Sí Àwọn Hébérù
1 Nígbà àtijọ́, Ọlọ́run bá àwọn baba ńlá wa sọ̀rọ̀ nípasẹ̀ àwọn wòlíì lọ́pọ̀ ìgbà àti lọ́pọ̀ ọ̀nà.+ 2 Ní báyìí, ní òpin àwọn ọjọ́ yìí, ó ti bá wa sọ̀rọ̀ nípasẹ̀ Ọmọ+ tó yàn ṣe ajogún ohun gbogbo,+ nípasẹ̀ ẹni tó dá àwọn ètò àwọn nǹkan.*+ 3 Ó ń gbé ògo Ọlọ́run yọ,+ òun ni àwòrán irú ẹni tó jẹ́ gẹ́lẹ́,+ ó sì ń fi ọ̀rọ̀ rẹ̀ tó lágbára gbé ohun gbogbo ró. Lẹ́yìn tó ti wẹ àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa mọ́,+ ó jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún Ọba Ọlọ́lá ní ibi gíga.+ 4 Torí náà, ó ti wá sàn ju àwọn áńgẹ́lì lọ,+ débi pé ó ti jogún orúkọ tó lọ́lá ju tiwọn lọ.+
5 Bí àpẹẹrẹ, èwo nínú àwọn áńgẹ́lì ni Ọlọ́run sọ fún rí pé: “Ìwọ ni ọmọ mi; òní ni mo di bàbá rẹ”?+ Tó sì tún sọ fún pé: “Màá di bàbá rẹ̀, á sì di ọmọ mi”?+ 6 Àmọ́ nígbà tó tún mú Àkọ́bí rẹ̀+ wá sí ilẹ̀ ayé tí à ń gbé, ó sọ pé: “Kí gbogbo áńgẹ́lì Ọlọ́run tẹrí ba* fún un.”
7 Bákan náà, ó sọ nípa àwọn áńgẹ́lì pé: “Ó dá àwọn áńgẹ́lì rẹ̀ ní ẹ̀mí, ó sì dá àwọn òjíṣẹ́ rẹ̀*+ ní ọwọ́ iná.”+ 8 Àmọ́, ó sọ nípa Ọmọ pé: “Ọlọ́run ni ìtẹ́ rẹ+ títí láé àti láéláé, ọ̀pá àṣẹ Ìjọba rẹ sì jẹ́ ọ̀pá àṣẹ ìdúróṣinṣin.* 9 O nífẹ̀ẹ́ òdodo, o sì kórìíra ìwà tí kò bófin mu. Ìdí nìyẹn tí Ọlọ́run, àní Ọlọ́run rẹ, fi fòróró ayọ̀ yàn ọ́+ ju àwọn ojúgbà rẹ.”+ 10 Àti pé: “Ní ìbẹ̀rẹ̀, Olúwa, o fi ìpìlẹ̀ ayé sọlẹ̀, ọ̀run sì jẹ́ iṣẹ́ ọwọ́ rẹ. 11 Wọ́n á ṣègbé, àmọ́ ìwọ á máa wà nìṣó; gbogbo wọn á sì gbó bí aṣọ, 12 o máa ká wọn jọ bí aṣọ àwọ̀lékè, a sì máa pààrọ̀ wọn bí aṣọ. Àmọ́ ìwọ ò yí pa dà, àwọn ọdún rẹ ò sì ní dópin láé.”+
13 Àmọ́ èwo nínú àwọn áńgẹ́lì ló sọ nípa rẹ̀ rí pé: “Jókòó sí ọwọ́ ọ̀tún mi, títí màá fi fi àwọn ọ̀tá rẹ ṣe àpótí ìtìsẹ̀ rẹ”?+ 14 Ṣebí ẹ̀mí tó ń ṣe iṣẹ́ ìsìn mímọ́*+ ni gbogbo wọn, tí a rán jáde láti ṣe ìránṣẹ́ fún àwọn tó máa rí ìgbàlà?