“Ìmọ̀lára Wọn Ru Sókè Bíi Tọmọdé”
Bẹ́ẹ̀ ni Sergei, ẹni ọdún 32, tí ó jẹ́ bàbá ọlọ́mọ mẹ́ta, ṣe ṣàpèjúwe ọ̀nà tí àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ gbà hùwà pa dà nígbà tí ó fi ìwé náà, Life—How Did It Get Here? By Evolution or by Creation?, hàn wọ́n. Sergei, tí ń gbé ní Tatarstan, Rọ́ṣíà, ṣàpèjúwe ohun tí ó ṣẹlẹ̀ pé:
“A kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ nípa wíwo àwọn àwòrán àti kíka àwọn àkọlé. Ìjíròrò gbígbanilọ́kàn tẹ̀ lé e. Gbogbo àwọn ọ̀rẹ́ mi jẹ́ àwọn bàbá àti ìyá tí kò ì lọ́jọ́ lórí púpọ̀ . . . Gbogbo wa máa ń lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì nígbà ọdún Easter àti fún ìbatisí, àmọ́ ibi tí gbogbo ohun tí a ní ṣe pẹ̀lú ṣọ́ọ̀ṣì mọ nìyẹn.
“Ní ìdà kejì, ẹ wo bí a ti lọ́kàn ìfẹ́ sí àwọn ìtẹ̀jáde yín tó! Èèpo ẹ̀yìn ìwé aláwọ̀ mèremère rírẹwà náà yára gba àfiyèsí wa. Bí o bá bẹ̀rẹ̀ sí í kà á, ó ṣòro láti ṣíwọ́. O fẹ́ láti bá àwọn aládùúgbò ṣàjọpín ohun tí o ti kọ́. Jù bẹ́ẹ̀ lọ, lẹ́yìn tí o bá ti ka àwọn ìsọfúnni náà tí o sì ti jíròrò wọn, o ń láyọ̀, o sì ń nímọ̀lára ìtẹ́lọ́rùn. Nígbẹ̀yìngbẹ́yín, a ti rí ohun kan tí ń gbádùn mọ́ni, tí ó lọ́gbọ́n nínú, tí ó sì ṣàǹfààní láti sọ̀rọ̀ lé lórí.
“Ní tòótọ́, a ń gbé nínú ayé kan tí ó ṣófo nípa tẹ̀mí. Olúkúlùkù ènìyàn ń sọ̀rọ̀ nípa owó, àwọn ìṣòro, ìdààmú, àti ìwà jìbìtì. Àwọn nǹkan wọ̀nyí wulẹ̀ ń dani lọ́kàn rú lásán ni. Lẹ́yìn ríronú nípa wọn, o kò ní lè sùn lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, bí ilẹ̀ bá sì mọ́, o kò ní fẹ́ láti jí, kí o sì tún máa kojú àwọn wàhálà ẹ̀dá ènìyàn.”
Bóyá o ní irú ìmọ̀lára kan náà, kí ó sì dùn mọ́ ọ láti ní ẹ̀dà kan ìtẹ̀jáde fífanimọ́ra yìí, tí Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ẹgbẹ́ kárí ayé kan tí ó ní àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tí ó lé ní mílíọ̀nù márùn-ún nínú, tẹ̀ jáde. Bí ìwọ yóò bá fẹ́ láti gba ìsọfúnni síwájú sí i nípa bí o ṣe lè gba ẹ̀dà kan tàbí tí o bá nífẹ̀ẹ́ sí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé lọ́fẹ̀ẹ́, jọ̀wọ́ kọ̀wé sí Watch Tower, P.M.B. 1090, Benin City, Edo State, Nigeria, tàbí sí àdírẹ́sì tí ó ṣe wẹ́kú lára àwọn tó wà ní ojú ìwé 5.