Jóòbù
3 Ṣé ó máa bẹ̀ ọ́ gidigidi,
Àbí ó máa fi ohùn jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́ bá ọ sọ̀rọ̀?
4 Ṣé ó máa bá ọ dá májẹ̀mú,
Kí o lè sọ ọ́ di ẹrú rẹ títí láé?
5 Ṣé o máa bá a ṣeré bí ẹyẹ,
Àbí o máa so okùn mọ́ ọn fún àwọn ọmọbìnrin rẹ kéékèèké?
6 Ṣé àwọn ọlọ́jà máa fi gba pààrọ̀?
Ṣé wọ́n máa pín in láàárín àwọn oníṣòwò?
8 Gbé ọwọ́ rẹ lé e;
O máa rántí ìjà náà, o ò sì ní ṣe bẹ́ẹ̀ mọ́ láé!
9 Asán ni ìrètí èyíkéyìí tí o bá ní pé o máa kápá rẹ̀.
Tí o bá rí i lásán, ṣe ni jìnnìjìnnì á bò ọ́.*
10 Kò sí ẹni tó jẹ́ ru ú sókè.
Ta ló wá lè kò mí lójú?+
11 Ta ló kọ́kọ́ fún mi ní ohunkóhun tí màá fi san án pa dà fún un?+
Tèmi ni ohunkóhun tó wà lábẹ́ ọ̀run.+
12 Mi ò ní ṣàìsọ̀rọ̀ nípa apá àti ẹsẹ̀ rẹ̀,
Nípa agbára ńlá rẹ̀ àti ara rẹ̀ tí a dá lọ́nà ìyanu.
13 Ta ló ti bọ́ ohun tó bò ó lára?
Ta ló máa wọ ẹnu rẹ̀ tó là sílẹ̀?
14 Ta ló lè fipá ṣí àwọn ilẹ̀kùn ẹnu* rẹ̀?
Gbogbo eyín rẹ̀ ń dẹ́rù bani.
15 Àwọn ìpẹ́ tò lọ́wọ̀ọ̀wọ́ ní ẹ̀yìn rẹ̀,*
Wọ́n lẹ̀ mọ́ra pinpin.
16 Ọ̀kọ̀ọ̀kan lẹ̀ típẹ́típẹ́ mọ́ ìkejì,
Débi pé afẹ́fẹ́ kò lè wọ àárín wọn.
17 Wọ́n lẹ̀ mọ́ra wọn;
Wọ́n so mọ́ra wọn, wọn ò sì ṣeé yà sọ́tọ̀ọ̀tọ̀.
18 Ìró tó ń ti imú rẹ̀ jáde ń mú kí iná kọ yẹ̀rì,
Ojú rẹ̀ sì dà bí ìmọ́lẹ̀ àárọ̀ tó ń tàn.
19 Mànàmáná ń kọ yẹ̀rì láti ẹnu rẹ̀;
Iná ń ta pàrà jáde.
20 Èéfín ń tú jáde látinú ihò imú rẹ̀,
Bí iná ìléru tí wọ́n fi koríko etídò dáná sí.
21 Èémí rẹ̀ ń mú kí ẹyin iná jó,
Ọwọ́ iná sì ń ti ẹnu rẹ̀ jáde.
22 Ọrùn rẹ̀ lágbára gan-an,
Jìnnìjìnnì sì ń sá lọ níwájú rẹ̀.
23 Àwọn ìṣẹ́po ẹran ara rẹ̀ lẹ̀ mọ́ra pẹ́kípẹ́kí;
Wọ́n le gbagidi, bí ohun tí a rọ, tó dúró digbí.
24 Ọkàn rẹ̀ le bí òkúta,
Àní, ó le bí ìyá ọlọ.
25 Tó bá gbéra, ẹ̀rù máa ń ba àwọn alágbára pàápàá;
Tó bá jà pìtìpìtì, ṣìbáṣìbo á bá wọn.
26 Kò sí idà tó bà á tó lè ràn án;
Bẹ́ẹ̀ ni ọ̀kọ̀, igaga tàbí orí ọfà kò lè ràn án.+
27 Ó ka irin sí pòròpórò
Àti bàbà sí igi tó ti jẹrà.
28 Ọfà kò lè lé e lọ;
Òkúta kànnàkànnà máa ń di àgékù pòròpórò tó bá bà á.
29 Ó ka kùmọ̀ sí àgékù pòròpórò,
Ó sì ń fi ẹ̀ṣín rẹ́rìn-ín bó ṣe ń dún pẹkẹpẹkẹ.
31 Ó ń mú kí ibú hó bí ìkòkò;
Ó ń ru òkun gùdù bí ìkòkò òróró ìpara.
32 Ipa ọ̀nà rẹ̀ ń dán lẹ́yìn rẹ̀.
Ṣe ni èèyàn á rò pé ibú omi ní irun funfun.
33 Kò sí ohun tó dà bíi rẹ̀ ní ayé,
Ẹ̀dá tí a dá pé kó má bẹ̀rù ohunkóhun.
34 Ó ń fìbínú wo gbogbo ohun tó ń gbéra ga.
Òun ni ọba lórí gbogbo ẹran ńlá inú igbó.”