Àwọn Ọba Kìíní
15 Ní ọdún kejìdínlógún Ọba Jèróbóámù+ ọmọ Nébátì, Ábíjámù di ọba lórí Júdà.+ 2 Ọdún mẹ́ta ló fi ṣàkóso ní Jerúsálẹ́mù. Orúkọ ìyá rẹ̀ ni Máákà,+ ọmọ ọmọ Ábíṣálómù. 3 Gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ tí bàbá rẹ̀ dá ṣáájú rẹ̀ ni òun náà dá, kò sì fi gbogbo ọkàn rẹ̀ sin Jèhófà Ọlọ́run rẹ̀ bíi Dáfídì baba ńlá rẹ̀. 4 Àmọ́, nítorí Dáfídì,+ Jèhófà Ọlọ́run rẹ̀ jẹ́ kí àtọmọdọ́mọ rẹ̀ máa ṣàkóso* ní Jerúsálẹ́mù,+ ó gbé ọmọ rẹ̀ dìde lẹ́yìn rẹ̀, ó sì jẹ́ kí Jerúsálẹ́mù máa wà nìṣó. 5 Dáfídì ṣe ohun tí ó tọ́ ní ojú Jèhófà, ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀, kò kúrò nínú gbogbo ohun tí Ó pa láṣẹ fún un, àfi nínú ọ̀ràn Ùráyà ọmọ Hétì.+ 6 Ogun sì ń wáyé láàárín Rèhóbóámù àti Jèróbóámù ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀.+
7 Ní ti ìyókù ìtàn Ábíjámù àti gbogbo ohun tí ó ṣe, ǹjẹ́ kò wà lákọsílẹ̀ nínú ìwé ìtàn ìgbà àwọn ọba Júdà?+ Bákan náà, ogun wáyé láàárín Ábíjámù àti Jèróbóámù.+ 8 Níkẹyìn, Ábíjámù sinmi pẹ̀lú àwọn baba ńlá rẹ̀, wọ́n sì sin ín sí Ìlú Dáfídì; Ásà+ ọmọ rẹ̀ sì jọba ní ipò rẹ̀.+
9 Ní ogún ọdún Jèróbóámù ọba Ísírẹ́lì, Ásà bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso lórí Júdà. 10 Ọdún mọ́kànlélógójì (41) ni ó fi ṣàkóso ní Jerúsálẹ́mù. Orúkọ ìyá rẹ̀ àgbà ni Máákà+ ọmọ ọmọ Ábíṣálómù. 11 Ásà ṣe ohun tí ó tọ́ ní ojú Jèhófà,+ bíi Dáfídì baba ńlá rẹ̀. 12 Ó lé àwọn aṣẹ́wó ọkùnrin tó wà ní tẹ́ńpìlì kúrò ní ilẹ̀ náà,+ ó sì mú gbogbo òrìṣà ẹ̀gbin* tí àwọn baba ńlá rẹ̀ ṣe kúrò.+ 13 Ó tiẹ̀ tún yọ Máákà+ ìyá rẹ̀ àgbà kúrò ní ipò ìyá ọba,* torí pé ó ṣe òrìṣà ẹ̀gbin tí wọ́n fi ń jọ́sìn òpó òrìṣà.* Ásà gé òrìṣà ẹ̀gbin+ rẹ̀ lulẹ̀, ó sì sun ún ní Àfonífojì Kídírónì.+ 14 Àmọ́ kò mú àwọn ibi gíga kúrò.+ Síbẹ̀, Ásà fi gbogbo ọkàn rẹ̀ sin Jèhófà ní gbogbo ọjọ́ ayé* rẹ̀. 15 Ó kó àwọn ohun tí òun àti bàbá rẹ̀ ti yà sí mímọ́ wá sínú ilé Jèhófà, ìyẹn fàdákà, wúrà àti àwọn ohun èlò míì.+
16 Ìgbà gbogbo ni ogun ń wáyé láàárín Ásà àti Bááṣà+ ọba Ísírẹ́lì. 17 Torí náà, Bááṣà ọba Ísírẹ́lì wá dojú kọ Júdà, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́* Rámà,+ kí ẹnikẹ́ni má bàa jáde tàbí kí ó wọlé sọ́dọ̀* Ásà ọba Júdà.+ 18 Ni Ásà bá kó gbogbo fàdákà àti wúrà tí ó ṣẹ́ kù nínú àwọn ibi ìṣúra ilé Jèhófà àti àwọn ibi ìṣúra ilé* ọba, ó sì kó wọn fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀. Ọba Ásà wá fi wọ́n ránṣẹ́ sí Bẹni-hádádì ọmọ Tábúrímónì ọmọ Hésíónì, ọba Síríà,+ tó ń gbé ní Damásíkù, ó sọ pé: 19 “Àdéhùn* kan wà láàárín èmi àti ìwọ àti láàárín bàbá mi àti bàbá rẹ. Mo fi ẹ̀bùn fàdákà àti wúrà ránṣẹ́ sí ọ. Wò ó, lọ yẹ àdéhùn* tí o bá Bááṣà ọba Ísírẹ́lì ṣe, kó lè pa dà lẹ́yìn mi.” 20 Bẹni-hádádì ṣe ohun tí Ọba Ásà sọ, ó rán àwọn olórí ọmọ ogun rẹ̀ láti gbéjà ko àwọn ìlú Ísírẹ́lì, wọ́n sì ṣá Íjónì,+ Dánì+ àti Ebẹli-bẹti-máákà balẹ̀ pẹ̀lú gbogbo Kínérétì àti gbogbo ilẹ̀ Náfútálì. 21 Nígbà tí Bááṣà gbọ́ ohun tó ṣẹlẹ̀, ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ló jáwọ́ nínú kíkọ́* Rámà, ó sì ń gbé ní Tírísà.+ 22 Ọba Ásà wá pe gbogbo Júdà, láìyọ ẹnì kankan sílẹ̀, wọ́n kó àwọn òkúta àti ẹ̀là gẹdú tó wà ní Rámà, tí Bááṣà fi ń kọ́lé, Ọba Ásà sì fi wọ́n kọ́* Gébà+ ní Bẹ́ńjámínì àti Mísípà.+
23 Ní ti gbogbo ìyókù ìtàn Ásà àti gbogbo agbára rẹ̀ àti gbogbo ohun tí ó ṣe àti àwọn ìlú tí ó kọ́,* ǹjẹ́ kò wà lákọsílẹ̀ nínú ìwé ìtàn ìgbà àwọn ọba Júdà? Àmọ́, nígbà tí ó darúgbó, àìsàn kan mú un ní ẹsẹ̀.+ 24 Níkẹyìn, Ásà sinmi pẹ̀lú àwọn baba ńlá rẹ̀, wọ́n sì sin ín pẹ̀lú wọn ní Ìlú Dáfídì baba ńlá rẹ̀; Jèhóṣáfátì+ ọmọ rẹ̀ sì jọba ní ipò rẹ̀.
25 Nádábù+ ọmọ Jèróbóámù di ọba lórí Ísírẹ́lì ní ọdún kejì Ásà ọba Júdà, ọdún méjì ló sì fi ṣàkóso lórí Ísírẹ́lì. 26 Ohun búburú ló ń ṣe ní ojú Jèhófà, ó sì ń rìn ní ọ̀nà bàbá rẹ̀+ àti nínú ẹ̀ṣẹ̀ tí bàbá rẹ̀ mú kí Ísírẹ́lì dá.+ 27 Bááṣà ọmọ Áhíjà ará ilé Ísákà dìtẹ̀ mọ́ ọn, Bááṣà sì pa á ní Gíbétónì+ tó jẹ́ ti àwọn Filísínì, nígbà tí Nádábù àti gbogbo Ísírẹ́lì dó ti Gíbétónì. 28 Bí Bááṣà ṣe pa á nìyẹn ní ọdún kẹta Ásà ọba Júdà, ó sì jọba ní ipò rẹ̀. 29 Gbàrà tí ó di ọba, ó ṣá gbogbo ilé Jèróbóámù balẹ̀. Kò ṣẹ́ alààyè kankan kù lára àwọn ará ilé Jèróbóámù; ó ní kí wọ́n pa wọ́n rẹ́ bí ọ̀rọ̀ tí Jèhófà gbẹnu ìránṣẹ́ rẹ̀, Áhíjà ọmọ Ṣílò,+ sọ. 30 Èyí jẹ́ nítorí ẹ̀ṣẹ̀ tí Jèróbóámù dá, tí ó sì mú kí Ísírẹ́lì náà dá àti nítorí pé ó mú Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì bínú gan-an. 31 Ní ti ìyókù ìtàn Nádábù àti gbogbo ohun tí ó ṣe, ǹjẹ́ kò wà lákọsílẹ̀ nínú ìwé ìtàn ìgbà àwọn ọba Ísírẹ́lì? 32 Ìgbà gbogbo ni ogun ń wáyé láàárín Ásà àti Bááṣà ọba Ísírẹ́lì.+
33 Ní ọdún kẹta Ásà ọba Júdà, Bááṣà ọmọ Áhíjà di ọba lórí gbogbo Ísírẹ́lì ní Tírísà, ó sì fi ọdún mẹ́rìnlélógún (24) ṣàkóso.+ 34 Àmọ́ ohun búburú ló ń ṣe ní ojú Jèhófà,+ ó sì rìn ní ọ̀nà Jèróbóámù àti nínú ẹ̀ṣẹ̀ tí ó mú kí Ísírẹ́lì dá.+