Tí Òbí Ọmọdé Kan Bá Kú
Ṣé ikú mọ̀lẹ́bí rẹ kan ló ń bà ẹ́ lọ́kàn jẹ́? Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, báwo lo ṣe le fara dà á? Wo bí Bíbélì ṣe ran àwọn ọmọ mẹ́ta kan lọ́wọ́ láti fara da ìṣòro yìí.
OHUN TÓ ṢẸLẸ̀ SÍ DAMI
Níbẹ̀rẹ̀, ó jọ pé orí lásán ló ń fọ́ dádì. Àmọ́ nígbà tí ìrora náà ń burú sí i, mọ́mì mi pe ọkọ̀ áńbúláǹsì láti gbé dádì lọ sílé ìwòsàn. Mo ṣì ń rántí bí wọ́n ṣe gbé wọn sínú ọkọ lọ́jọ́ náà. Mi ò mọ pé ọjọ́ yẹn ni màá rí dádì mi kẹ́yìn. Ọjọ́ mẹ́ta lẹ́yìn náà, àìsàn kan tí wọ́n ń pè ní aneurysm pa wọ́n. Mi ò sì tíì ju ọmọ ọdún mẹ́fà lọ nígbà yẹn.
Ọ̀pọ̀ ọdún ni mo fi ń dá ara mi lẹ́bi nítorí ikú dádì. Mo máa ń rántí bí wọ́n ṣe gbé wọn sínú áńbúláǹsì, màá sì bi ara mi pé: ‘Kí ló fà á tí mo kàn fi dúró, tí mi ò ṣe nǹkan kan?’ Tí mo bá rí àwọn arúgbó tí wọ́n ní àìlera, mo máa ń ronú pé, ‘Ṣebí àwọn kan nìyí tí wọ́n ṣì ń rọ́gbọ́n dá sọ́rọ̀ ara wọn, kí ló dé tí àìsàn yìí fi pa dádì mi?’ Nígbà tó yá, èmi àti mọ́mì jọ sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀dùn ọkàn tí mò ń ní. Torí pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni wá, àwọn ará ìjọ wa tún ràn wá lọ́wọ́.
Àwọn kan gbà pé téèyàn bá ti sunkún nígbà tẹ́nì kan kú, ẹ̀dùn ọkàn náà máa dín kù, àmọ́ ọ̀rọ̀ tèmi ò rí bẹ́ẹ̀. Ìgbà tí mo tó ọmọ ọdún mẹ́tàlá ni ìbànújẹ́ mi wá pọ̀.
Ìmọ̀ràn tí màá fún àwọn ọ̀dọ́ tí òbí wọn kú ni pé, “Kí ẹ bá ẹnì kan sọrọ̀ nípa ẹ̀dùn ọkàn yín. Tẹ́ ẹ bá ti tètè sọ bó ṣe ń ṣe yín fún ẹnì kan, ọkàn yín á fúyẹ́.”
Ká sòótọ́, ó máa ń dùn mí pé dádì mi ò sí mọ́ láti rí gbogbo àwọn àṣeyọrí tí mo ṣe nígbèésí ayé mi. Àmọ́, ọ̀rọ̀ tó wà ní Ìṣípayá 21:4, máa ń tù mí nínú, ẹsẹ Bíbélì yẹn sọ pé Ọlọ́run máa “nu omijé gbogbo nù kúrò ní ojú [wa], ikú kì yóò sì sí mọ́, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò sí ọ̀fọ̀ tàbí igbe ẹkún tàbí ìrora mọ́.”
OHUN TÓ ṢẸLẸ̀ SÍ DERRICK
Mo máa ń rántí bí èmi àti dádì mi ṣe máa ń lọ pẹja, tá a sì máa ń pàgọ́ sórí àwọn òkè. Dádì mi fẹ́ràn òkè gan-an.
Ó pẹ́ díẹ̀ tí àìsàn ọkàn ti ń yọ dádì mi lẹ́nu. Mo rántí pé nígbà tí mo ṣì kéré, mo lọ wò wọ́n nílé ìwòsàn lẹ́ẹ̀kan tàbí ẹ̀ẹ̀mejì. Ṣùgbọ́n mi ò mọ bí àìsàn náà ṣe le tó. Àìsàn náà pa dádì mi nígbà tí mo wà lọ́mọ ọdún mẹ́sàn-án.
Nígbà tí wọ́n kú, mo sunkún sunkún. Ńṣe ló dà bíi pé ẹ̀mí mi fẹ́ bọ́, mi ò sì fẹ́ bá ẹnikẹ́ni sọ̀rọ̀. Ọkàn mi ò bà jẹ́ tó báyìí rí, nǹkan kan ò sì wù mí ṣe. Àwọn ọ̀dọ́ tá a jọ ń ṣe ẹgbẹ́ ní ṣọ́ọ̀ṣì wá wò mí bí ìgbà mélòó kan, àmọ́ nígbà tó yá wọn ò wá mọ́. Wọ́n sábà máa ń sọ pé, “Àsìkò dádì ẹ ló dé” tàbí “Wọ́n jẹ́ ìpè Ọlọ́run ni” tàbí “Ọ̀run ni ilé wọn báyìí.” Kò sí èyí tó tẹ́mi lọ́rùn nínú gbogbo ọ̀rọ̀ yìí, àmọ́ mí ò mọ nǹkan kan nípa ohun tí Bíbélì sọ.
Àkókò yẹn ni mọ́mì mi bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́dọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, nígbà tó yá èmi àti bọ̀dá mi náà dara pọ̀ mọ́ wọn. A kẹ́kọ̀ọ́ nípa ipò táwọn òkú wà àti ìlérí tó ń tuni nínú tí Ọlọ́run ṣe pé òun máa jí àwọn òkú dìde. (Jòhánù 5:28, 29) Àmọ́ ẹsẹ Bíbélì tó ràn mí lọ́wọ́ jù ni Aísáyà 41:10, níbẹ̀ Ọlọ́run sọ pé: “Má fòyà, nítorí mo wà pẹ̀lú rẹ. Má wò yí ká, nítorí èmi ni Ọlọ́run rẹ. Dájúdájú, èmi yóò fi okun fún ọ. Èmi yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ ní ti tòótọ́.” Bí mo ṣe mọ̀ pé Jèhófà wà pẹ̀lú mi tù mí nínú gan-an lásìkò náà àti títí di báyìí.
OHUN TÓ ṢẸLẸ̀ SÍ JEANNIE
Àìsàn jẹjẹrẹ pa mọ́mì mi nígbà tí mo wà lọ́mọ ọdún méje. Àfi bíi pé mò ń lálàá. Mo rántí pé ilé ni wọ́n kú sí, àwọn òbí wọn sì wà níbẹ̀. Mo rántí pé àwọn èèyàn kò bara jẹ́. Mo tún rántí pé ẹyin la jẹ sùn lálẹ́ ọjọ́ náà. Àmọ́, ńṣe ni gbogbo nǹkan tojú sú mi, ó sì wá ń ṣe mi bíi pé ayé mi ti fẹ́ bà jẹ́.
Látìgbà yẹn lọ, mo ronú pé àfi kí n ṣara gírí torí àbúrò mi kékeré, èyí mú kí n pa ẹ̀dùn ọkàn mi mọ́ra. Kódà títí dòní, ó ti wá mọ́ mi lára láti máa gbé ohun tó ń dùn mí sára, àmọ́ mo mọ̀ pé kó dáa fún ìlera mi.
Mi ò gbà gbé bí àwọn ará ìjọ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe fìfẹ́ hàn sí mi, tí wọ́n sì ràn mí lọ́wọ́. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò tíì pẹ́ tá a bẹ̀rẹ̀ sí í lọ sí ìpàdé ní Gbọ̀ngàn Ìjọba, síbẹ̀ wọ́n sún mọ́ wa, ńṣe ló dà bíi pé a ti mọ́ra fún ọ̀pọ̀ ọdún. Mi ò rò pé dádì mi dáná oúnjẹ alẹ́ fún nǹkan bí ọdún kan, torí pé gbogbo ìgbà ni wọ́n ń gbé oúnjẹ wá fún wa.
Ẹsẹ Bíbélì tó wọ̀ mí lọ́kàn jù lọ ni Sáàmù 25:16, 17. Ẹni tó kọ Sáàmù yẹn bẹ Ọlọ́run pé: “Yí ojú rẹ sọ́dọ̀ mi, kí o sì fi ojú rere hàn sí mi; Nítorí tí mo dá nìkan wà, a sì ń ṣẹ́ mi níṣẹ̀ẹ́. Wàhálà ọkàn-àyà mi ti di púpọ̀; Mú mi jáde kúrò nínú másùnmáwo tí ó bá mi.” Ọkàn mi balẹ̀ pé mi ò dánìkan wà lásìkò ìbànújẹ́. Ọlọ́run wà pẹ̀lú mi. Ìlérí tí Bíbélì ṣe pé àwọn òkú máa jíǹde ti ràn mí lọ́wọ́ gan-an. Ohun tó tọ́ ni mo máa ń ronú nípa rẹ̀, mo sì ń bá ìgbésí ayé mi lọ. Mo nírètí pé mo ṣì máa rí mọ́mì lẹ́ẹ̀kan sí i nínú Párádísè, tí ara wọn á ti dá ṣáṣá, tá a sì máa mọ ara wa dáadáa.—2 Pétérù 3:13.
Ṣé wàá fẹ́ mọ sí i nípa ọ̀rọ̀ ìtùnú tí Bíbélì sọ fún àwọn tí èèyàn wọn kú? Lọ sí ìkànnì wa www.jw.org/yo, ìwé kan wà níbẹ̀ tá a pè ní “Nígbà Tí Ẹnìkan Tí Ìwọ Fẹ́ràn Bá Kú.” O lè wà á jáde lọ́fẹ̀ẹ́. Ó wà ní abẹ́ ÀWỌN ÌTẸ̀JÁDE > ÀWỌN ÌWÉ ŃLÁ ÀTÀWỌN ÌWÉ PẸLẸBẸ.