Jóòbù
30 “Wọ́n ti ń fi mí rẹ́rìn-ín báyìí,+
Àwọn ọkùnrin tí kò tó mi lọ́jọ́ orí,
Àwọn tí mi ò lè gbà kí bàbá wọn
Dúró lẹ́gbẹ̀ẹ́ àwọn ajá tó ń ṣọ́ agbo ẹran mi.
2 Àǹfààní wo ni agbára ọwọ́ wọn ṣe mí?
Okun wọn ti ṣègbé.
3 Àìní àti ebi ti tán wọn lókun;
Wọ́n ń họ ilẹ̀ gbígbẹ jẹ,
Ilẹ̀ tó ti pa run, tó sì ti di ahoro.
4 Wọ́n ń kó ewé iyọ̀ jọ látinú igbó;
Gbòǹgbò igi wíwẹ́ ni oúnjẹ wọn.
5 Wọ́n lé wọn kúrò ní ìlú;+
Àwọn èèyàn kígbe mọ́ wọn bí ẹni ń kígbe mọ́ olè.
6 Wọ́n ń gbé ní gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ àfonífojì tó jin kòtò,
Nínú àwọn ihò inú ilẹ̀ àti inú àpáta.
7 Wọ́n ń ké jáde látinú igbó,
Wọ́n sì kó ara wọn jọ sí àárín èsìsì.
8 A ti lé wọn kúrò* ní ilẹ̀ náà,
Bí àwọn ọmọ òpònú àti àwọn tí kò lórúkọ.
12 Wọ́n dìde ní ọwọ́ ọ̀tún mi bí àwọn jàǹdùkú;
Wọ́n mú kí n sá lọ,
Wọ́n sì fi àwọn ohun ìdènà tó ń fa ìparun sí ojú ọ̀nà mi.
13 Wọ́n ya àwọn ọ̀nà mi lulẹ̀,
Wọ́n sì mú kí àjálù tó dé bá mi le sí i,+
Láìsí ẹnikẹ́ni tó dá wọn dúró.*
14 Wọ́n wá bí ẹni pé ihò tó fẹ̀ lára ògiri ni wọ́n gbà kọjá;
Wọ́n ya wọlé nígbà ìṣòro.
15 Ìbẹ̀rù bò mí;
Wọ́n lé iyì mi lọ bí atẹ́gùn,
Ìgbàlà mi sì pòórá bí ìkùukùu.
18 A fi agbára ńlá sọ ẹ̀wù mi di ìdàkudà;*
Ó ń fún mọ́ mi lọ́rùn bí ọrùn aṣọ mi.
19 Ọlọ́run ti jù mí sínú ẹrọ̀fọ̀;
Ó ti mú kí n dà bí iyẹ̀pẹ̀ àti eérú.
20 Mo ké pè ọ́ pé kí o ràn mí lọ́wọ́, àmọ́ o ò dá mi lóhùn;+
Mo dìde dúró, àmọ́ ńṣe lo kàn ń wò mí.
21 O ṣe mí níkà, o sì kẹ̀yìn sí mi;+
O fi gbogbo agbára ọwọ́ rẹ gbéjà kò mí.
22 O gbé mi sókè, o sì fi atẹ́gùn gbé mi lọ;
O wá ń fi ìjì jù mí kiri.*
23 Torí mo mọ̀ pé wàá mú kí n kú,
Kí n lọ sí ibi tí gbogbo alààyè á ti pàdé.
25 Ṣé mi ò sunkún torí àwọn tí ìṣòro dé bá?*
Ṣebí mo* banú jẹ́ torí aláìní?+
26 Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ire ni mò ń retí, ibi ló ṣẹlẹ̀;
Mo retí ìmọ́lẹ̀, àmọ́ òkùnkùn ló dé.
27 Inú mi tó ń dà rú kò dáwọ́ dúró;
Ọjọ́ ìpọ́njú dé bá mi.
28 Mò ń rìn káàkiri nínú ìbànújẹ́;+ kò sí ìmọ́lẹ̀.
Mo dìde nínú àpéjọ, mo sì kígbe fún ìrànlọ́wọ́.
31 Ọ̀fọ̀ nìkan ni háàpù mi wúlò fún,
Igbe ẹkún sì ni fèrè* mi wà fún.