Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . .
Kí Nìdí Tó Fi Pọn Dandan Fún Mi Láti Máa Kàwé?
“Ara mi ò balẹ̀ débi tí mo fi lè máa kàwé. Tẹlifíṣọ̀n ló máa ń wù mí wò.”—Margarita, ọmọ ọdún mẹ́tàlá, láti orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà.
“Tí wọ́n bá ní kí n mú ọ̀kan nínú ìwé kíkà àti gbígbá bọ́ọ̀lù alápẹ̀rẹ̀, bọ́ọ̀lù alápẹ̀rẹ̀ ni màá mú.”—Oscar, ọmọ ọdún mọ́kàndínlógún, láti orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà.
BÓ O ṣe ń ka gbólóhùn yìí, ó ṣeé ṣe kó o ti rí i pé ó ṣe pàtàkì kéèyàn mọ̀wé kà. Síbẹ̀, lójú ẹ, kíka ìwé tàbí kíka àpilẹ̀kọ kan nínú ìwé ìròyìn lè dà bíi lílo oògùn oníkóró: O mọ̀ pé ó dáa fára ẹ, àmọ́ o ò ní í fẹ́ lò ó.
Àwọn òǹkọ̀wé ìròyìn Jí! fọ̀rọ̀ wá ọ̀rọ̀ wò lẹ́nu àwọn ọ̀dọ́ láti orílẹ̀-èdè mọ́kànlá láti lè mọ ohun tí wọ́n ní í sọ nípa ohun tó mú kó ṣòro fún wọn láti máa kàwé àti àǹfààní tí wọ́n ń rí nínú kíkàwé. Ohun tí wọ́n sọ rèé nísàlẹ̀ yìí.
Kí ló máa ń mú kó ṣòro fún ẹ láti kàwé?
“Mi kì í sábàá rí ààyè fún un.”—Semsihan, ọmọ ọdún mọ́kàndínlógún, láti ilẹ̀ Jámánì.
“Iṣẹ́ ńlá ni ìwé kíkà. Ó dà bíi pé mo ya ọ̀lẹ díẹ̀.”—Ezekiel, ọmọ ọdún mọ́kàndínlógún, láti orílẹ̀-èdè Philippines.
“Kì í wù mí kó dà bíi pé tipátipá ni mo fi ń kà nípa nǹkan tí kò dùn mọ́ mi.”—Christian, ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún, láti orílẹ̀-èdè England.
“Tí ìwé yẹn ò bá tóbi púpọ̀ ó lè wù mí kà. Àmọ́ tó bá ti tóbi jù ó máa ń kà mí láyà.”—Eriko, ọmọ ọdún méjìdínlógún, láti orílẹ̀-èdè Japan.
“Ó rọrùn fáwọn nǹkan míì láti pín ọkàn mi níyà. Mi kì í lè pọkàn pọ̀.”—Francisco, ọmọ ọdún mẹ́tàlá, láti orílẹ̀-èdè South Africa.
A rọ àwọn ọ̀dọ́ tó jẹ́ Kristẹni láti máa ka Bíbélì. (Sáàmù 1:1-3) Ṣéyẹn ò ṣòro fún ẹ? Tó bá ṣòro fún ẹ, kí ló fà á?
“Bíbélì ti tóbi jù! Mi ò rò pé mo lè kà á tán títí ayé mi!”—Anna, ọmọ ọdún mẹ́tàlá, láti orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà.
“Àwọn apá ibì kan nínú Bíbélì ṣòro láti lóye wọn ò sì dùn ún kà.”—Jezreel, ọmọ ọdún mọ́kànlá, láti orílẹ̀-èdè Íńdíà.
“Ó máa ń ṣòro fún mi láti ka Bíbélì déédéé torí pé mi ò fètò sọ́rọ̀ ara mi.”—Elsa, ọmọ ọdún mọ́kàndínlógún, láti orílẹ̀-èdè England.
“Ó ṣòrò fún mi láti ka Bíbélì torí pé iṣẹ́ ilé àti iṣẹ́ ilé ìwé máa ń gba púpọ̀ jù lọ nínú àkókò mi.”—Zurisadai, ọmọ ọdún mẹ́rìnlá, láti orílẹ̀-èdè Mẹ́síkò.
“Bíbélì kíkà ṣòro fún mi torí pé ó dà bíi pé mi ò lè dín àkókò tí mò ń lò lẹ́nu eré ìgbà-ọwọ́-dilẹ̀ kù.”—Sho, ọmọ ọdún mẹ́rìnlá, láti orílẹ̀-èdè Japan.
Ó ṣe kedere pé ìwé kíkà máa ń ṣòro. Àmọ́ ṣó lérè nínú? Èrè wo lo ti rí nínú ìwé kíkà?
“Ìwé kíkà ti mú kí ìmọ̀ mi pọ̀ sí i ó sì ti jẹ́ kí n túbọ̀ ní ìdánilójú nínú ohun tí mò ń sọ tí mo bá ń bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀.”—Monisha, ọmọ ọdún mẹ́rìnlá, láti orílẹ̀-èdè Íńdíà.
“Ìwé dà bí ìsinmi fún mi ni ó sì máa ń gbé ọkàn mi kúrò nínú àwọn nǹkan tó ń dà mí láàmú.”—Alison, ọmọ ọdún mẹ́tàdínlógún, láti orílẹ̀-èdè Ọsirélíà.
“Ńṣe ni ìwé kíkà máa ń jẹ́ kó dà bíi pé mo ti dé àwọn ibi tí mi ò lè dé.”—Duane, ọmọ ọdún mọ́kàndínlógún, láti orílẹ̀-èdè South Africa.
“Ìwé kíkà máa ń jẹ́ kí n lè ṣèwádìí nǹkan fúnra mi, dípò kí n kàn máa gbára lé ohun táwọn ẹlòmíì bá sọ fún mi.”—Abihú, ọmọ ọdún mẹ́rìndínlógún, láti orílẹ̀-èdè Mẹ́síkò.
Kí ló mú kí ìwé kíkà máa dùn mọ́ ẹ?
“Látìgbà tí mo ti wà ní kékeré làwọn òbí mi ti máa ń rọ̀ mí pé kí n máa kàwé sókè.”—Tanya ọmọ ọdún méjìdínlógún, láti orílẹ̀-èdè Íńdíà.
“Àwọn òbí mi rọ̀ mí pé kí n máa ronú fúnra mi nígbà tí mo bá ń kàwé, kí n máa fọkàn yàwòrán bí nǹkan tí mò ń kà ṣe ṣẹlẹ̀.”—Daniel, ọmọ ọdún méjìdínlógún, láti orílẹ̀-èdè England.
“Bàbá mi dá a lábàá fún mi pé kí n bẹ̀rẹ̀ Bíbélì kíkà láti apá ibi tí mo rí i pé ó dùn mọ́ mi jù, bí ìwé Sáàmù àti ìwé Òwe. Ní báyìí ṣe ni Bíbélì kíkà ń dùn mọ́ mi, kò nira fún mi rárá.”—Charene, ọmọ ọdún mẹ́rìndínlógún, láti orílẹ̀-èdè South Africa.
“Nígbà tí mo ṣì wà lọ́mọ ọdún mẹ́rin làwọn òbí mi ti bá mi wá tábìlì ìkàwé àti ibi tí mo lè máa to ìwé sí pẹ̀lú gbogbo ìwé tí wọ́n ti yà sọ́tọ̀ fún mi látìgbà tí wọ́n ti bí mi.”—Airi, ọmọ ọdún mẹ́rìnlá, láti orílẹ̀-èdè Japan.
Kí nìdí tó o fi rò pé ó ṣe pàtàkì kó o máa ka Bíbélì?
“Ọ̀pọ̀ nǹkan tí kì í ṣe òótọ́ làwọn èèyàn gbà gbọ́ nípa Bíbélì. Ó dáa jù tó o bá lè yẹ àwọn nǹkan wọ̀nyí wò fúnra rẹ.” (Ìṣe 17:11)—Matthew, ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún, láti orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà.
“Ọ̀pọ̀ nǹkan téèyàn lè ronú lé lórí ló wà nínú Bíbélì. Ṣùgbọ́n kíkà tí mò ń kà á ti jẹ́ kí n lè fọkàn balẹ̀ ṣàlàyé ara mi lọ́nà tó ṣe kedere nígbà tí mo bá ń bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ nípa ohun tí mo gbà gbọ́.” (1 Tímótì 4:13)— Jane, ọmọ ọdún mọ́kàndínlógún, láti orílẹ̀-èdè England.
“Nígbà tí mo bá ń ka Bíbélì, ó máa ń ṣe mí bíi pé Jèhófà ń bá mi sọ̀rọ̀ tààràtà. Nígbà míì, ọ̀rọ̀ inú ẹ̀ máa ń wọ̀ mí lákínyẹmí ara.” (Hébérù 4:12)—Obadiah, ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún, láti orílẹ̀-èdè Íńdíà.
“Mo ti ń kọ́ láti máa gbádùn Bíbélì kíkà torí pé ó sọ ohun tí Jèhófà ń rò nípa mi fún mi ó sì ń fún mi ní ìmọ̀ràn àtàtà.” (Aísáyà 48:17, 18)—Viktoriya, ọmọ ọdún mẹ́rìnlá, láti orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà.
Ìgbà wo lo máa ń wáyè ka Bíbélì àtàwọn ìwé tó ṣàlàyé Bíbélì?
“Mo ní ètò fún ìwé kíkà. Ohun àkọ́kọ́ tí mo máa ń ṣe láràárọ̀ ni pé màá ka orí Bíbélì kan.”—Lais, ọmọ ọdún mẹ́tàdínlógún, láti orílẹ̀-èdè Brazil.
“Mo máa ń ka Bíbélì àtàwọn ìwé tó ṣàlàyé Bíbélì nígbà tí mo bá wà nínú ọkọ ojú irin tó ń gbé mi lọ sílé ìwé. Láti bí ọdún mẹ́rin sẹ́yìn ni mo ti ń ṣe bẹ́ẹ̀ láìdáwọ́dúró.”—Taichi, ọmọ ọdún mọ́kàndínlógún, láti orílẹ̀-èdè Japan.
“Mo máa ń ka díẹ̀ nínú Bíbélì lálaalẹ́ kí n tó lọ sùn.”—Maria, ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún, láti orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà.
“Mo máa ń ka ojú ìwé mẹ́rin nínú ìwé ìròyìn ‘Ilé Ìṣọ́’ àti ‘Jí!’ lójoojúmọ́. Nípa bẹ́ẹ̀, mo máa ń ka ìwé ìròyìn kan tán pátápátá kí òmíì tó dé.”— Eriko, ọmọ ọdún méjìdínlógún, láti orílẹ̀-èdè Japan
“Mo máa ń ka Bíbélì láràárọ̀ kí n tó lọ sílé ìwé.”— James, ọmọ ọdún mẹ́tàdínlógún, láti orílẹ̀-èdè England.
Gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ táwọn ọ̀dọ́ yìí sọ ṣe fi hàn, téèyàn bá ń kàwé, á mú kó túbọ̀ ní ìdánilójú, á sì mú kí ìmọ̀ rẹ̀ pọ̀ sí i. Tó o bá sì ń ka Bíbélì àtàwọn ìwé tó ń ṣàlàyé Bíbélì, tó fi mọ́ ìwé ìròyìn tó o mú dání yìí, wàá lè “sún mọ́ Ọlọ́run.” (Jákọ́bù 4:8) Torí náà, bí ìwé kíkà bá tiẹ̀ ṣòro fún ẹ, má ṣe juwọ́ sílẹ̀!
OHUN TÓ YẸ KÓ O RONÚ LÉ LÓRÍ
◼ Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé kó o máa ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run?
◼ Báwo lo ṣe lè ‘ra àkókò’ tí wàá fi máa ka Bíbélì àtàwọn ìwé tó ń ṣàlàyé Bíbélì?—Éfésù 5:15, 16.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 11]
WO BÓHUN TÓ Ò Ń KÀ ṢE TAN MỌ́ NǸKAN MÍÌ
Wo bóhun tó ò ń kà ṣe bá ohun tó o mọ̀ nípa ara rẹ àti àyíká rẹ mu. Bi ara ẹ láwọn ìbéèrè yìí:
◼ Wo Ibi Tó Ti Jọ Ohun Tó O Ti Kà Tẹ́lẹ̀ Ṣé ọ̀ràn tàbí ìṣòro tí wọ́n ń sọ yìí jọ èyí tó wà nínú àwọn ìwé míì tàbí ìwé ìròyìn míì, tàbí ìtàn kan tí mo ti kà? Ṣé àwọn tí mò ń kà nípa wọn ní àwọn ìwà tó jọ tàwọn ẹlòmíì tí mo ti mọ̀ nípa wọn tẹ́lẹ̀?
◼ Wo Ibi Tó Ti Kan Ìwọ Alára Báwo ni ọ̀rọ̀ yìí ṣe bá mi mu, báwo ló ṣe bá àṣà ìbílẹ̀ mi mu, báwo ló sì ṣe bá ìṣòro mi mu? Ṣé mo lè fi ohun tí mò ń kà yìí yanjú ìṣòro mi tàbí kí n fi mú kí ìgbésí ayé mi sunwọ̀n sí i?
◼ Wo Bó Ṣe Bá Àyíká Rẹ Mu Kí ni ohun tí mo kà yìí kọ́ mi nípa ìṣẹ̀dá, nípa àyíká mi, nípa oríṣiríṣi àṣà tàbí àwọn ìṣòro tó wà láwùjọ? Kí lohun tí mo kà náà kọ́ mi nípa Ẹlẹ́dàá?