Ẹ́kísódù
18 Jẹ́tírò àlùfáà Mídíánì, bàbá ìyàwó Mósè+ gbọ́ nípa gbogbo ohun tí Ọlọ́run ti ṣe fún Mósè àti fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó jẹ́ èèyàn rẹ̀, bí Jèhófà ṣe mú Ísírẹ́lì kúrò ní Íjíbítì.+ 2 Jẹ́tírò bàbá ìyàwó Mósè ti mú Sípórà ìyàwó Mósè sọ́dọ̀ nígbà tó ní kó pa dà sọ́dọ̀ Jẹ́tírò, 3 pẹ̀lú àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ méjèèjì.+ Ọ̀kan ń jẹ́ Gẹ́ṣómù,*+ torí Mósè sọ pé, “mo ti di àjèjì nílẹ̀ òkèèrè.” 4 Èkejì ń jẹ́ Élíésérì,* torí ó sọ pé, “Ọlọ́run bàbá mi ni olùrànlọ́wọ́ mi, ẹni tó gbà mí lọ́wọ́ idà Fáráò.”+
5 Jẹ́tírò, bàbá ìyàwó Mósè, pẹ̀lú àwọn ọmọ Mósè àti ìyàwó rẹ̀ wá bá Mósè ní aginjù níbi tó pàgọ́ sí, ní òkè Ọlọ́run tòótọ́.+ 6 Ó ránṣẹ́ sí Mósè pé: “Èmi, Jẹ́tírò bàbá ìyàwó rẹ+ ń bọ̀ wá bá ọ, pẹ̀lú ìyàwó rẹ àti àwọn ọmọ rẹ̀ méjèèjì.” 7 Lójú ẹsẹ̀, Mósè lọ pàdé bàbá ìyàwó rẹ̀, ó wólẹ̀, ó sì fi ẹnu kò ó lẹ́nu. Wọ́n béèrè àlàáfíà ara wọn, wọ́n sì wọ inú àgọ́.
8 Mósè sọ fún bàbá ìyàwó rẹ̀ nípa gbogbo ohun tí Jèhófà ṣe sí Fáráò àti Íjíbítì torí Ísírẹ́lì,+ gbogbo ìyà tó jẹ wọ́n lọ́nà+ àti bí Jèhófà ṣe gbà wọ́n sílẹ̀. 9 Inú Jẹ́tírò dùn torí gbogbo ohun rere tí Jèhófà ṣe fún Ísírẹ́lì, bó ṣe gbà wọ́n sílẹ̀ kúrò ní* Íjíbítì. 10 Jẹ́tírò wá sọ pé: “Ẹ yin Jèhófà, ẹni tó gbà yín sílẹ̀ kúrò ní Íjíbítì àti lọ́wọ́ Fáráò, tó sì gba àwọn èèyàn náà kúrò lọ́wọ́ àwọn ará Íjíbítì. 11 Mo ti wá mọ̀ báyìí pé Jèhófà tóbi ju gbogbo ọlọ́run yòókù lọ+ torí ohun tó ṣe sí àwọn tí kò ka àwọn èèyàn rẹ̀ sí.” 12 Jẹ́tírò bàbá ìyàwó Mósè wá mú ẹbọ sísun àtàwọn ẹbọ míì wá fún Ọlọ́run, Áárónì àti gbogbo àgbààgbà Ísírẹ́lì sì bá bàbá ìyàwó Mósè jẹun níwájú Ọlọ́run tòótọ́.
13 Ní ọjọ́ kejì, Mósè jókòó bí ìṣe rẹ̀ láti dá ẹjọ́ fún àwọn èèyàn náà, àwọn èèyàn náà sì dúró níwájú Mósè láti àárọ̀ ṣúlẹ̀. 14 Nígbà tí bàbá ìyàwó Mósè rí gbogbo ohun tí Mósè ń ṣe fún àwọn èèyàn náà, ó ní: “Kí lò ń ṣe fún àwọn èèyàn yìí? Kí ló dé tí ìwọ nìkan jókòó síbí, tí gbogbo èèyàn dúró síwájú rẹ láti àárọ̀ ṣúlẹ̀?” 15 Mósè sọ fún bàbá ìyàwó rẹ̀ pé: “Torí pé àwọn èèyàn ń wá sọ́dọ̀ mi kí n lè bá wọn wádìí ọ̀rọ̀ lọ́wọ́ Ọlọ́run ni. 16 Tí ẹjọ́ kan bá délẹ̀, wọ́n á gbé e wá sọ́dọ̀ mi, màá sì ṣèdájọ́ ẹnì kìíní àti ẹnì kejì, màá jẹ́ kí wọ́n mọ àwọn ìpinnu Ọlọ́run tòótọ́ àti àwọn òfin rẹ̀.”+
17 Bàbá ìyàwó Mósè sọ fún un pé: “Ohun tí ò ń ṣe yìí kò dáa. 18 Ó máa tán ìwọ àtàwọn èèyàn tó wà pẹ̀lú rẹ lókun, torí ẹrù yìí ti pọ̀ jù fún ọ, o ò lè dá rù ú. 19 Gbọ́ ohun tí mo fẹ́ sọ fún ọ. Jẹ́ kí n gbà ọ́ nímọ̀ràn, Ọlọ́run yóò sì wà pẹ̀lú rẹ.+ Ìwọ máa ṣe aṣojú àwọn èèyàn náà lọ́dọ̀ Ọlọ́run tòótọ́,+ kí o sì máa kó ẹjọ́ náà tọ Ọlọ́run tòótọ́ lọ.+ 20 Kí o kìlọ̀ fún wọn nípa ohun tí àwọn ìlànà àtàwọn òfin sọ,+ kí o sì jẹ́ kí wọ́n mọ ọ̀nà tí wọ́n á máa rìn àti ohun tí wọ́n á máa ṣe. 21 Àmọ́ kí o yan àwọn ọkùnrin tó kúnjú ìwọ̀n nínú àwọn èèyàn náà,+ àwọn tó bẹ̀rù Ọlọ́run, tí wọ́n ṣeé fọkàn tán, tí wọ́n sì kórìíra èrè tí kò tọ́,+ kí o wá fi àwọn yìí ṣe olórí wọn, kí wọ́n jẹ́ olórí ẹgbẹẹgbẹ̀rún, olórí ọgọ́rọ̀ọ̀rún, olórí àràádọ́ta àti olórí mẹ́wàá-mẹ́wàá.+ 22 Kí wọ́n máa dá ẹjọ́ tí àwọn èèyàn náà bá gbé wá.* Kí wọ́n máa gbé gbogbo ẹjọ́ tó bá ṣòroó dá wá sọ́dọ̀ rẹ,+ àmọ́ kí wọ́n máa dá àwọn ẹjọ́ tí kò tó nǹkan. Jẹ́ kí wọ́n bá ọ gbé lára ẹrù yìí kí nǹkan lè rọrùn fún ọ.+ 23 Tí o bá ṣe bẹ́ẹ̀, tí Ọlọ́run sì pa á láṣẹ fún ọ, wàá lè gbé ẹrù yìí, gbogbo èèyàn á sì fi ìtẹ́lọ́rùn pa dà sílé wọn.”
24 Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, Mósè fetí sí ohun tí bàbá ìyàwó rẹ̀ sọ, ó sì ṣe gbogbo ohun tó sọ. 25 Mósè yan àwọn ọkùnrin tó kúnjú ìwọ̀n nínú gbogbo Ísírẹ́lì, ó sì fi wọ́n ṣe olórí àwọn èèyàn náà, ó fi wọ́n ṣe olórí ẹgbẹẹgbẹ̀rún, olórí ọgọ́rọ̀ọ̀rún, olórí àràádọ́ta àti olórí àwọn mẹ́wàá-mẹ́wàá. 26 Wọ́n ń bá àwọn èèyàn náà dá ẹjọ́ tí wọ́n bá gbé wá. Wọ́n máa ń gbé ẹjọ́ tó bá ṣòroó dá lọ sọ́dọ̀ Mósè,+ àmọ́ wọ́n máa ń dá àwọn ẹjọ́ tí kò tó nǹkan. 27 Lẹ́yìn náà, Mósè sin bàbá ìyàwó rẹ̀ sọ́nà,+ ó sì pa dà sí ilẹ̀ rẹ̀.