rí ohunkóhun tí kò bójú mu láàárín rẹ, kó sì pa dà lẹ́yìn rẹ.
15 “O ò gbọ́dọ̀ fi ẹrú lé ọ̀gá rẹ̀ lọ́wọ́ tó bá sá kúrò lọ́dọ̀ ọ̀gá rẹ̀ wá sọ́dọ̀ rẹ. 16 Ó lè máa gbé láàárín rẹ níbikíbi tó bá yàn nínú ọ̀kan lára àwọn ìlú rẹ, níbikíbi tó bá wù ú. Má fìyà jẹ ẹ́.+
17 “Ìkankan nínú àwọn ọmọbìnrin Ísírẹ́lì ò gbọ́dọ̀ di aṣẹ́wó tẹ́ńpìlì,+ bẹ́ẹ̀ ni ìkankan nínú àwọn ọmọkùnrin Ísírẹ́lì ò gbọ́dọ̀ di aṣẹ́wó tẹ́ńpìlì.+ 18 O ò gbọ́dọ̀ mú owó tí wọ́n san fún obìnrin kan nídìí iṣẹ́ aṣẹ́wó tàbí owó tí wọ́n san fún ọkùnrin kan* nídìí iṣẹ́ aṣẹ́wó* wá sínú ilé Jèhófà Ọlọ́run rẹ láti fi san ẹ̀jẹ́, torí méjèèjì jẹ́ ohun ìríra lójú Jèhófà Ọlọ́run rẹ.
19 “O ò gbọ́dọ̀ gba èlé lọ́wọ́ arákùnrin rẹ,+ ì báà jẹ́ èlé lórí owó, lórí oúnjẹ tàbí ohunkóhun tí wọ́n ń gba èlé lé lórí. 20 O lè gba èlé lọ́wọ́ àjèjì,+ àmọ́ o ò gbọ́dọ̀ gba èlé lọ́wọ́ arákùnrin rẹ,+ kí Jèhófà Ọlọ́run rẹ lè máa bù kún ọ nínú gbogbo ohun tí o bá dáwọ́ lé ní ilẹ̀ tí o fẹ́ lọ gbà.+
21 “Tí o bá jẹ́jẹ̀ẹ́ fún Jèhófà Ọlọ́run rẹ,+ má ṣe lọ́ra láti san án.+ Torí ó dájú pé Jèhófà Ọlọ́run rẹ máa béèrè rẹ̀ lọ́wọ́ rẹ; àìjẹ́ bẹ́ẹ̀, ó máa di ẹ̀ṣẹ̀ sí ọ lọ́rùn.+ 22 Àmọ́ tí o ò bá jẹ́jẹ̀ẹ́, kò ní di ẹ̀ṣẹ̀ sí ọ lọ́rùn.+ 23 Máa mú ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ ṣẹ,+ tí o bá sì fi ẹnu ara rẹ jẹ́jẹ̀ẹ́ pé wàá ṣe ọrẹ àtinúwá fún Jèhófà Ọlọ́run rẹ, o gbọ́dọ̀ ṣe é.+
24 “Tí o bá lọ sínú ọgbà àjàrà ọmọnìkejì rẹ, o lè jẹ èso àjàrà débi tó bá tẹ́ ọ* lọ́rùn, àmọ́ o ò gbọ́dọ̀ kó ìkankan sínú àpò rẹ.+
25 “Tí o bá wọ inú oko ọkà ọmọnìkejì rẹ, o lè fọwọ́ ya àwọn ṣírí ọkà tó ti gbó, àmọ́ má yọ dòjé ti ọkà ọmọnìkejì rẹ.+